Ootọọrọ bii isọkusọ ni i ri

Spread the love

Ọrọ kan jade lati ẹnu Igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin Agba, SẹnetọIke Ekweremadu. Ododo ọrọ lọrọ naa o, ṣugbọn niṣeloda bii isọkusọ. O da bii isọkusọ nitori awọn oloṣelu ko ni i fi ara balẹ gbọ iru ọrọ bẹẹ, nigba to jẹ lẹnu ọtawọn lo ti jade. Awọn araalu paapaa ti wọn ko ba fẹran ẹgbẹ PDP ko ni i gbe ọrọ naapaapaayẹwo, wọn yoo ni katikati lọkunrin naan sọ. Bẹẹọrọ daadaani. Ekweremadu ni ki awọn ṣe ofin kan, ofin ti yoo jẹ ko jẹẹẹkan naa ni olori Naijiria yoo maa ṣejọba, saa kan pere naa ni yoo maa lo, ṣugbọn to jẹ kaka ko lo ọdun mẹrin, ọdun mẹfa ni wọn yoo fi akọkọ ti yoo lo yiiṣe. Ọrọ Ekweremadu niyẹn. Ṣugbọn o jọ pe ohun to tubọ jẹ ki awọn eeyan mi-in poṣe nigba to sọọ ni pe ki i ṣe oun lo kọkọ sọrọ naa, Olori Naijiria atijọ,  Goodluck Jonathan, lo kọ sọ ọ, koda, o mura lati sọọ dofin, pe ki aarẹNaijiria maalo saa kan pere. Anfaani wa nibẹ, awọn ti ko ba mọ ni wọn ko mọ, awọn ti ko ba ri i ni ko ri i. Anfaani ibẹ ni pe ohun aburu to n ṣẹlẹ ni Naijiria lasiko yii ko ni i ṣẹlẹ bo ba jẹ saa kan ni oloṣelu yoo lo. Nigba ti awọn oloṣelu yiibẹrẹ sii wa awọn ti wọn yoo fi ṣe minisita, ki wọn si too fi idi ijọba wọn mulẹ, ọdun kan yoo ti pe tabi ko ti kọja paapaa. Biwọn ba ti lo ọdun keji ti wọn si lo ọdun kẹta, ko tun si iṣẹ mọ, oṣelu bi wọn yoo ti yan wọn wọle lẹẹkeji ni yoo ku, iyẹn ni wọn yoosi fi gbogbo ọdun kẹrin wọn ṣe. Iru ẹ lo n ṣẹlẹ lọwọ lasiko ti a wa yii ninu ijọba Buhari. Yatọ si ti akoko ọmọ Naijiria ti wọn fi n ṣofo, owo rẹpẹtẹ ni wọn yoo na. Wọn yoobẹrẹ si i fun arawọn lowo abẹtẹlẹ, wọnyoomaa ja ọmọẹgbẹ kan gba si ikeji, wọn yoo maafi ọlọpaa ati awọn agbofinro ti ko yẹ ki wọn da si ọrọ oṣelu rara halẹ mọ ara wọn nitoripe aarẹ fẹẹ du ipo rẹ lẹẹkeji. Amọ bo ba jẹẹẹkan naani, to jẹ aarẹ kodu ipo kankan mọ, yoo le lo agbara ijọba lati le ri i pe ko si ojooro, ko si si ẹni to lo awọn ọlọpaa tabi ṣọja nilokulo lọjọ idibo, ati pe ẹni ti ko ti idipo mu ni yoo maaṣe kanmpeeni kiri, aarẹ atawọn eeyan rẹ yoo si le raaye dojukọ iṣẹ wọn. Ohun to dara bi Naijiria ba le gbe e yẹwo ni, ohun ti yoo ṣe Naijiria lanfaani ni. Ẹ ma jẹ ka woo pe wọn ki i ṣe bẹẹ nibi kan, nitori bi a ti n ṣe nilẹ yii, eewọ ibomi-in ni. Ẹ jẹ ka dan an wo, ootọọrọ lọrọ Ekweremadu, o kan da bii isọkusọ ni.

 

(52)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.