Oore ti Buhari ṣe fun wa yii, nnkan ni o!

Spread the love

Nigba ti iru awọn ọrọ bayii ba ṣẹlẹ ni mo maa n mọ bi ẹ ṣe ka mi si to. N ko le sọ bi inu mi ṣe maa n dun to nigba ti mo ba n ri awọn ọrọ ti ẹ n sọ. Afi bii ẹni pe emi ni ẹgbọn tabi aburo Abiọla, tabi pe emi ni mo ni ki wọn fun un ni oye ti wọn fun un. Gbogbo yin ni ẹ n sọ pe ẹ fẹẹ gbọ ohun ti mo ri si i. Bi awọn kan ti n sọrọ naa daadaa, awọn miiran n ṣe ko tan nidii mi. Ẹ gbọ ọrọ ti ọkan ninu awọn eeyan wa sọ ranṣẹ. O tẹ atẹjiṣẹ bayii pe: “Baba, ẹyin ti ẹ ni Buhari ko le ṣe daadaa fun Yoruba, eyi to ṣe yii nkọ o!” Eleyii fihan pe iru inu ẹni bayii ko dun si gbogbo ohun ti mo n sọ tẹlẹ nipa Buhari, bii pe mo koriira rẹ lainidii lasan ni. Mo ti n sọ ọ ni gbogbo igba pe n ko ni ikoriira kan fun olori ijọba Naijiria naa, awọn ẹya rẹ ni n ko fẹran, nitori pe alaburu eeyan ni wọn; agbalọwọ-merii, awọn apamọlẹkunjaye niran wọn.

Gbogbo ohun ti mo n fẹ ni daradara fun ilu yii, bi Buhari ba ṣe daadaa, idunnu mi ni yoo jẹ, nitori ninu ko dara fun Naijiria, nibẹ laye gbogbo wa ti le dara. Bi ko ba dara fun Naijiria, koda ki Yoruba ya ara rẹ sọtọ, awọn Ibo ati Fulani yii naa ko ni i jẹ ka gbadun aye wa. Iyẹn lo ṣe jẹ pe bi a ba ri ọna alaafia lati maa fi ba ara wa gbe, o dara ju ka ja, ka tuka lọ. Ohun ti Buhari ṣe fun Abiọla ati fun ‘June 12’ ti ẹ n beere lọwọ mi yii, oore-ẹdẹ gbaa ni. Oore-ẹdẹ ni oore ti a ṣe fun eniyan ti yoo lẹyin, iyẹn oore to da bii oore ti ẹgbẹji ṣe fun agan. Olori oloogun ni ẹgbẹji, agan si lobinrin ti ko loyun debi ti yoo ri ọmọ bi nile ọkọ. Bi ẹgbẹji ba waa ṣe ọmọ fun agan ti agan n yọ ṣẹṣẹ, afi ka gba agan nimọran ko rọra yọ niwọnba o, nitori ẹgbẹji to ṣe ọmọ fun ni naa tun le pada gba ọmọ lọwọ ẹni. Bi oore ti Buhari ṣe fun Yoruba ṣe jẹ ree o.

Awọn ohun mẹta ni ki ẹ kọkọ jẹ ka mọ. Ẹtọ to tọ si Yoruba ati Abiọla ni wọn fun wa; ekeji ni pe Buhari ko ṣe e fun wa nitori pe o fẹran Abiọla tabi Yoruba; ẹẹkẹta si ni pe oore naa ko ti i tẹ wa lọwọ lodidi, o kan fun wa ni ori ọbẹ, o di eeku (idi) rẹ mu ni, bẹẹ eleeku lo lọbẹ. Ki ẹ too gba ọrọ naa sodi, ẹ jẹ ki n ṣalaye fun yin o. Ẹtọ to tọ si Yooba ti mo wi yii, awọn ti wọn dagba ni 1993 si 1998 lọrọ naa yoo ye daadaa. Abiọla du ipo aarẹ Naijiria, o si wọle. Ṣugbọn wọn ko gbejọba naa fun un. Ko ṣe ohun meji ju pe o jẹ Yoruba lọ, awọn Hausa-Fulani ti wọn ro pe tiwọn nikan ni Naijiria si pinnu pe awọn ko ni i gbejọba fun un. Nibi ti Abiọla ti n ja lorukọ ara rẹ ati lorukọ Yoruba, nibẹ ni wọn pa a si. Wọn pa a ni. Awọn wo ni wọn pa a, awọn Hausa-Fulani yii naa ni wọn pa a, wọn si fi agidi gba ẹtọ rẹ, ati ti Yoruba kuro lọwọ rẹ.

Nigba ti wọn ṣe eleyii tan, wọn gbejọba fidi-hẹ-ẹ fun Ṣonẹkan, ẹni ti ko dibo, ti ko nawo kan, ti ko si ṣe wahala kan, titi di bi a si ṣe n wi yii, ti wọn ba n ṣepade awọn olori orilẹ-ede Naijiria, Ṣonẹkan yoo maa jokoo si aarin wọn. Lẹyin ti wọn ṣe eleyii ti ọrọ di wahala gidi, nitori lati tu Yoruba loju, wọn lọ sinu ọgba ẹwọn, wọn lọọ fa Ẹgbọn Ṣẹgun jade, wọn ni ko waa ṣe aarẹ Naijiria. Ni 1999, ki i ṣe ọmọ Naijiria lo dibo fun Ọbasanjọ, awọn alagbara Fulani ni wọn fẹẹ fi i jẹ oye naa, awọn ni wọn si mọ bi wọn ti ṣeru ibo ọhun to fi wọle. Nibi ti ẹgbọn yii si ti ṣe aṣiṣe ree, nibi to ti ṣẹ ọpọlọpọ eeyan niyẹn. Niṣe loun naa n ṣe bii ẹru awọn Fulani yii, bii pe awọn Fulani yii ni okun kan ti wọn fi de e mọlẹ, tabi pe wọn ti fun un lofin awọn ohun ti ko gbọdọ ṣe. Niṣe lo yiju si ẹgbẹ kan, bo tilẹ jẹ pe o mọ pe lori ẹtọ Abiọla loun jokoo le.

Ko si ohun ti a gbọdọ ṣe fun ara wa ti eeyan yoo daju ọmọlakeji rẹ gẹgẹ bi Ẹgbọn Ṣẹgun ti ṣe fun Abiọla, ko dara rara. Bi eeyan ba ranti pe ko si ohun ti a n jẹ ti ki i tan ju ọla Ọlọrun lọ, ati bi eeyan ba mọ pe ko si oke giga kan ti oun gun laye ti oun ko ni i sọ kalẹ, iba diẹ ni yoo gbegi dina fun ẹlomiiran pe ko ma ga lọ. Boya ẹgbọn yii ko fẹ ki orukọ Abiọla ga ju toun lọ ni o, boya awọn Fulani ti wọn gbe e sipo lo si n bẹru, eyi o wu ko jẹ, Ẹgbọn Ṣẹgun ko ṣe daadaa f’Abiọla rara, ko si ṣe daadaa fun Yoruba, nitori ko gba ẹtọ wa fun wa. Lara ohun ti Yoruba ko si ṣe fẹran rẹ titi doni, ti wọn maa n fi oju ọdalẹ wo o niyẹn. Nigba miiran, Ọlọrun yoo da ija silẹ laarin awọn ọta wa, ki agbega ati oore ti Oun Ọlọrun fẹẹ ṣe le jade. Bi ija ko ba de laarin ẹgbọn yii ati awọn Buhari, ẹtọ Abiọla ati ti Yoruba ko ni i to wa lọwọ.

Ṣugbọn ka mọ eleyii daadaa o. Ki i ṣe pe Buhari fẹran Abiọla o, tabi pe o nigbagbọ ninu ‘June 12’, tabi pe o fẹẹ ṣe oore kan fun Yoruba. Bi ẹnikan ba n ro iru rẹ, a jẹ pe ọrọ oṣelu Naijiria yii ko ye e, bẹẹ ni ko mọ iru awọn eeyan ti wọn n pe ni Fulani. Bi Buhari ba nigbagbọ ninu ‘June 12’ ati Abiọla, awọn Bọla, awọn Bisi, ati awọn aṣaaju APC ilẹ Yoruba ni iba kọkọ fi ọrọ naa lọ, tawọn aa ti sọ ọ jade ko too ṣe e. Ṣugbọn ko sọrọ naa leti ẹnikẹni ninu wọn, bi awa ṣe gbọ lori redio lawọn eeyan yii naa gbọ, itiju gidi lo si jẹ fun wọn laarin awọn ẹgbẹ wọn. Ọgbọn oṣelu ni. Ki i ṣe ohun meji. Nitori lati sọ Ẹgbọn Ṣẹgun to n bu u kiri, to si ti da ẹgbẹ oṣelu silẹ di yẹyẹ ni akọkọ, ati lati fi abuku kan Babangida toun naa ri bii tirẹ nikeji, ati lati fa oju awọn ọmọ Yoruba mọra lai ni i si Bọla ati Bisi atawọn mi-in nibẹ lo ṣe ṣe e.

Buhari fẹ ibo awọn ọmọ Yoruba, o si mọ pe ohun ti oun ti ṣe fun Yoruba ko dara, bẹẹ ni ki i ṣe pe o mura lati ṣe atunṣe, ṣugbọn lati tan wọn gba ibo wọn lẹẹkeji lawọn ara rẹ ṣe ronu pe ko fi ọrọ ‘June 12’ tu wọn loju, bo ba ti ṣe bẹẹ ni wọn yoo gbagbe inu to n bi wọn si i. Ko fẹ ki ọrọ naa fun awọn Bọla ati Bisi ni iyi tabi apọnle kankan, ṣe awọn yii naa ko kuku ja fun ọrọ ‘June 12’ tabi ti Abiọla mọ lati ọjọ to ti pẹ, o fẹ ki Yoruba ri i pe oun nikan loun ṣe e, ki wọn si ro pe oun fẹran wọn. Ṣugbọn ẹni ti ọrọ ko ba ye ni yoo ro bẹẹ. Fun gbogbo ọdun marun-un ti Abacha fi ṣe ijọba were nilẹ yii, to n paayan kiri, titi ti wọn fi mu Abiọla ti wọn ju u sẹwọn, ọlọwọ-ọtun rẹ ni Buhari, Buhari fẹran Abacha debii pe bi gbogbo aye ti n pariwo loni-in pe o jale, pe o paayan, Buhari si n sọ pe eeyan daadaa ni titi dọla. Bẹẹ ni Abacha naa fẹran rẹ. Ki lo waa de ti ko sọ fun un pe ‘June 12’ ati Abiọla ki i ṣe nnkan buburu.

Bi ẹnikan ba si sọ pe nigba naa, oun kọ ni aarẹ orilẹ-ede, ko lagbara, ki lo de ti ko ṣe ikede naa lọjọ to gbajọba Naijiria gbara, ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2015, (May 29, 2015). Bo ba jẹ loootọ lo ni igbagbọ ninu ‘June 12’, ijọ yẹn ni yoo kede rẹ, bi ko si kede rẹ lọjọ naa, yoo kede rẹ ni ọdun to ba tẹle e, nigba to ba n ṣe ayẹyẹ akọkọ rẹ. Awọn akoko ti olori ijọba maa n kede eto pataki niyẹn. Eleyii ti wọn ṣe yii, wọn sare ṣe e lasan nitori pe ọjọ ibo ku si dẹdẹ ni. O ti fabuku kan awọn Ẹgbọn Ṣẹgun, o fi kan awọn Bọla, nitori o fẹẹ da di Yoruba mu funra ẹ laisi atilẹyin awọn eeyan yii, ko si fi awọn ọmọ rẹ to ti ni lọwọ bayii l’Abuja ranṣẹ si wa. Igbagbọ temi ni pe ki i ṣe oun lo n ṣe gbogbo eleyii, Ọlọrun lo o lati da ẹtọ wa pada fun wa ni. Iyẹn ni a ko ṣe gbọdọ yọ layọju, nitori kinni naa paapaa ko ti i to wa lọwọ. Ohun ti Buhari sọ ni pe lọjọ iwaju lawọn yoo sọ ‘June 12’ di ‘Dẹmokiresi Day’, iyẹn ni ijọba apapọ ko ṣe fun wa ni ọlude fun un loni-in yii.

Bo ba jẹ wọn fẹẹ ṣe e pari ni, lẹsẹkẹsẹ to ti kede ni ọrọ naa yoo ti di aṣẹ, ti a o maa gba ọlude rẹ, ti wọn yoo si sọ pe awọn ti pa ‘May 29’ ti a ti n sami rẹ tẹlẹ rẹ ninu iwe ijọba. Wọn ko ti i pa a rẹ o. Koda, bi a ti n wi yii, awọn Fulani ti n gbarajọ, wọn ti n pariwo pe ohun to ṣe ko dara, lọjọkọjọ lẹlomi-in si le de ninu wọn ti yoo sọ pe ọrọ naa ko ri bẹẹ mọ, nitori wọn ko kuku ti i fa a le wa lọwọ tan. Koda, Buhari yii funra rẹ le ma ṣe nnkan kan le e lori mọ. O fẹẹ lo o lati fi gba ibo wa ni, ki i ṣe ohun ti a gbọdọ tori ẹ ba ara wa ja tabi ka ṣe aṣiṣe mi-in. Buhari ko fẹran Yoruba, ko fẹran Abiọla, ko nigbagbọ ninu ‘June 12’, ibo lo n wa o.

(75)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.