Ọọni rọ awọn oloṣelu lati ni ifẹ araalu lọkan

Spread the love

Ọọni ti Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja 11, ti ke si gbogbo awọn oloṣelu; yala, awọn ti wọn wa nipo lọwọlọwọ tabi awọn ti wọn ṣẹṣẹ n tiraka lati debẹ, lati jẹ ki ifẹ awọn araalu ti wọn fibo yan wọn sipo jẹ akọkọ lọkan wọn.

 

O ni wọn ko gbọdọ sọpakọ sẹyin nigba ti wọn ba ti depo tan, wọn gbọdọ maa ṣiṣẹ tọ imuṣẹ ohunkohun ti wọn ba ṣeleri fawọn araalu lasiko ipolongo ibo wọn.

 

Lasiko ti Igbakeji aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ṣabẹwo si aafin Ọọni ni Kabiyesi ti rọ ọ pe idagbasoke iran Yoruba gbọdọ mumu laya ọmọ Yoruba to ba wa nipo kan tabi omi-in.

 

Ọọni rọ Ọṣibajo lati ṣokunfa oriṣiiriṣii nnkan ti yoo buyi kun ilu Ileefẹ gẹgẹ bii orirun ilẹ Yoruba kaakiri agbaye. O ni aṣoju Yoruba ni nipo to wa, ko si gbọdọ ja awọn eeyan kulẹ.

 

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Ọṣinbajo ni ipa takuntakun ni Ọọni Ogunwusi n ko nipa titọ awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa nipo giga lorileede yii ati kaakiri agbaye sọna, ati ṣiṣi wọn leti loorekoore lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe.

 

O ni oun ko le gbagbe nnkan ti ọba naa ṣe foun ni kete ti wọn kede orukọ oun gẹgẹ bii ẹni ti yoo jẹ igbakeji oludije funpo aarẹ nigba naa, idi si niyẹn ti oun ko fi le koyan iran Yoruba kere nigbakuugba tipade ba wa lori idagbasoke orileede yii.

 

Ọṣinbajọ, ẹni ti gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla ati Ọtunba Iyiọla Omiṣore ba kọwọọrin lọ siluu Ileefẹ lo asiko naa lati ṣepolongo ibo fawọn ẹya Hausa ni Sabo, niluu Ileefẹ, ko too kọja si ilu Mọdakẹkẹ.

 

Nigba to de aafin Ogunṣua ti Mọdakẹkẹ, Ọba Oyeduran rọ ọ lati ma ṣe gbagbe iran Yoruba ti wọn ba ti lanfaani lati depo naa lẹẹkeji, ko ma si ṣe faaye gba ohunkohun to le mu ina iran Yoruba jo ajorẹyin laarin awọn iran to ku lorileede yii.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.