Oogun owo ni mo ba lọ sọdọ Wolii, pata obinrin lo ni ki n lọọ ko wa- Adejoh

Spread the love

Ọkunrin kan to porukọ ara rẹ ni Adejoh Ojoungwa, ẹni tọwọ tẹ niluu Uso, nijọba ibilẹ Ọwọ, lọsẹ to kọja yii, ti ni wolii ijọ Sẹlẹ kan lo sa si oun toun fi lọọ ji pata ko.

 

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni ọkunrin to n ṣiṣẹ wẹda naa ra pala wọ yara iyawo ẹgbọn rẹ lọ niluu Uso, nijọba ibilẹ Ọwọ, nibi to ti ji pata meji to jẹ ti abilekọ ọhun ko lasiko ti obinrin ọhun ṣi wa lọja.

 

Bo ṣe ṣetan to fẹẹ jade ni iyawo ẹgbọn rẹ, Abilekọ Benjamin Grace, pada de lati ọja, to si ri aburo ọkọ rẹ to n ko awọn pata to ji ko ọhun sinu baagi kan to gbe lọwọ.

 

Kiakia lo fariwo ta, to si ke sawọn araadugbo ki wọn le jọ mu ole ajipata naa ko too di pe o sa lọ mọ ọn lọwọ.

 

Wọn lọọ fẹjọ afurasi ọhun sun lagọọ ọlọpaa Uso, iyalẹnu nla lo jẹ fawọn eeyan tọrọ naa ṣoju wọn pẹlu bi wọn tun ṣe ba pata mẹta mi-in to ti kọkọ ji ko ninu baagi to gbe lọwọ.

 

Nigba to n sọ iha tirẹ lori iṣẹlẹ ọhun, Adejọh jẹwọ fun wa pe loootọ ni wọn ka oun mọ ibi toun ti n gbiyanju lati ji pata.

 

O juwe iṣẹlẹ ọhun bii eedi ati asasi lati ọdọ wolii ijọ Sẹlẹ kan to pe orukọ rẹ ni Ọlajide Ogunlẹyẹ,.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni nigba ti iṣẹ toun n ṣe ko lọ deedee mọ loun lọ sọdọ Wolii Ogunlẹyẹ, ẹni tawọn eeyan ilu Uso tun mọ si Kọkọrọ Ayọ, lati ba oun ṣoogun owo.

 

Lẹyin to gbadura foun tan lo tun fun oun ni kinni kan to da bii ororo mu, leyii to mu koun bẹrẹ si i ji pata lati igba naa.

 

Meji ninu pata ti wọn ka mọ ọn lọwọ lo ni wọn jẹ ti iyawo ẹgbọn oun, nigba ti mẹta yooku jẹ ti aburo rẹ obinrin ti wọn jọ jẹ ọmọ iya kan naa.

 

Wolii Ogunlẹyẹ sẹ kanlẹ pe ko sibi toun ati Adejoh to fẹsun kan oun ti mọra.

 

Oludasilẹ ijọ Sẹlẹ ti wọn n pe ni Ibanujẹ mi Dopin, eyi to wa niluu Uso, ọhun ni akoba lasan ni wọn fẹẹ fi iṣẹlẹ naa ṣe foun.

 

Asiko kan wa to ni ẹgbọn Adejoh toun mọ daadaa waa tọrọ ilẹ lọwọ oun lati fi dako, ṣugbọn toun ko fun un nitori ibẹru pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe igbo lo fẹẹ gbin sori ilẹ naa.

 

Wolii Ogunlẹyẹ ni o da oun loju gbangba pe kikọ toun kọ lati fun ọkunrin ọhun nilẹ to fẹẹ fi dako igbo nigba naa lo ṣokunfa bi wọn ṣe koba oun.

 

Fẹmi Joseph to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

 

Ẹsun meji lo ni o ṣee ṣe ki wọn fi kan awọn afurasi ọhun lẹyin ti wọn ba pari iwadii wọn.

 

Awọn mejeeji lo ni wọn yoo jẹjọ lori ẹsun igbiyanju lati paayan ti iwadii awọn ba lọọ fidi rẹ mulẹ pe etutu ni wọn fẹẹ fi awọn pata ti wọn ji ko naa ṣe, nigba to ṣee ṣe ki wọn fẹsun ole jija lasan kan wọn to ba jẹ pe wọn ko ni i lọkan lati fi awọn pata ti wọn ji naa ṣetutu.

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.