Oogun owo ni Chibuzor loun fẹẹ fi pata mẹta toun ji ṣe

Spread the love

Laye ti pata ati awọn awọtẹlẹ obinrin ti di ohun ti wọn fi n ṣoogun yii, afi ki gbogbo obinrin maa ṣọ ibi ti wọn ba n sa awọn awọtẹlẹ wọn si. Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, ni ileeṣẹ ọlọpaa wọ afurasi meji kan; Peter Ayọdele, ẹni ogun ọdun ati Chibuzor David, ẹni ọdun mọkanlelogun, lọ si kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, wọn ni ṣe ni wọn ka awọn awọtẹlẹ mẹta ti wọn jẹ ti iyawo ile kan mọ wọn lọwọ.

Iṣẹ kọndọkitọ ni awọn afurasi mejeeji yii lawọn n ṣe. Ayọdele, ẹni ti akọsilẹ ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe agbegbe Oshodi lo n gbe, ni wọn fi ẹsun igbimọ-pọ huwa ọdaran ati ole jija kan. Ayọdele loun ko jẹbi ẹsun naa, ṣugbọn ṣe ni Chibuzor loun mọ nipa rẹ, ootọ loun huwa yii.

Agbefọba to n rojọ tako wọn nile-ẹjọ, Insipẹkitọ Aondohemba Koti, sọ pe lọjọ kẹfa, oṣu yii, ni awọn mejeeji huwa naa laduugbo Idi-Oro, ni Mushin, nigba ti wọn lọọ ji pata Abilekọ Kẹhinde Ọladimeji, o ni iwadii awọn ọlọpaa si fi han pe oogun owo ni wọn fẹẹ fi awọn awọtẹle obinrin naa ṣe. O ṣalaye pe obinrin yii n sun lọwọ ni awọn mejeeji fi ja wọ inu ile rẹ, ṣugbọn nigba ti wọn n sa lọ ni wọn ko sọwọ awọn ọlọpaa to n yide kaakiri lasiko naa. Katikati ti wọn n sọ lẹnu lo jẹ ki awọn agbofinro yii yẹ ara wọn wo, nigba ti wọn si gbọn ara wọn yẹbẹ-yẹbẹ ni won ba pata mẹta lọwọ wọn. Ayọdele nikan lo jẹwọ pe loootọ lawọn ji pata naa, obinrin to si ni wọn fidi rẹ mulẹ pe oun loun ni awọn awọtẹlẹ ọhun. Ẹsun naa ni agbefọba sọ pe o tako awọn abala kan to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko ṣagbekalẹ  rẹ lọdun 2015.

Adajọ M.O Tanimọla ni ki wọn lọọ fi Ayọdele pamọ sọgba ẹwọn Kirikiri, o si faaye beeli silẹ fun Peter ni ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira ati oniduuro meji niye kan naa.

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, lo sun igbẹjọ naa si.

(55)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.