Oogun oloro ti Adigun n mu lo fi para rẹ, ki i ṣe ifidirẹmi lẹnu ẹkọ ẹ -Unilorin

Spread the love

Awọn alaṣẹ Fasiti Ilọrin ti ni ki i ṣe nitori ti akẹkọọ wọn kan, Adigun Ọlawale Emmanuel, fidi-rẹmi ninu iṣẹ iwadii ijinlẹ (Research project), lo mu un pa ara rẹ, bi ko ṣe oogun oloro to n mu.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro fasiti naa, Ọgbẹni Kunle,****  gbe jade l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, wọn ni oogun oloro to n lo lati fi pa gbogbo iṣoro to n la kọja, eyi to ti di baraku fun oloogbe naa lo fi gba ẹmi ara rẹ.

Awọn to sun mọ ọdọmọkunrin naa ni bii igba mẹta ọtọọtọ lo ti gbiyanju lati pa ara rẹ. Eleyii to jẹ igba kẹrin lo pada mu erongba buruku rẹ ṣẹ.

Adigun ni wọn lo ti maa n banujẹ tipẹ, to si maa n sọ fawọn eeyan pe aburo oun kan lo n tọ oun nileewe.

Wọn ni ninu iṣẹ bii meje lo ti fidi-rẹmi tẹlẹ, eyi to si nilo lati tunṣe ko too le wa lara awọn akẹkọọ to kawe gboye. Ṣugbọn ko mọ bo ṣe tun maa lọọ ba aburo rẹ naa lati beere owo to maa fi ṣeto iforukọsilẹ lọwọ rẹ.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ yii ni ọkan lara awọn ọga fasiti naa ti ṣakiyesi pe oogun oloro to n mu naa ti fẹẹ da ọpọlọ rẹ ru, tiyẹn si ti gbiyanju lati ran an lọwọ.

Wọn ni lara igbesẹ tileewe naa gbe lati ran ipo ti oloogbe yii wa lọwọ ni itọju ọsẹ mẹrin gbako nilewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, gbigba ile fun un ninu ọgba ileewe naa atawọn nnkan mi-in.

Ileewe ọhun ni pẹlu gbogbo akitiyan wọnyi lati da a pada sipo, o ṣe ni laaanu pe oloogbe naa pada gba ẹmi ara rẹ.

Wọn ni awọn ọrẹ to n ba rin tun ṣe akoba fun un. Idi ni pe bi ọkan lara wọn toun naa wa nileewe giga kan nipinlẹ Kwara ṣe gbẹmi ara rẹ niyẹn laipẹ yii.

Ko too gbẹmi ara rẹ lo ti sọ fawọn ọrẹ rẹ lori ikanni ibanisọrọ Whatsapp lori ẹrọ ayelujara pe idi toun fi gbe igbesẹ naa ko ṣẹyin bi olukọ oun ṣe loun dawẹ kọ.

Ọdọmọkunrin naa to wa nipele to gbẹyin, 400 level, lẹnu ẹkọ rẹ lo ti ilẹkun mọri sinu yara rẹ, to si gbe majele jẹ.

Lẹyin ọjo keji lawọn ayalegbe ẹgbẹ rẹ n gbọ oorun to bu jade lati inu yara naa, ti wọn si ja ilẹkun. Si iyalẹnu wọn, oku rẹ ni wọn ba nilẹ.

Ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn naa ni wọn lo fidi-rẹmi ninu apilẹkọ aṣekagba rẹ (Project) ni saa ikẹkọọ ọdun to kọja, lẹyin ti ọga to n yẹ iwe naa wo fẹsun kan an pe o da iṣẹ oniṣẹ kọ.

Akẹkọọ imọ nipa eto ọgbin (Agriculture) lo ni ile aye ti su oun, bii igba koun ku lo n ṣe oun lasiko to n ba ọrẹ rẹ kan sọrọ. Ṣugbọn ṣe ni awọn ọrẹ rẹ naa n tu u ninu lati ma ṣe ro o pin.

Lẹyin iṣẹju diẹ lo gbe aworan oogun ti wọn fi n pa kokoro (sniper) sori ikanni Whatsapp to n fi n ba wọn sọrọ. Ki wọn too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ti da kinni naa jẹ.

Ohun ti Adigun kọ sawọn ọrẹ rẹ ni pe: “Iṣẹ iwadii kan naa ti mo ti n ṣe lati ọdun to kọja lo (olukọ) ni mo da kọ. Latigba naa ni nnkan ti yipada si buburu fun mi. Igbe-aye mi ti su mi bayii. O n ṣe mi bii pe ki n ku. O wu mi ki n sun ki n si ma ji saye mọ”.

Iwadii fi han pe ọrẹ rẹ kan da a lohun pe: ” Wale, dakun ni suuru. Mo bẹ ẹ nitori Ọlọrun, ma gbe igbesẹ buruku o. Ko si ohun to ṣẹlẹ ti Ọlọrun ko mọ si”.

Idahun to fi sọwọ ni pe: “Mo dupẹ lọwọ yin fun imọran yin. Mo gbagbọ pe nnkan maa yi pada. Ọlọrun a tẹsiwaju lati maa bukun fun yin, ẹ ṣe”.

Ero awọn ọrẹ to ba a sọrọ ni pe o ti gbọ imọran ti wọn fun un, laimọ pe ọrọ idagbere rẹ lo fi ranṣẹ si wọn.

Fasiti naa ba awọn obi ati mọlẹbi oloogbe yii kẹdun. Wọn ke si awọn obi ati alagbatọ lati maa ṣe ojuṣe wọn lori awọn ọmọ daadaa.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.