Onyekuru ṣegbeyawo alarinrin ni Benin

Spread the love

Atamatase ilẹ wa, Henry Onyekuru, ti ṣegbeyawo alarinrin niluu Benin, nipinlẹ Edo, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja pẹlu ololufẹ ẹ, Esty, ẹni ti wọn ti jọ wa tipẹ.

Onyekuru to ṣe bẹbẹ fun Galatasaray, ilẹ Turkey, ni saa to kọja pẹlu goolu mẹrinla lawọn agbabọọlu Naijiria ya bo ibi ayẹyẹ rẹ lati yẹ ẹ si. Lara awọn to wa nibẹ ni Oghenekaro Etebo, John Ogu, Kenneth Omeruo ati Chidozie Awaziem.

Oriire yii waye lẹyin bii ọsẹ kan ti Onyekuru atawọn ọmọ ikọ Super Eagles to ku pari idije ilẹ Afrika tọdun yii.

Aspire Academy ilẹ Qatar ni Onyekuru ti kọ nipa bọọlu laarin ọdun 2010 si 2015, ko too lọ si Kilọọbu Eupen, ilẹ Belgium. Ọdun 2017 lo balẹ si Everton, wọn si kọkọ ta a fun Anderlecht, ilẹ Belgium, ki wọn too ya Galatasaray.

Ọdun 2017 lo bẹrẹ si i gba bọọlu fun Naijiria, bẹẹ lo wa lara awọn ọdọmọde agbabọọlu to dangajia ju ni Super Eagles lọwọlọwọ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.