Ọmọtayọ wọ gau, oyinbo lo fi ọrọ ifẹ ṣe gbaju-ẹ fun

Spread the love

Ọmọtayọ Tapere ni Ajọ EFCC, ti wọ lọ si kootu to n gbọ ẹsun iwa ọdaran to wa ni Ikẹja, niwaju Adajọ Mojisọla Dada. Ẹsun meji ọtọọtọ, iyẹn nini awọn iwe ayederu lọwọ ati ṣiṣe ayederu iwe ni wọn fi kan an.

Gẹgẹ bii atẹjade ti ajọ naa fi sita ṣe ṣalaye, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni Ọmọtayọ ti inagijẹ rẹ n jẹ Robert Fine, huwa naa laarin ọdun 2018, niluu Eko, pẹlu bo ṣe fi imeeli ranṣẹ latori ikanni Robert.fine231101@gmail.com, si  Fredicia Fox, nibi to ti sọ fun Fox pe oun nifẹẹ rẹ. Iwa yii ni wọn ni Ọmọtayọ mọ ninu ara rẹ pe irọ loun n pa fun Fox.

 Olujẹjọ naa loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun pẹlu alaye.

Agbẹjọro EFCC, M.A Bashir, rọ kootu ko fun awọn lọjọ ki awọn le ko awọn ẹlẹrii wa sile-ẹjọ, o si bẹ adajọ pe ko fi Ọmọtayọ pamọ si ọgba ẹwọn titi asiko ti awọn aa fi pari ẹjọ rẹ.

Agbẹjọro olujẹjọ, Oye Akanni, rọ adajọ lati ṣiju aanu wo onibaara oun, ko si faaye beeli silẹ fun un.

Adajọ Dada sun ẹjọ naa si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, o si paṣẹ pe ki wọn ṣi maa mu olujẹjọ lọ si ọgba ẹwọn

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.