Ọmọ ọdun mẹtala dawati l’Akurẹ

Spread the love

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣi n wa ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtala kan, Beloved Ọlatunde, ti wọn lo dawati lati ọjọ Aje, Mọnde, ọṣe to kọja yii.

 

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ileewe alaadani ‘Ileri Ayọ’ to wa lagbegbe High School, niluu Akurẹ, ni wọn ti ri ọmọdebinrin ọhun kẹyin ko too di pe o dawati lọsan- an ọjọ naa. Ọkan ninu awọn agba iranṣẹ Ọlọrun to n ṣiṣẹ pẹlu ijọ Mountain of Fire niluu Zaria, nipinlẹ Kaduna, ni wọn pe baba ọmọ yii.

 

Ọdọ iya to bi i ni wọn ṣọ poun atawọn aburo rẹ n gbe niluu Akurẹ ki iṣẹlẹ ọhun too ṣẹlẹ. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph juwe iṣẹlẹ naa bii eyi to ba ni ninu jẹ. O di ẹbi bi Beloved ṣe dawati ru awọn obi rẹ pẹlu bo ṣe jẹ ko di mimọ fun wa pe awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe o da bii ẹni pe ọmọdebinrin ọhun nilo itọju daadaa ko too di ẹni ti wọn n wa kiri.

 

Ni ibamu pẹlu alaye to ṣe fun wa, o ni to ba jẹ pe ara ọmọdebinrin naa ya daadaa, ko ṣẹṣẹ yẹ ko wa ni nọsiri keji nileewe alakọọbẹrẹ pẹlu ọjọ ori rẹ. O ni o yẹ kawọn obi rẹ ti kọkọ tọju rẹ daadaa ki wọn too jẹ ko bẹrẹ ileewe. Bẹẹ lo ni ileewe awọn akanda ẹda, nibi to ti le ri itọju to peye gba lo yẹ ki wọn mu un lọ.

 

Joseph ni awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ takun-takun lati mọ ibi ti ọmọdebinrin naa wọlẹ si, o ni gbogbo bọrọ naa ba ṣe n lọ ni wọn yoo maa fi to awọn araalu leti.

 

 

 

 

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.