Ọmọ ọdun mẹrinla fẹẹ lu jibiti miliọnu meji l’Abẹokuta, atẹjiṣẹ iku lo fi ranṣẹ sẹni to fẹẹ gba

Spread the love

Ọmọ Ibo ni Tochukwu Anyika, ọmọ ọdun mẹrinla pere ni. Bo ti kere mọ yii naa ni wọn n gbe e wa si kootu Majisireeti n’Iṣabọ, l’Abẹokuta, nibi to ti n jẹjọ ẹsun idunkooko mọ ni nitori miliọnu meji, to ni bi wọn ko ba fun oun, oun yoo pa ọga ileeṣẹ Victor Vicagu to fi mẹseeji aṣekupani naa ranṣẹ si

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni wọn tun ṣafihan Tochukwu to wa ni SS1, nileewe girama kan l’Abẹokuta. Niṣe lo leju koko ninu igi idajọ to ti n dahun ibeere ti wọn n bi i.

Akọsilẹ kootu naa fi ye wa pe lọjọ keji, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, Tochukwu ki foonu rẹ mọlẹ, o si tẹ atẹjiṣẹ iku si ọkunrin onile itaja nla kan l’Abẹokuta, eyi ti orukọ rẹ n jẹ Victor Ezeama, to ni ileeṣẹ Victoru Vicagu ti wọn ti n ta awọn eroja ikọle.

Ohun ti Tochukuwu tẹ ranṣẹ si ọkunrin naa ni pe awọn kan ti san miliọnu kan Naira foun lati pa a, o ni bi oniṣowo naa ko ba fẹẹ padanu ẹmi ẹ lai tọjọ, ko tete fi miliọnu meji ranṣẹ si akaunti toun kọ sabẹ atẹjiṣẹ oun yii, ai jẹẹ bẹẹ, o ti ku tan, ki wọn gbe e sin lo ku.

Akaunti ọrẹ ẹ kan to n jẹ Ejike Michael ni ọmọ kekere yii ni ki Ọgbẹni Victor fowo naa ranṣẹ si, ṣugbọn ko sọ fun Ejike pe oun lo akaunti ẹ lati huwa to lodi sofin naa, igba tọrọ bẹyin yọ ni wọn mu Ejike mọ Tochukwu to huwa arufin.

Nigba to n ṣalaye are ẹ lọjọ Jimọ to kọja yii ni kootu naa, ọmọ yii sọ pe fiimu kan loun wo lọjọ toun tẹ atẹjiṣẹ naa, niṣe ni ẹnikan tẹ iru ẹ si baba olowo kan pe ko fowo ranṣẹ bi ko ba fẹẹ ku. O ni boun ti wo fiimu naa tan ni ero kan sọ soun lọkan pe oun naa le ṣe iru ẹ kẹ, boun ṣe ki iwe ileeṣẹ Victor Vicagu to wa niwaju oun mọlẹ niyẹn, oun wo ọkan lara awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ to wa nibẹ, oun si fi atẹjiṣẹ adunkooko mọ ni naa ṣọwọ si wọn, paapaa si olori oko ileeṣẹ naa ti i ṣe Ọgbẹni Ezeama.

Owo loun n reti, oun ro pe ọrẹ oun yoo gba alaati, yoo sọ foun, awọn yoo si jọ pin owo naa ni. Afi bo ṣe di pe ọlọpaa lo waa gbe oun, ti wọn tun gbe Ejike, ẹni ọdun mẹrinlelogun naa mọ ọn.

Njẹ ki lo fẹẹ fi miliọnu meji Naira ṣe pẹlu bi ọjọ ori ẹ ṣe kere to yii, ọmọ Ibo yii ni oun ṣaa kan fi atẹjiṣẹ ranṣẹ ni. Iya rẹ ati baba rẹ naa wa nikalẹ ni kootu lọjo yii, bẹẹ lawọn famili wọn naa pọ nibẹ ti wọn roju koko. Awọn obi ọmọ yii gba lọọya fun un, agbẹjọro naa si gbiyanju titi pe ki kootu ma ti i mọ ile awọn ọmọ alaigbọran ti ọjọ ori wọn ko ti i to mejidinlogun.

Ṣugbọn Adajọ agba Aliu Ṣonẹyẹ paṣẹ pe ki wọn maa gbe ọmọde toju ẹ le koko naa lọ si ọgba ẹwọn to ba ọjọ ori rẹ mu, eyi ti wọn n pe ni Booster to wa ni Adigbẹ, l’Abẹokuta, kan naa.

Lọọya ti wọn gba fun Tochukwu sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ ẹmi eṣu lo ti i to fi huwa naa, bo tilẹ jẹ pe eyi ko ṣee fidi ẹ mulẹ ni kootu. O ni ṣugbọn bi ẹmi eṣu ba wọle siiyan lara tan, ki i ṣee le jade bọrọ o. O ni ki adajọ jọwọ gba ọmọ Anyika laaye lati ṣe ọdun tuntun pẹlu awọn obi rẹ, bo ba si pari ọdun tan, ki wọn waa mu.

Adajọ loun ko gba iru ẹ mọ, lọmọ to jẹ ẹẹmẹta ọtọọtọ lo ti ṣi anfaani ti wọn fun un lati maa tile waa jẹjọ lo, ti ko yọju, to jẹ awọn obi rẹ yii naa ni wọn gbe e pamọ. O ni ki lọọya lọọ rin in lọna ẹtọ nipa tito awọn iwe ipẹ to yẹ, ki kootu too pari ijokoo lọjọ Ẹti naa, oun ko fẹ ọrọ ẹnu rara.

Lọọya ko riwee kankan to ti wọn fi pari iṣẹ ọjọ naa, bẹẹ lawọn obi ọmọ naa n ṣare soke-sodo lati jẹ ko ba wọn pada sile, ṣugbọn oju wọn nibẹ ni awọn wọda ọgba ẹwọn ti fa a jade ninu igi ijẹjọ, to wọn gbe e si mọto to n lọ sọgba ẹwọn taara.

 

 

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.