Ọmọ ọdun meloo ni ọ, nigba ti wọn ṣe ọdun FESTAC ni Nigeria?

Spread the love

Ẹni to ba ṣoju rẹ ni yoo le wi, awọn eeyan ti wọn ba mọ itan naa ni wọn yoo le royin, ṣugbọn ohun to daju ni pe ko sẹni kan to ri iran ọdun naa wo ti yoo gbagbe, lọjọ ti wọn bẹrẹ ọdun FESTAC nilẹ wa. Bi a ti n royin kinni ọhun bọ lati ọjọ diẹ, iroyin ọhun ko to afojuba, awọn ti wọn foju ri ọdun naa gan-an ni wọn yoo le mọ hulẹhulẹ ohun ti a n sọ. Fun odidi oṣu kan ni, ojumọ kan, ara kan, ojumọ kan, iṣẹlẹ kan, ilu Eko si n dun yungba, bẹẹ naa lo si kari gbogbo Naijiria, ọdun to ko gbogbo awọn eeyan dudu aye jọ ni. Tabi orilẹ-ede wo ni wọn ko ti wa. Awọn ara Somalia ko awọn onijo wa, awọn ara Zimbabwe ni ki lo ṣubu tẹ awọn, awọn ara Zambia wa pẹlu aarẹ ilẹ wọn, awọn eeyan dudu ilẹ Amẹrika ni ọdun naa yoo ṣoju awọn, bẹẹ lawọn oyinbo alawọ-dudu lati Jamaica, Venezuela, Brazil, Tobago wa tijo-tijo.
Lati Dahomey titi wọ Sierra Leone, lati Ghana titi de Abidjan, ni Ivory Coast, ati lati Kampala, ni Uganda, titi to fi de Liberia, lati Ginni titi wọ Ethiopia, lati Lesotho titi de Zaire, lati Cameroon titi de Congo, lati Togo titi de Senegal, lati Tanzania titi wọ Morocco, ati lati Algeria titi wọ Sudan. Ni apapọ, awọn orilẹ-ede mẹtalelaaadọta ni wọn n kopa ninu ọdun aṣa ati iṣe awọn adulawọ agbaye naa, wọn wa tile-tile ni. Ṣugbọn awọn ti wọn waa ṣe ere yii ko pọ to awọn ero iworan, awọn oyinbo ko ara wọn jọ, lati ilẹ Yuroopu (Europe) ati lati ọdọ awọn Aṣia, awọn Ṣinko ati awọn India, gbogbo wọn ni wọn rọ wa si Naijiria lọdun naa, lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 1977, ti ọdun naa si ti bẹre titi di ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii, kan naa, odidi oṣu kan ti ko sẹnikan ti yoo gbagbe ni. Loootọ ni mo wi fun yin, o le ju.
Ohun to ya gbogbo aye lẹnu ju ni asiko ọdun yii ni pe o fẹrẹ jẹ igba akọkọ niyẹn ti awọn alawọ funfun ati alawọ-dudu ti wọn pọ to bẹẹ yẹn yoo jọ pade ara wọn, ti wọn yoo jọ maa ṣere, ti wọn yoo jọ maa jo, ti wọn yoo jọ maa ṣe faaji, ti wọn yoo si jọ maa rin kiri, lai ni i si ẹni kan ti yoo bu ẹni keji pe alawọ-dudu bii ọbọ ni, tabi pe alawọ-funfun bii afin ni. Awọn oyinbo n ba awọn adulawọ jẹun, wọn n ba wọn jo, awọn mi-in ti wọn si jẹ oyinbo n sọ pe awọn kan funfun lawọ ni, eeyan dudu lawọn, nitori Afrika ni baba awọn ti lọ ko too lọọ gbe oyinbo niyawo, ki awọn too waye ni alawọ-funfun. Ọrọ naa de ori gongo nigba tawọn oyinbo mi-in n sọ pe awọn fẹẹ kọla, wọn ni ila ti awọn n ri loju awọn eeyan awọn yii fihan pe ojulowo ni wọn, bi awọn naa ba si kọla, ko sohun to buru nibẹ o jare, nitori ọmọ ọkọ lawọn, awọn ki i ṣe ọmọ ale.
Ohun to dara ki i fẹ ka ṣe oun o. Bi ipalẹmọ ọdun naa ti lọ to, awọn ohun meji kan fẹrẹ ko ifasẹyin ba kinni naa, o kan jẹ wọn tete dọgbọn si i ni. Akọkọ ni awọn oyinbo Britain, awọn ọga wa ni London, awọn ti wọn ti ṣejọba le Naijiria lori fun ọpọlọpọ ọdun. O da bii pe inu wọn ko fi bẹẹ dun si kinni naa, ati pe ni asiko naa, ede-aiyede wa laarin ijọba Naijiria ati ijọba ilẹ Gẹẹsi naa, nitori iku to pa Muritala Muhammed, ati bi ijọba Naijiria ti fẹsun kan Yakubu Gowon, ti wọn si ni ko wale ko waa jẹ ẹjọ, ṣugbọn ti awọn alaṣẹ ilu oyinbo yii da aburandà bo o mọlẹ, ti wọn ni ko le wale, ko duro ti awọn ni London, ko sohun ti ijọba Naijiria yoo fi i ṣe. Gowon ko si wale loootọ o, o jokoo sọdọ awọn oyinbo nibẹ. Eleyii n bi ijọba Naijiria ninu, wọn woju awọn oyinbo yii, wọn laali wọn daadaa, awọn oyinbo naa si binu pe Naijiria ri awọn fin.
Boya ni ko jẹ ohun to fa a ree ti wọn ko fi fẹ ki ọdun FESTAC naa jẹ aṣeyọri fun wa. Ohun ti wọn ṣe naa ni pe wọn fẹẹ di Naijiria lọwọ. Ere kan ti wa ti Naijiria fẹẹ lo lati fi ṣe ami ọdun yii, ere FESTAC ni wọn pe e, kinni naa ko si yatọ si ori Olokun. Ọjọ pẹ ti awọn gbẹnagbẹna ti gbẹ ere naa, awọn oniṣẹ-ọna, awọn agbẹgilere gidi ti iru wọn ko pọ lagbaaye ni wọn gbẹ kinni naa ni Ibinni, ṣe awọn meji ti wọn mọ kinni naa ju ni Naijiria niyẹn: Ile-Ifẹ, ati awọn Ibinni. Amọ ere naa ko si lọwọ ijọba Naijiria mọ. Awọn oyinbo Britain yii naa ni wọn ji i ko. Asiko ti wọn waa jagun ni Ibinni, ti wọn ni ọba ibẹ ri awọn fin, ti wọn si pa ọpọlọpọ eeyan, ti wọn dana sun aafin ọba Ibinni, ni wọn ji gbogbo ere naa ko lọ si London. Ọdun 1897 leleyii ṣẹlẹ, lati igba naa ni wọn si ti ko kinni naa pamọ si ọdọ wọn, bẹẹ wọn mọ pe ki i ṣe tawọn.
Nigba ti ọdun FESTAC yii waa n bọ, awọn ti wọn ṣeto naa ranṣẹ sibudo aṣa ti wọn ko kinni naa si ni London, iyẹn British Museum, wọn ni ki wọn fun awọn ni ere naa ki awọn lo o gẹgẹ bii ami ọdun yii, nigba to jẹ ohun to fi ọkan ninu ẹwa ati aṣa awọn adulawọ han ni, nitori ko si ibi ti wọn ko ti mọ ọn, ṣebi Olokun ni agba odo, ko si si ibi ti ko ti si omi okun. Awọn oyinbo yii si ti kọkọ gba pe wọn yoo fun wọn o, nigba to jẹ awọn naa ni wọn kuku ni nnkan wọn tẹlẹ, ọdọ wọn ni wọn si ti ko o lọ. Afi bi awọn oyinbo yii ṣe tun yipada biri lẹyin ti ọrọ iku Muritala ti dija yii, ni wọn ba bẹrẹ si i fi oni donii, ti wọn n fi ọla da ọla, wọn ko si sọ pe awọn ko ni i ko kinni naa silẹ titi ti ọjọ ọdun naa fi wọle. Igba ti wọn yoo gbe iṣe wọn de, ni wọn ba ni awọn ko ro pe awọn le ko o silẹ mọ jare, nitori ko ma di wahala lẹyin ọla.
Ọrọ wo ni yoo di wahala, Naijiria ni ki lo le di wahala nibẹ, ṣebi nnkan awọn ni. Awọn oyinbo yii ni ohun ti awọn n wi gan-an niyẹn, bi Naijiria ba waa ya a lo, ti wọn ko ba da a pada mọ nkọ, ṣebi wọn yoo ni nnkan awọn naa ni, awọn si ti gba a pada niyẹn. Wọn waa ni bi Naijiria ba fẹẹ ya a lo, a jẹ pe wọn yoo ṣe inṣọransi, wọn yoo si ko owo bii miliọnu meji kalẹ lati fọkan awọn balẹ pe bi wọn ba gbe ere naa lọ ti wọn ko ba gbe e pada mọ, awọn yoo fi owo wọn yii di i. Miliọnu meji Naira ki i ṣe owo kekere nigba naa, lasiko ti a wa yii, owo naa le ni biliọnu meji daadaa. Ni inu ba bi ijọba Naijiria, ni wọn ba wa fọto ere naa jade, wọn wa a ninu awọn iwe itan ilẹ yii, wọn si tun mu fọto ẹ jade ninu awọn iwe itan wọn niluu oyinbo, nibi ti wọn ko kinni naa pamọ si. Fọto yii ni wọn mu pada tọ awọn gbẹnagbẹna ilu Ibinni lọ.
Ohun ti a ba mọ, bii idan ni i ri, bẹẹ ni aigbọfa ni a n wo oke, ifa kan ko si ni para. Nigba ti ọwọ awọn gbẹnagbẹna ilu Ibinni tẹ aworan ere naa, ẹrin ni wọn bu si, ni wọn ba jokoo ti iṣẹ naa, nigba ti yoo si to ọsẹ meji ti wọn ti ko si i, wọn gbe kinni naa jade. Ohun to ya gbogbo aye lẹnu ni pe bi wọn ba ko awọn ere mejeeji si ẹgbẹ ara wọn, ati eyi ti awọn oyinbo ji ko lọ, ati eyi ti wọn ṣẹṣẹ ya, bi ẹni yẹn ko ba wo o daadaa, ko ni i mọ iyatọ laarin wọn. Bi awọn miiran tilẹ wo o lati oni titi di ọla, wọn ko ni i ri iyatọ kan ninu wọn. Ọrọ naa ya ijọba Britain lẹnu, o si doju ti wọn, nitori ohun ti wọn ro pe ko ṣee ṣe lo ti ṣee ṣe loju wọn yẹn. Ohun to si jẹ ki inu Olori ijọba Naijiria, Ọgagun Oluṣẹgun Ọbasanjọ dun dẹyin nigba ti wọn gbe ere naa fun un ree, to si n kọrin, ‘Wọn ro pe a o ni i le ṣe e, a ṣe e tan, oju ti wọn.’
Awọn agbẹgilere marun-un ni wọn gbẹ kinni naa ni Ibinni, ohun to si ya Ọbasanjọ ati awọn ti wọn jọ n ṣejọba lẹnu julọ nigba naa ni pe kinni naa ko gba wọn ju ọjọ diẹ lọ ti wọn fi gbe e jade. Awọn naa mọ pe ko si ẹni ti yoo ṣe bẹẹ niluu oyinbo, ko si gbẹnagbẹna oyinbo to le gba iṣẹ naa ti yoo ṣe e pari lasiko ti awọn gbẹnagbẹna Ibinni ṣe e yẹn. Ohun ti awọn oyinbo naa si ro niyẹn, wọn mọ pe ko le ṣee ṣe fun Naijiria lati ri kinni naa ṣe nibomi-in, itiju ni yoo si jẹ fun wọn nitori wọn ti pariwo faye pe ohun ti awọn yoo lo niyẹn. Nigba ti gomina ipinlẹ Bendel igba naa, Ọga Ologun Husaini Abdullahi, si gbe ere naa gẹgẹ de ọdọ Ọbasanjọ ni Dọdan Barrack, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu kin-in-ni, ọdun 1977, ohun to dun mọ olori ijọba naa ninu ju ni pe oju ko ti awọn, ibi ti awọn oyinbo Britain fi oju si, ọna ko ba ibẹ lọ rara.
Ọdun naa ku bii ọsẹ kan ni wọn ri ọrọ yii yanju, wọn si ti ro pe ko tun si iṣoro kan to n bọ ti awọn ko ni i le yanju mọ ni. Afi bi rogbodiyan mi-in ṣe tun ṣẹlẹ. Ohun to waa ṣẹlẹ yii ki i ṣe ti Naijiria nikan, ọrọ to fẹẹ ta ba araale ta ba ara oko ni. Nigba ti wọn n dana eto naa, lara awọn orilẹ-ede to n fi gbogbo ara ba wọn ṣe e ni awọn aladuugbo wa, iyẹn orilẹ-ede Bẹnnẹ. Ẹni to n ṣe olori ijọba ibẹ nigba naa ni Ọgagun Mathew Kerekou. Ọdun 1972 ni Kerekou yii gbajọba, nigba to si gbajọba lo yi orukọ orilẹ-ede rẹ pada si Bẹnnẹ (Benin). Ko too di igba naa, Dahomey ni orilẹ-ede naa n jẹ, bi gbogbo aye ti mọ ọn si niyẹn. Lati igba ti Kerekou ti waa gbajọba yii, ọrẹ lo n ba Naijiria ṣe, ko si ohun ti ijọba Naijiria n ṣe ti ko ni i ṣaaju ninu awọn alatilẹyin rẹ, nigba ti FESTAC yii naa si de, wọn jọ n sare ẹ kiri naa ni.
Ṣugbọn loru ọjọ ti o ku ọla ti wọn yoo bẹrẹ ọdun nla naa gan-an ni wahala gidi ṣẹlẹ nilẹ Bẹnnẹ, Kutọnu gbona kọja afẹnusọ. Ohun to ṣẹlẹ ni pe laarin oru ni awọn ajagunta kan de, awọn ajagunta oyinbo ni wọn, wọn de pẹlu ẹronpileeni adigboluja, wọn si de pẹlu ibọn ati awọn maṣin-gan-an-nu ti wọn lagbara gan-an. Bii aago kan oru ni wọn de, bi wọn si ti de ni baalu wọn balẹ dẹẹ si papa ọkọ-ofurufu ni Kutọnu. Awọn ara papa-ọkọ-ofurufu naa ko reti ẹronpileeni, nitori bẹẹ ni wọn ṣe n wo o pe iru ẹronpileeni wo lo foru rin wọlu yii. Amọ bo ti n balẹ bayii ni ina ibọn ati maṣin-gan-an-nu bẹrẹ si i jo bulabula, ti oko buruku si n tẹnu ibọn jo. N lọrọ ba di bo o lọ o yago, ẹni ori yọ o dile. Kaluku awọn oṣiṣẹ ati awọn ẹṣọ ti wọn wa ni ẹẹpọọtu Kutọnu yii lo fere ge e, igbẹ la a fewe, oko la a wa nnkan ọbẹ!
Ko sẹni to mọ ibi ti awọn ajagunta naa ti wa, ṣugbọn ohun to han si gbogbo eeyan ni pe ibi yoowu ti wọn ti wa, wọn ko ba daadaa wa, ija ni wọn gbe wa, ko si si ohun meji ti wọn waa ṣe ju lati le Kerekou kuro lori oye lọ. Wọn fẹẹ fi agbara gba ijọba lọwọ rẹ, nitori lati igba to ti wa lori ipo naa lawọn kan ti n wa bi wọn yoo ṣe le e lọ. Ẹẹmeji ni wọn ti mura lati fibọn yanju ijọba rẹ laarin ọdun1975 nikan, ṣugbọn Kerekou bori awọn ọta rẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ọta rẹ naa ko sinmi, wọn n ba a wọ ọ gidi ni. Eyi to kan mu iyalẹnu diẹ dani ni pe awọn ti wọn n yinbọn lati oju-ọrun yii, ti wọn gbe ẹronpileeni waa fi jagun ni Kutọnu, awọn oyinbo ni, ibi ti oyinbo si ti wa, ati bi ọrọ awọn eeyan dudu ṣe yara kan oyinbo bẹẹ ko ye awọn eeyan, iyẹn naa lo si jẹ ki awọn ṣọja Dahomey gbebọn tiwọn naa jade.
Nigba naa ni ina koju ina, ibọn koju ibọn, awọn ṣọja dudu koju awọn ṣọja funfun. Wọn ja ija naa titi ti ilẹ fi fẹrẹ mọ, nigba ti awọn oyinbo ajagunta yii si ri i pe afaimọ ki ilẹ ma mọ oloro awọn si gbangba, wọn gbera lojiji, wọn sa ko si inu ẹronpileeni wọn, wọn si fẹsẹ fẹ ẹ. Idunnu to kan wa nibẹ ni pe wọn ko ri ibi de ile ijọba, koda wọn ko jẹ ki wọn kuro ni agbegbe ẹẹpọọtu ti wọn de si ti wọn fi fibọn da wọn lẹkun a-n-ṣe-kọndu-kọndu, awọn ṣọja Bẹnnẹ paapaa sọ fun wọn pe ọkunrin lada, ati pe yoo ṣoro gan-an ki aṣa too wọle gbe ọmọ ewurẹ lọ. Ni gbogbo akoko ti ina ija naa fi n jo, Kerekou funra ẹ ti fara soko, o sa lọ dẹn-un dẹn-un, o jinna sile ijọba pata. Ta ni yoo ṣe, adiẹ paapaa gbọ ọjọ iku rẹ o poṣe titi, o ni ‘ṣio!’
Ọrọ naa bi ijọba Naijiria ninu gan-an. Akọkọ ni pe eeyan wọn ni Kerekou, wọn si jọ dajọ ayẹyẹ naa ni. Iyẹn ni wọn ṣe ro pe awọn oyinbo yii kan waa da kinni kan silẹ ni Afrika ti yoo di ọdun FESTAC ti awọn fẹẹ ṣe lọwọ ni. Ki lo de to jẹ lọjọ ti ọdun awọn adulawọ yoo bẹrẹ ni Naijiria ni wọn waa kọlu orilẹ-ede to mule ti wọn gan-an? Ki lo de to jẹ awọn oyinbo ajagunta ni wọn waa ṣe iṣẹ naa, ti ẹnikẹni ko si mọ ibi ti wọn ti wa. Titi ti ọrọ naa fi kuregbe-kuregbe, ko sẹni to le sọ pato ibi ti awọn oyinbo agbebọnrin naa ti wa, kaluku kan n fi atamọ mọ atamọ ni. Bi awọn kan ti ni awọn ti wọn fẹẹ gbajọba lọwọ Kerekou ni wọn pe awọn oyinbo naa wa, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe awọn ti wọn fẹẹ da Afrika ru ni.
Amọ adiro kan ko ni i gbona jan-in jan-in ko ma rọlẹ, ijọba Naijiria ko jẹ ki kinni naa da ọdun ọhun duro, bi wọn ti gbọ ni wọn ti sare ranṣẹ lọọ ba Kerekou, wọn fẹẹ mọ pe ko si kinni kan to ṣe ọrẹ awọn. Lẹyin ti wọn si ti mọ pe koko lara ogun rẹ le, wọn ko dawọ eto naa duro, wọn ni ki awọn ọmọ ọlọdun maa ba ọdun wọn lọ. Ṣe awọn ero kuku ti rọ de lati origun mẹrẹẹrin aye loootọ, wọn ko si ba ohun meji wa ju faaji ọdun lọ. Pupọ ninu wọn ko tilẹ mọ pe bi awọn ti n jo nni, gbẹkẹ ti bẹ ni Bẹnnẹ nitori awọn, ohun to jẹ wọn logun ni bi awọn yoo ṣe ṣe ọdun awọn, ti awọn yoo si ri nnkan gidi lọọ royin pada fawọn ti wọn ko wa nile. Bi ilẹ ọjọ keji si ti mọ ni ilu sọ kaakiri Eko ti i ṣe olu ilu Naijiria, ariwo nla bẹrẹ lati papa-iṣere nla, National Stadium, ni Suurulere, nibẹ ni wọn ti dana nla to jo kari gbogbo Naijiria.
Bawo lọdun naa ṣe lọ si gan-an? Eleyii di inu Alaroye ọsẹ to n bọ.

(80)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.