Ọmọ Ọṣọba yọ ara ẹ kuro ninu awọn oludije ti Amosun fa kalẹ

Spread the love

Iwe to n ṣafihan orukọ awọn oludije sile igbimọ aṣoju ipinlẹ Ogun ti jade gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ yii, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ṣe ni oun yoo gbe e jade. Orukọ Olumide Babatunde Ọṣọba ti i se ọmọ Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba naa wa ninu iwe yii, ṣugbọn ọkunrin naa loun ko ṣe, lo ba yọ ara rẹ kuro.

Iran wiwo ki i su oju ni awọn ohun to ti n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati ọjọ Abamẹta ti ipade ti waye laarin awọn eeyan Ila-Oorun ipinlẹ Ogun ati tawọn Iwọ-Oorun. Bi Ọladunjoye ṣe kede tiẹ pe wọn fipa mu oun lati gba ohun ti ẹgbẹ n fẹ wọle ni Olumide Ọṣọba naa yọ ara rẹ pẹlu atẹjade to fi sita pe oun ko ṣe.

Idi ti Olumide fi loun ko ṣe ni pe oun ko mọ nnkan kan nipa ipade ti wọn ti fẹnuko si yiyan awọn eeyan kan bii oludije. O ni iyalẹnu nla lo jẹ foun lati ri orukọ oun ninu iwe tuntun yii pe koun waa ṣoju wọn ni Guusu Abẹokuta, nigba to jẹ Ariwa Abẹokuta, Ọbafẹmi Owode ati Ọdẹda, loun ti ṣoju wọn laarin ọdun 2011 si 2015, ti ajọṣepọ oun ati wọn ko si daru titi dasiko yii. Ọmọ Ọṣọba loun ko ro o lati fi wọn silẹ lọọ dupo aṣoju ni Guusu ipinlẹ Ogun, nitori naa, oun yọ ara oun kuro ninu iwe Amosun, ou

Eyi ni bi wọn ṣe to orukọ awọn aṣoju naa gẹgẹ bo ti jade

Suraj Adekunbi- Yewa North/ Imẹkọ Afọn

Akinlade Abiodun Isiaq-Yewa South/ Ipokia

Ramon Rotimi- Ado Odo Ọta

Leke Adewọlu-Ifọ/Ewekoro

Mikhail Kazeem-Abeokuta North/ Ọbafẹmi Owode

Olumide Oṣọba-Abẹokuta South

Yinka Mafe-Ikenne/ Sagamu/ Rẹmọ North

Dayo Adenẹye-Ijẹbu Ode/ Odogbolu/ Ijẹbu North East

Biyi Ismail-Ijẹbu North/ Ijẹbu East/ Ogun waterside

Orukọ mẹta to jade fun ile igbimọ aṣofin ni:

Sẹnetọ Ibikunle Amosun- Ogun Central

Sẹnetọ Lekan Mustapha- Ogun East ati Oloye Tolu Ọdẹbiyi ti yoo ṣoju Ogun West.

 

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.