Ọmọ Ayọ Ọpadokun ti wọn lo jale l’Ọffa

Spread the love

Ole to ja to gbe fila lemọọmu, o ti gbe orukọ lemọọmu mọ ọn, nitori nigbakugba ti wọn yoo ba sọrọ, wọn yoo ni ohun to n dun awọn ninu ọrọ yii ni pe fila lemọọmu lole naa gbe lọ. Bẹẹ naa lo ri fun ọmọ kan to ba daran, yoo mu orukọ idile wọn ati ti awọn ti wọn bi i mọ ọn. Idi niyi ti ọmọ Yoruba ki i ṣee daran, nitori ile wọn ni wọn maa n wo ki wọn too ṣe ohunkohun, ọmọ to ba ba orukọ ẹbi jẹ, iru ọmọ bẹẹ ko ni i niyi nibi kan titi aye mọ. Ariwo ti lọ lọtun-un losi pe ọmọ Oloye Ayọ Ọpadokun wa ninu awọn ti wọn mu pe wọn digunjale niluu Ọffa, ti wọn si pa awọn eeyan lọ rẹpẹtẹ. Ole ti wọn ko ja iru rẹ ni ilu Ọffa ri, ti wọn ko si ja iru ẹ ri ni gbogbo Kwara. Njẹ o waa dara ko jẹ nigba ti wọn yoo waa wa a lọ wa a bọ, ọmọ ọkan ninu awọn aṣaaju ilu naa wa ninu awọn to ṣe iṣẹ aburu bẹẹ. Abi ta ni ko mọ Ayọ Ọpadokun. Oore pẹ, aṣiwere gbagbe! Nigba ti ogun le niluu yii lọjọsi, ti wọn n gbe awọn eeyan ti mọle, ti wọn n ju wọn sẹwọn, ti wọn si n pa awọn mi-in, Ayọ Ọpadokun wa ninu awọn ti wọn duro, ti wọn dojukọ ibọn Abacha, ti wọn si tori rẹ di ero aja-ilẹ, nibi ti wọn ti wọn mọ fun ọjọ to pẹ gan-an. Bi Ayọ Ọpadokun ba fẹẹ lowo nigba naa, yoo ni in, lasiko to jẹ gbogbo ẹni to ba loun faramọ ti Abacha lo n ri ṣe. Ṣugbọn ko ṣe bẹẹ, ẹyin awọn agbalagba Yoruba ti ko sowo lọwọ wọn lo wa, wọn si jọ ja ija naa ni. O waa ṣe jẹ pe ọmọ alagbara lo n ya ọlẹ, o ṣe jẹ iru ọmọ Ọpadokun ni yoo huwa itiju bayii. Ṣugbọn bi ọrọ aye ti ri niyẹn, ki i ṣe gbogbo ọmọ ti eeyan bi ninu ni i jọ ni tabi ti i mu iwa ẹni, ki Ọlọrun ma fi oloriburuku ọmọ ṣe tẹni ni, ki Ọlọrun ma si fun wa lọmọ ti yoo ba iṣẹ owurọ ẹni jẹ. Ko si ẹkọ ti ẹ le fun iru awọn ọmọ bẹẹ ti wọn yoo gbọ, wọn yoo pada jade nibi ti ẹ ba fi wọn pamọ si ni. Ọmọ to jale yii ki i ṣe ọmọ kekere, ọmọ to ti n lọ si ogoji ọdun, oun naa ti dagba, o ti bimọ, o ti n ṣe aye rẹ, ko si ohun to kan Ayọ Ọpadokun mọ rara ninu ohun to ṣe. Ṣebi awọn ọmọ Ọpadokun mi-in wa ti wọn ti ṣe lọọya, ti awọn mi-in si ni iṣẹ gidi lọwọ, eleyii kan ya bi yoo ti ya ni tirẹ ni. Eeyan ko ni i tori ọmọ abanilorukọ jẹ yii gbagbe iwa ati awọn aṣesẹyin Ọpadokun, ika to ba ṣẹ ni ki ọba ge, ohun to ba tọ si iru ọmọ olóríi-bámbáṣì bayii ni ki ijọba ṣe fun un. Ko ju bẹẹ lọ!

(412)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.