“Ọmọ-ale Ilọrin nikan ni ko ni i ṣatilẹyin fun Saraki lati dupo aarẹ” Shehu

Spread the love

Gbajugbaja oniwaasi ọmọ bibi ilu Ilọrin, Sheik Usman Sannu Shehu, ti kede rẹ pe asiko ti to fun ilu Ilọrin lati de ori ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria.

O ni awọn aṣaaju ilu Ilọrin ti gbadura fun iru nnkan bẹẹ, yoo si wa si imuṣẹ.

Shehu sọ lopin ọsẹ to kọja niluu Ilọrin pe o ti jẹ akọsilẹ pe Olori ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Abubakar Bukọla Saraki, maa di aarẹ orilẹ-ede Naijiria, nitori naa, o rọ gbogbo ọmọ bibi ilu naa lati gbadura, ki wọn si ṣiṣẹ tọ bi Saraki yoo ṣe de ori ipo naa.

O  waa ṣekilọ fun awọn to ti ri jẹ labẹ iṣejọba ẹbi Saraki lati fopin si gbigbe ogun ti erongba rẹ, o ni ọmọ ale Ilọrin nikan ni ko ni i ṣatilẹyin fun Saraki lati dupo aarẹ.

Shehu ni: “A ti gba ilu Ilọrin ati Kwara kuro loko ẹru, ko si ojulowo ọmọ bibi Ilọrin to gbọdọ ta ilu yii soko ẹru oloṣelu Eko labẹ ṣiṣe oṣelu.

” Awawi ti awọn to n tako Saraki maa n sọ ni pe Saraki ko yan awọn sipo tabi o gbe ipo to yẹ ko jẹ ti awọn fun ẹnikan.”

O ni bi Saraki ba di aarẹ, yoo mu idagbasoke ba ipinlẹ Kwara ati ilu Ilọrin, idi eyi si lo ṣe yẹ ki awọn ṣatilẹyin fun un.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.