Omiyale: Gomina Oyetọla bẹrẹ atunṣe awọn oju-odo

Spread the love

Florence Babaṣọla

Latari ọsẹ nla ti iṣẹlẹ omiyale ṣe lawọn agbegbe kan nipinlẹ Ọṣun lọsẹ to kọja lọhun-un, ijọba ti bẹrẹ iṣẹ lori mimu ki oju awọn odo fẹ si i, ati kiko awọn idọti ti wọn ti rọ di ojuna odo kuro.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja ni awọn ọkọ nla-nla ti wọn fi n ṣiṣẹ naa de siluu Oṣogbo, ọjọ keji lo si ti bẹrẹ iṣẹ kaakiri awọn agbegbe tijamba omiyale ọhun ti ṣọṣẹ.

Lasiko abẹwo rẹ sibi iṣẹ naa, Gomina Gboyega Oyetọla ṣalaye pe igbesẹ kiakia tijọba oun gbe lori ọrọ naa ko ṣẹyin adehun idaabobo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun toun ṣe lasiko ipolongo ibo.

Oyetọla ṣalaye pe bi ọpọlọpọ awọn agbegbe ṣe ri nipinlẹ Ọṣun lo ṣokunfa bi omiyale ṣe n tete raaye ṣẹlẹ nibẹ, ati pe ijọba oun ko ni i kuna lati wo awọn ile ti wọn ba wa leti odo lati le daabo bo ẹmi awọn ti wọn ba n gbenu ẹ.

Bakan naa lo rọ gbogbo awọn ti wọn maa n da idọti sinu odo ati si eti odo lati jawọ ninu iru iwa bẹẹ, nitori niwọn igba ti omi ko ba ti raaye kọja bo ṣe fẹ, o di dandan ko maa ya kaakiri.

Gomina sọ siwaju pe ijọba yoo gbe igbimọ amuṣeya kan kalẹ laipẹ ti wọn yoo maa ri si bi awọn eeyan ṣe n da ilẹ kaakiri, ẹnikẹni ti ọwọ ba si tẹ yoo foju wina ofin ijọba.

O ni ki i ṣe ilu Oṣogbo ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ọṣun nikan nigbesẹ lila oju agbara tijọba oun gun le bayii yoo ti waye, wọn yoo lọ kaakiri awọn agbegbe mi-in bii Ifẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu ọrọ ọkan lara awọn ti wọn fara kaasa iṣẹlẹ omiyale naa, Ọlayiwọla Gbadewo, o dupẹ lọwọ ijọba fun igbesẹ akin naa, bẹẹ lo ṣeleri pe awọn yoo fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati ri i pe iru iṣẹlẹ omiyale bẹẹ ko tun ṣẹlẹ mọ.

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.