Oluwoo sorenda: Oonirisa ni baba gbogbo wa

Spread the love

Ahesọ lawọn oniroyin kọkọ pe ọrọ naa nigba ti wọn gbọ pe Oluwoo ti ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu 1 yoo kopa nibi ipade awọn lọbalọba ipinlẹ Ọṣun to waye laafin Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi lọsẹ kọja. Ko si nnkan to fa eleyii ju wahala to ti fi ọpọlọpọ oṣu wa laarin Oluwoo ati Ọọni lọ.

Bii mọlẹbi la gbọ pe Ọba Akanbi ṣe maa n ṣe nile awọn Ọọni Ogunwusi ko too di pe awọn mejeeji jọba, ko si si gbọnmi si i omi o to o laarin wọn rara.

Lẹyin tawọn mejeeji jọba, ibaṣepọ yii tun dan mọran, afi igba ti nnkan deede yi biri lai si ẹni to mọ pato ohun to ṣẹlẹ. Lara wahala to ṣẹlẹ nigba naa, gẹgẹ bi igbagbọ awọn eeyan ni bi Ọba Akanbi ṣe deede sọ orukọ ọmọ ti iyawo rẹ, Olori Channel, bi ni Oduduwa, eleyii ti gbogbo eeyan mọ pe Ọọni lo n jẹ Arole Oodua, ṣe ni Oluwoo ni Oduduwa gan-an lọmọ oun yoo maa jẹ.

Bakan naa ni Oluwoo ti fi ọpọlọpọ igba sọ oniruuru ọrọ nipa ipo Ọọni lawọn ayẹyẹ, titi to fi de ori igba ti Oluwo kegbajare pe ṣe ni Ọọni ran awọn ẹṣọ ẹ lati kan oun labuku nibi ipade awọn ọba nla nla lorileede yii to waye niluu Portharcourt laipẹ yii.

Amọ ṣa, manigbagbe ni ọjọo Tọsidee to kọja, iyẹn ọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun yii, jẹ nigba ti Oluwoo wọ aafin Ọọniriṣa pẹlu awọn ọba mi-in nipinlẹ Ọṣun fun ipade pataki naa, eleyii to jẹ ẹlẹẹkeji iru ẹ latigba ti Ọọni Ogunwusi ti gun ori itẹ awọn baba nla rẹ.

Nibi ipade naa la ti ri awọn ọba ti wọn to ogoji, lara wọn ni Ọba Adedapọ Alayemọrẹ ti Ido-Ọṣun, Ọwa ti Imẹsi Ile, Aragberi ti Iragberi, Aragbiji ti Iragbiji ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu ọrọ tirẹ, Alayemọrẹ ti Ido-Ọṣun sọ pe ilẹ Oodua ni aafin Ọọni, o ni, “Ibi ni gbogbo wa ti kuro, ki i ṣe ni ilẹ Yoruba nikan, titi to fi de Warri, Onitsha, Benin ati bẹẹ bẹẹ lọ, ibi yii ni gbogbo wa ti gba ade ti a n de sori. Eredi ipade oni ni lati san ọna ti ọla ati ọwọ yoo fi wa fun ipo lọbalọba, ati bi irẹpọ ati iṣọkan yoo ṣe tubọ fidi mulẹ si i. Inu wa dun pe Oluwoo tilu Iwo wa nibi, amu oriire wa ni Ọọni Adeyẹye jẹ, ilẹ Yoruba si gbọdọ wa ni mimọ.”

Nigba tawọn oniroyin beere eredi ahesọ pe Oluwoo pe ara rẹ ni Emir laipẹ yii, Ọba Adewale Akanbi ni, “Awa ni baba gbogbo yin, awa ni baba Buhari, awa ni baba Arẹgbẹsọla, Ọọni ni baba gbogbo wa, ko si ilu ti Ileefẹ jade ninu ẹ, gbogbo ilu lo jade lati Ileefẹ, Ifẹ la ti mu gbogbo ade nilẹ Yoruba, Kabiyesi Ọọniriṣa lo si n ṣoju Oodua. Ohun to ba wu yin ni kẹ ẹ pe mi, bo ba wu yin ẹ pe mi ni Igwe, Tupac, Obi, Emir, bo ba wu yin ẹ maa bu mi, emi ni baba gbogbo yin”.

Ninu ọrọ Ọọni Adeyẹye Ogunwusi, ẹni to jẹ alaga igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọṣun ati niha Iwọ-Oorun Guusu orileeede yii, o ni dingi awokọṣe ni iha Iwọ-Oorun Guusu orileeede yii jẹ, idi si ni pe a gbe aṣa ati iṣe wa ga kọja ọrọ ẹsin. O ni “A fẹẹ fi idi eleyii mulẹ bẹrẹ lati ipinlẹ Ọṣun, ko si nnkan kan to gbọdọ ṣe aṣa ati iṣe wa, ogun (heritage) wa ni.

Oluwo ti ilu Iwo naa wa nibi, orukọ ti a mọ ọn mọ niyẹn, a ko fẹẹ feti si ọrọ ahesọ, ọkan ni wa, iṣọkan yoo si maa tẹsiwaju nilẹ Yoruba.

“Eredi ipade oni ni lati tun le ran ara wa leti pe aṣa wa lagbara ju ẹsin lọ. Ko si ija kankan laarin emi ati Oluwoo, ara Ifẹ ni Iwo wa, emi ni Arole Oodua, ṣe ni mo kan n mojuto ibi yii fawọn to ku. A gbọdọ lepa iṣọkan ati ifẹ, ka baa le jẹ awokọṣe rere fawọn oloṣelu. Asiko oṣelu la wa yii, a gbọdọ jẹ ki wọn ri ẹkọ ifara ẹni jin lati ara awa lọbalọba”

Lẹyin eyi ni wọn pari ipade naa pẹlu awẹjẹwẹmu, ti onikaluku si rẹrin-in pada siluu rẹ. Igbagbọ awọn eeyan si ni pe ifẹ tuntun laarin awọn ọba mejeeji yii yoo maa tẹsiwaju, ko si si eyi ti yoo da a ru laarin wọn.

 

(177)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.