Oluṣẹgun lu iyawo ẹ pa niluu Ogbomọṣọ, o ni ko tete se ounjẹ foun

Spread the love

Bi ọdun Keresi ṣe maa n larinrin to niluu Ogbomọṣọ nitori ti awọn kristẹni pọ nibẹ ju awọn ẹlẹsin mi-in lọ, ohun ibanujẹ to ṣẹlẹ si idile meji kan, Ọlajide ati idile Ọlaogun, ko ni i jẹ ki wọn roju raaye ṣọdun ọhun lọdun yii. Ọdun ku ọjọ mẹsan-an lawọn Ọlaogun padanu Ruth, ọmọ wọn. Ọ̀fọ̀ ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ọhun ni ko ni i jẹ ki wọn fidunnu ṣọdun, nitori oku ẹ ṣi wa ni mọṣuari, nibi ti awọn dokita ti n ṣewadii ohun to pa a titi ti akọroyin wa fi pari akojọpọ iroyin yii.

 

Airoju to ba wọn ni idile Ọlajide tun ju iyẹn lọ. Lọna kin-in-ni, ọmọ wọn, Oluṣẹgun Ọlajide lo lu Ruth Ọlajide to jẹ iyawo ẹ pa. Nitori naa, yatọ si pe ọfọ to ṣẹ awọn Ọlaogun kan awọn paapaa, Oluṣẹgun ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa, ibẹ ni yoo ti ṣọdun Keresi lọla, bi ọdun tuntun (2019), paapaa ko ba ba a nibẹ, dajudaju, inu ahamọ ọgba ẹwọn ni yoo ti ṣọdun tuntun.

 

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Mọnde ọjọ kẹtadinlogun (17), oṣu kejila, ọdun 2018, yii ti iṣẹlẹ ọhun waye, ounjẹ lo dija silẹ. Nigba ti Oluṣẹgun de lati ibi to ti n ṣiṣẹ, ko ba ounjẹ nilẹ, n lo ba fa ibinu yọ si iyawo ẹ. Ohun to si dija ko ju bẹẹ naa lọ. Nigba ti iyawo yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọkọ ti bẹrẹ si i rọjo ikuuku le e lagbari.

 

Ile ori oke ni Oluṣẹgun ati Ruth n gbe laduugbo Alapata, nitosi Sọọ-Meeli, niluu Ogbomọṣọ. Nigba ti iyawo ri i pe ẹmi oun n bọ lọ, o sa jade, o si mu ọna isalẹ ile ọhun pọn, ṣugbọn lilu lọkọ ẹ fi sin in de isalẹ, to si tun le e de oju titi nita titi ti obinrin naa fi ṣubu, to si n ja raparapa nilẹ.

 

 

Awọn alabaagbe wọn ninu ile naa ni wọn lọọ gbe Ruth dide nibi to ṣubu si, ti ẹjẹ si ti bẹrẹ si i gba imu ati agbari ẹ jade. Ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ keji lo dagbere faye.

 

Ọkọ ẹgbọn oloogbe, Ọgbẹni Taiwo Ajala, ṣalaye fakọroyin wa pe, “laaarọ ọjọ keji ti Oluṣẹgun na iyawo ẹ lẹgbọn ẹ kan to n jẹ Godwin waa tufọ Ruth fun wa nile wa. O (Godwin) ni awọn araadugbo ti Ruth ati ọkọ ẹ n gbe ni wọn pe oun lori foonu pe ki oun tete maa bọ waa gbe oku ti aburo oun pa, nitori Oluṣẹgun ti lu iyawo ẹ pa.

 

“Igba ti awọn alabaagbe wọn maa de ibi ti iyawo ṣubu si loju titi, wọn ri i pe ọkọ ti fẹẹ lu u pa, ẹjẹ ti n jade lori ati nimu ẹ. Nigba ti awa gan-an debẹ laaarọ ọjọ keji, a o ba ẹmi lara Ruth mọ, loootọ lo n mi, ṣugbọn ko le sọrọ, ko tiẹ mọ pe ẹnikankan wa lọdọ oun paapaa.

 

“Ọkunrin yẹn ko ya si ti iyawo ẹ rara. O kan n wo o niran ni. Nigba ti awọn ẹgbọn ẹ de lati ile tiwọn ni wọn ṣẹṣẹ gbe Ruth lọ si ọsibitu.”

 

Gẹgẹ bii iwadii akọroyin wa, agbẹ ni Oluṣẹgun to jẹ ọmọ bibi agboole Lemọ́lẹ̀, niluu Ogbomọṣọ. O da oko koko nla si ipinlẹ Ondo. ***Ninu to si maa n lọ ṣabẹwo si iyawo ẹ naa, ija loun atiyawo ẹ maa n ja ṣaa, a si maa lu obinrin naa nilukulu lori ọrọ ti ko to nnkan.

 

Aburo Ruth kan to n jẹ Adewuyi fidi eyi mulẹ, o ni “wọn (Oluṣẹgun ati iyawo ẹ) ti maa n ja tẹlẹ ta a ti maa n pari ẹ. Aaimọye igba lawọn obi wa ti pari ija fun wọn. Ija naa ni wọn ja nigba kan ti iyawo fi lọọ lo oṣu kan nile wọn ko too di pe wọn pari ẹ.

 

“A ri Oluṣẹgun lalẹ ̣ọjọ to ku ọla ti iṣẹlẹ yẹn maa ṣẹlẹ. Awa tiẹ n ba a sọrọ lori bo ṣe maa n lu iyawo ẹ lọjọ yẹn, a jẹ ko mọ pe ki i ṣe nnkan gidi ni fun ọkunrin lati maa n lu iyawo ẹ. Aṣe gbogbo ọrọ ta a ba a sọ lọjọ yẹn ko wọ ọ leti, afi bi mo ṣe gbọ lọjọ keji pe o ti na Anti Ruth pa.

 

“Ọrẹ lemi ati Oluṣẹgun jẹ sira wa. Mi o ri ọti lẹnu ẹ ri, ṣugbọn gbogbo bo ṣe maa n ṣe pẹlu iyawo ẹ ju tẹni to n muti gan-an lọ.”

 

ALAROYE gbọ pe kaka ki Oluṣẹgun ṣe aajo iyawo ẹ lẹyin to fi lilu han an leemọ tan, nigba tobinrin naa ku tan lo ṣẹṣẹ n sare kiri. O lọọ fi iroyin iku ẹ to awọn ọlọpaa leti, ṣugbọn ohun to sọ fun wọn ni pe aisan lo pa iyawo oun.

 

O ni ileewosan ti oun ti lọọ tọju ẹ naa lo ku si, oun si fẹẹ wa sọ fun awọn ọlọpaa ko too di pe awọn ẹbi obinrin naa de. Ko tilẹ sọrọ lọ sibi ija ti wọn ja rara debi ti awọn agbofinro yoo fi le mọ pe oun funra ẹ lo fi lilu yọ ile aye lẹmi-in iyawo ẹ, ta lo jẹ fi ọbẹ to nù jẹṣu.

 

Ṣugbọn esi ti agbẹ onikoko yii ko reti lawọn ọlọpaa fun un. Wọn ni bi iyawo eeyan ba ku sibi to ti n gba itọju nileewosan, ṣe agọ ọlọpaa lọrọ waa kan. Asiko yii lọkunrin ti ko le ti i ju ẹni ọgbọn (30), ọdun lọ yii ṣẹṣẹ waa tufọ iku Ruth fawọn eeyan ẹ lori ẹrọ ibanisọrọ.

Awọn ọlọpaa teṣan Arowomọle ti Oluṣẹgun funra ẹ ti kọkọ lọọ rojọ ibẹ́rí fun niluu Ogbomọṣọ naa ni wọn pada fi pampẹ ọba gbe e ni kete ti awọn ẹbi Ruth ti fidi ẹ mulẹ pe ọdaju ọkunrin ti awọn fọmọ fun lo lu awọn lọmọ pa, ti wọn si lọọ fẹjọ afurasi ọdaran naa sun awọn agbofinro.

 

Nigba to n bakọroyin wa sọrọ, ẹgbọn Ruth, Dokita Simeon Ọlaogun sọ pe ẹni ti ko yẹ ki ofin ṣiju aanu wo ni Oluṣẹgun nitori ọmọluabi eeyan kan ko le lu eeyan ẹlẹran ara bii tiẹ nilukulu to bẹẹ ti yoo fi fi ẹṣẹ fọ ọ lori ati imu titi ti oluwarẹ yoo fi j’Ọlọrun nipe.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “emi o si nile lọjọ yẹn, ori foonu ni wọn ti fi to mi leti. Ohun to pamọ fun eeyan, kedere lo han si Ọlọrun. Ija yẹn ko ṣoju ẹnikankan debi ti eeyan yoo le mọ boya nnkan ija oloro lo fi lu iyawo ẹ. Ṣugbọn ohun ti gbogbo eeyan mọ ni pe ọmọkunrin yẹn lo lu iyawo ẹ to fi ku. Wọn si lo ti maa n lu u bẹẹ tẹlẹ”.

 

Bo tilẹ jẹ pe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adekunle Ajiṣebutu, ko fidi iroyin yii mulẹ nitori ti ko gbe ipe ti akọroyin wa pe e lati mọ ibi ti awọn agbofinro ba iṣẹ de lori ọrọ naa, ALAROYE gbọ pe wọn ti gbe Oluṣẹgun lọ si ẹka to n tọpinpin iṣẹlẹ iṣekupani fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fun iwadii.

 

O ṣe ni laaanu pe awọn to yẹ ki wọn jẹrii tako Oluṣẹgun ko ṣetan lati ran awon ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn. Idi ni pe lati ọjọ ti Ruth ti ku, ti awọn agbofinro si ti mu ọkọ obinrin naa ni gbogbo awọn araale ọhun ti wọn le sọ nipa ija ọhun ti sa lọ bamubamu, ko si sẹni to ti i yọju sile ninu wọn titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

 

Inu oṣu kẹwaa, ọdun 2016, ni Oluṣẹgun ati Ruth fẹra wọn niṣu lọka pẹlu igbeyawo alarinrin. Ni bayii ti wọn ti pa obinrin telọ naa ni kekere, ọmọkunrin ọmọ ọdun meji kan ṣoṣo to bi fun ọkọ ẹ ti di tawọn ẹbi ọkọ ẹ bayii.

Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, ileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ (LAUTECH), to wa niluu Ogbomọṣọ loku Ruth wa, nibi ti wọn ti n ṣayẹwo si i lati mọ ohun to ṣokunfa iku ẹ, nigba ti Oluṣẹgun ti wa ninu ahamọ awọn ọlọpaa atọpinpin, nibi ti wọn ti n fi oriṣiriṣii ibeere po o nifun pọ lori ohun to mọ nipa iku iyawo ẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.