Olukọ ileewe pokunso ni Kano

Spread the love

Iyalẹnu gbaa niku olukọ kan, Fẹmi Oguntumi, to n gbe lagbegbe Dakata Quaters, nipinlẹ Kano, ṣi n jẹ fawọn aladuugbo rẹ nigba ti wọn kan an nibi to pokunso si lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

A ri i gbọ pe Karish College, to wa niluu Kawaji, lọkunrin naa ti n kọ awọn ọmọ lẹkọọ, ẹnikan ko si ro o si i pe o le deede gbẹmi-in ara rẹ ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ to pa ara rẹ yii.

Ohun to waa mu ki ọrọ ọkunrin yii yatọ si ti ọpọ eeyan to n dẹmi ara wọn legbodo ni pe Fẹmi ko kọ lẹta kankan silẹ lati fi ṣalaye idi ti oun fi pa ara oun sinu yara.

Eyi lo mu alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kano, DSP Haruna Abdullahi, fi atẹranṣẹ sita pe awọn ti fi oku ẹ ranṣẹ si ileewosan Murtala Muhammad Hospital, lati ri i daju pe ki i ṣe pe wọn pa ọkunrin yii ti wọn si fi oku rẹ kọ sibi faanu ile rẹ bii ẹni pe o pokunso.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni iwadii awọn ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun to ṣokunfa iku Oguntumi gan-an.

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.