Olubadan kan ku, wọn fi Olubadan mi-in jẹ, n lawọn oloṣelu ba sinmi agbaja fodidi ọsẹ kan

Spread the love

Awọn iṣẹlẹ nla nla mẹta ọtọọtọ lo kọkọ ja lu wọn ni West nipari oṣu karun-un, titi wọ inu oṣu kẹfa, ọdun1964. Olubadan jẹ Ọlọrun nipe; awọn oṣiṣẹ daṣẹ silẹ; ṣugbọn eyi to kan olori ijọba Oloye Ladoke Akintọla, Igbakeji rẹ, ati awọn agbaagba ẹgbẹ Dẹmọ ju, ti wọn si fẹẹ ja nitori ẹ ni ti Michael Okpara, olori ẹgbẹ oṣelu NCNC, to ni oun yoo ṣe abẹwo si gbogbo ilu ati agbegbe ni Western Region. Ọrọ naa ko ba wọn lara mu, wọn ni ki lo n wa, ki lo fẹẹ waa ṣe, ta lo pe e, awọn Yoruba ko fẹ ẹ, Ibo ni, ọmọ ajokuta-ma-mumi ati bẹẹ bẹẹ lọ. Bẹẹ apani ki i fẹ ki wọn mu ida kọja niwaju oun ni o. Ohun to jẹ ki ọrọ yii mu wọn lara ju ni pe wọn mọ ohun ti ẹgbẹ NCNC le ṣe, ọpọlọpọ eeyan ni wọn si fẹ ti ẹgbẹ naa ni awọn igberiko, bi Akintọla funra rẹ si ṣe gbe Okpara wa silẹ Yoruba ni 1962 ree pe ko waa ba awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ sọrọ ki wọn ṣe toun.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un, (May 26), ni 1964 yii, ni Olubadan Isaac Babalọla deede sun ti ko ji mọ, ọba naa waja loju gbogbo ọmọ ilu Ibadan ati awọn ara Western Region patapata. Ohun to mu iku ọba naa la ariwo lọ ni pe ọkan ninu awọn ọba ọmọwe ti yoo kọkọ jẹ ni ilu Ibadan ni, koda, ko si ọba kan to kawe to o titi asiko naa ninu awọn ọba to ti jẹ. Oun lọba Ọmọwe Akọkọ to gori oye nilẹ Ibadan. Iwe naa pọ debii pe ọkan ninu awọn olori ijọ CAC ni Naijiria ni, ọkan ninu awọn oludasilẹ ati agbatẹru ijọ naa ni ko too di ọba rara, igba kan si wa ti wọn fi i ṣe olori  ijọ naa lasiko ija, ti wọn ni oun nikan lo le ba wọn yanju ọrọ naa. Nigba to si di ọba tan, ko tun fi ijọ naa silẹ, gbogbo ẹsin ati aṣa ibilẹ rẹ ko si di igbagbọ ọhun lọwọ, aṣaaju CAC ti wọn mọ kaakiri aye nigba naa ni.

Ipo yii jẹ ki iṣejọba rẹ yatọ pata n’Ibadan, bi rogbodiyan oṣelu si ti pọ to, Ọba Akinyẹle ko si ninu awọn ti wọn ba nidii palapala, koda, ko ba wọn kopa ninu rẹ, nigba ti ọrọ ba ruju nikan ni wọn maa n ke si i, nitori oye minisita ti ko niṣẹ kan pato (Minister Without Portfolio) lo jẹ. Nigba tawọn ọba to ku doloṣelu, Akinyẹle ko si ninu wọn, idi si ni pe o ti ka ara rẹ kun baba gbogbo ilu, to jẹ nigba ti tọtun-tosi ba ja, oun nikan ni yoo duro laarin lati laja fun wọn, ti yoo si le dajọ naa sibi ti ẹjọ wa gan-an, ki ẹni to jẹbi gbọ ko mọ, ki ẹni to jare naa si fi iye denu. Ohun ti iku rẹ ṣe mi gbogbo ilu Ibadan titi ree, bo si tilẹ jẹ pe ọmọ ọdun mejilelọgọrin (82), ni baba naa ko too di pe o lọ yii, awọn mi-in ni awọn ko mọ pe ọjọ ori rẹ to bẹẹ rara, nitori ko ṣiwọ akitiyan, bẹẹ ni iṣẹ rẹ ni ṣọọṣi ati niluu ko tori rẹ dinku, piri lolongo n ji ni.

Fun ọpọlọpọ nnkan lawọn ti wọn n ṣejọba ni Western Region fi gbojule Ọba Akinyẹle, wọn si ti mọ pe ọrọ rẹ, bi itakun ko ba ja ni, ọwọ ko ni i ba ọkẹrẹ, ko si igba ti wọn yoo de ọdọ rẹ ti wọn ko ni i ri ọna abayọ, nitori baba lo jẹ si gbogbo wọn. Ṣe ki i kuku i ṣe pe oun naa ko ti i ṣiṣẹ ijọba ri, o ti ṣe e ri daadaa ko too waa jokoo fẹyinti, ko si too di ọba alade le gbogbo wọn lori. Ọdun 1882 ni wọn bi i, oun gangan ni wọn bi le Biṣọọbu Anglican ilu Ibadan, Bishop Alexander Akinyẹle. Ẹṣin iwaju ni tẹyin yoo wo sare ni ọrọ naa jọ, nitori lati ilẹ ni ko ti si yiya sọtun-un-sosi fun Akinyẹle, bo ti yẹ ko bẹrẹ ileewe lo ti bẹrẹ, ileewe awọn onigbagbọ, St Peters Day School, ni Arẹmọ, n’Ibadan naa kọkọ lọ, nibẹ lo si ti kawe sitandaadi ti wọn n fi bii ọdun mẹsan-an ka nigba naa jade, eleyii ki i ṣe nnkan kekere rara lọdun 1897.

Ọdun 1898 lo wọ ileewe CMS Grammar School, nitori to ṣe daadaa nigba to jade iwe sitandaadi to ka. Odidi ọdun mẹsan-an lo fi wa nileewe yii, nitori lọdun 1907 lo jade kuro nibẹ. Lasiko yii, o ti di ọmọwe daadaa, nitori iwe mẹwaa igba naa, bii ẹni to lọ si yunifasiti to gba oye Masters lasiko yii ni. Koda, nigba naa, ọpọlọpọ awọn oyinbo ti wọn n ṣe akoso Naijiria ko kawe ju bẹẹ lọ. Eyi lo fa a to fi jẹ iṣẹ kọsitọọmu lo wọ bo ṣe de, to si di ọga nibẹ, ohun kan ti ọrọ rẹ si fi yatọ ni pe Ibadan lo ti n ṣe gbogbo iṣẹ rẹ, bi wọn ba si gbe e jade lọ diẹ bayii, ko tun ni i pẹ ti yoo fi pada waa maa ba iṣẹ rẹ lọ n’Ibadan, o fẹran lati wa niluu naa ṣaa ni. Ohun to jẹ ki wọn fi i ṣe adajọ kekere niluu naa lọdun 1933 niyẹn, to si n ba wọn ṣe eto idajọ naa daadaa pẹlu ọgbọn iwe to ka, lara awọn adajọ ibilẹ to mo iṣẹ naa ni.

Lẹyin to ti tun ṣe awọn idanilẹkọọ daadaa si i, ti wọn si ti ri i pe o mọ iṣẹ naa loootọ, ki i ṣe kekere, wọn sọ ọ di olori awọn ile-ẹjọ to n dajọ ọrọ ilẹ, oun ni aarẹ fawọn ile-ẹjọ naa, President, Court of Land Courts. Ọdun 1936 leleyii, nigba to si di ọdun 1945, Akinyẹle di adajọ ibilẹ agba fun gbogbo ẹkun Ibadan ati agbegbe rẹ. Ni gbogbo akoko yii naa ni ipo rẹ ninu oye Ibadan n ga si i, ọdun 1953 ni wọn si fi i jẹ oye Balogun, oye ti ki i ṣe kekere. Bo ti di ọdun 1955 lo di Olubadan, ti gbogbo ilẹ Yoruba si n wari fun un gẹgẹ bii ọkan pataki ninu awọn ọba wọn. O ku diẹ ki ọdun mẹwaa rẹ pe lori oye ni iku pa a loju de lọdun 1964 yii, iku rẹ si ko gbogbo ilu naa lọkan soke, agaga awọn oloṣelu ti wọn ti gbojule e pe bi ọrọ ba fẹẹ di wahala tootọ, oun ni yoo le gba wọn lọwọ awọn alatako wọn. Lẹsẹkẹsẹ naa ni wọn ṣeto isinku rẹ sinu ṣọọṣi Arẹmọ.

Oye Ọba Ibadan ki i ṣe ohun ti wọn n ja le lori, nitori ki Olubadan kan too ku ni ẹni ti yoo gba ipo naa lọwọ rẹ ti mọ ara rẹ, ti awọn ijoye to ku si ti mọ ọn, ko ṣẹṣẹ ni ọrọ idibo tabi a n jiyan le lori. Nidii eyi, lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, ọdun 1964 yii, iyẹn bii ọsẹ kan pere ti Olubadan Akinyẹle waja ni wọn ti kede Olubadan tuntun, orukọ rẹ si ni Yesufu Kobiowu. Aṣaaju Olubadan igba naa, Oloye D. T. Akinbiyi, lo kede orukọ Kobiowu bii Olubadan ilẹ Ibadan tuntun. Ọrọ naa ko si la ariwo lọ rara. Ṣe lati ọdun 1937 loun naa ti n jẹ oye nla bọ, ọdun 1953 ni wọn si fi i jẹ Ọtun Olubadan, ipo naa ko ṣe ajoji si i rara. Bẹẹ loun naa n dọgbọn ṣoṣelu labẹlẹ, nitori ọkan ninu awọn ọmọ ile-igbimọ awọn lọbalọba ni Western Region ni. Koda, o ti ba awọn igbimọ naa lọ si London lọdun 1957, o si mọ nipa ohun to n lọ nile ijọba.

Ohun to mu ọrọ rẹ daa loju ọpọ eeyan ni pe Kobiowu ki i ṣe agbalagba nigba to joye naa, ko ti i pe ọmọ ọgọta ọdun rara, igbagbọ awọn eeyan si ni pe eleyii yoo jẹ ko pẹ lori oye ju ọpọlọpọ awọn ti wọn n fi arugbo joye naa lọ. Oun naa ti ṣiṣẹ adajọ ibilẹ daadaa, ọkan ninu awọn ọmọṣẹ Olubadan Akinyẹle to ku ni, nitori ile-ẹjọ to n dajọ ọrọ ilẹ loun naa wa fun igba pipẹ. Oun naa ki i ṣe eeyan kuẹkuẹ nidii eto oye ati toṣelu Ibadan, ko si sẹni to sọ pe oye naa ko tọ si i. Lẹyin ti wọn ti kede orukọ rẹ, ti wọn si ti sinku Olubadan Akinyẹle, iduro ko si, ibẹrẹ ko si mọ, ipalẹmọ bi wọn yoo ṣe fi oun naa jẹ bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ ni, nitori lọjọ karun-un ti wọn kede orukọ rẹ, iyẹn ni June 5, 1964, ni wọn fi Kobiowu jẹ Olubadan tuntun l’Ọjaaba, ko si sọmọ Ibadan ti ko debẹ ke Kabiyesi, nitori ọba kan ti ku, o si di dandan ki ọba mi-in jẹ.

Gbogbo rọtirọti isinku Olubadan yii mu ki nnkan lọ silẹ diẹ laarin awọn oloṣelu Ibadan ati gbogbo Western Region, nigba to kuku jẹ Ibadan ni ibujokoo ijọba wọn. Gbogbo awọn eeyan bii Adisa Akinloye, Richard Akinjide, Adisa Adeoye, ati awọn mi-in ti wọn jẹ ọmọ ilu Ibadan ni wọn pa oṣelu wọn ti, ti kaluku si kopa ninu eto isinku Ọba Akinyẹle, ati ifijoye Ọba Kobiowu. Awọn naa kuku gbọn, wọn mọ ohun ti wọn n ṣe, wọn mọ pe bi oloṣelu kan ba ni oun ọmọ ilu Ibadan, ti ko kopa nibi eto naa daadaa, tabi to ṣe ohunkohun to le da eto naa ru, yoo pada waa jere rẹ lọdọ awọn ọmọ Ibadan, nitori laarin igba naa ni wọn yoo ba orukọ rẹ jẹ, ko si si ohun ti yoo ṣe ti yoo tun jẹ ko niyi laarin wọn mọ. Nitori ẹ ni kaluku wọn ṣe fi gbogbo ara ṣiṣẹ nibi isinku ati igbade yii, titi dori olori ijọba wọn paapaa, Ladoke Akintọla.

Ṣugbọn bi a ba sọrọ sọrọ ka ma gbagbe pe ẹni ti a de lokun lọrọ awọn oloṣelu. Awọn kinni kan ti wa nilẹ ti ọkan kaluku ko kuro nibẹ, wọn fẹẹ mọ ibi tawọn ọrọ naa yoo ja si gan-an. Akọkọ ni ti awọn oṣiṣẹ ti wọn n pariwo pe wọn yoo da iṣẹ silẹ nitori owo oṣu awọn ti ko to nnkan, ọrọ naa si ti debii pe apa ko fẹẹ ka a mọ, aṣọ ko fẹẹ ba ọmọyẹ mọ, ọmọyẹ n fẹẹ rin ihooho wọja. Ṣugbọn iyẹn, ọrun n ya bọ ni, ki i ṣe ọrọ ẹni kan. Ọrọ ijọba apapọ ni, o si di igba ti apa ijọba apapọ ko ba ka a ki kinni naa too kan awọn ijọba ipinlẹ to ku, nitori awọn oṣiṣe ijọba apapọ lo pọ ninu awọn ti wọn n leri pe awọn yoo daṣẹ silẹ yii. Eyi to kan ijọba Western Region, to si fẹẹ ti wọn ṣubu ni ti Michael Okpara to n bọ ni agbegbe naa, to ni oun fẹẹ ṣe abẹwo si awọn eeyan oun nibẹ, iyẹn awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NCNC gbogbo.

Ọkan ijọba Akintọla ko balẹ rara nitori ọrọ naa. Wọn mọ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣi wa ni ilẹ Yoruba nigba naa ti wọn n ṣe ẹgbẹ NCNC, o si tẹ wọn lọrun ki wọn ṣe ẹgbẹ AG, iyẹn Action Group, ju ki wọn ṣe ẹgbẹ Akintọla, ẹgbẹ Dẹmọ lọ. Ṣe nigba ti ọrọ Awolọwọ pẹlu Akintọla le koko nijọsi, ti awọn Akintọla lọọ ba NCNC pe ki wọn gba awọn, pe awọn yoo jọ ṣejọba ni, awọn yoo si jọ maa pin gbogbo ohun to ba tidi ẹ yọ ni, awọn araalu ti wọn jẹ Yoruba ọmọ NCNC ko tete gba, wọn ni awọn ko fẹẹ ba Akintọla ṣe, nitori yoo dalẹ ẹgbẹ awọn gbẹyin ni. Ohun ti wọn si ṣe sọ bẹẹ ni pe ẹni to dalẹ ọga rẹ ti wọn jọ n bọ lati ọjọ to pẹ, ko si ohun ti yoo na an lati kọyin si ẹgbẹ NCNC nigba to ba gba ohun to n fẹ lọwọ awọn tan. Bi wọn ti n gbe ọrọ naa lo n jabọ, wọn ko ri i sọ rara. Nigba naa ni wọn ni afi ki wọn pe olori ẹgbẹ wọn wa.

Bii igba ti ina n jo, ti wọn bu omi tutu si i lo ri nigba ti Okpara waa ṣe abẹwo rẹ, nitori gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ ati awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC nilẹ Yoruba lo ba sọrọ, bo si ti n ti ilu kan de ekeji lo n sọ fun wọn pe ọpọn ti sun, ọrọ ti yatọ, Akintọla lawọn yoo ba ṣe. O ṣalaye fawọn eeyan naa pe awọn ti ba Akintọla ṣepade loriṣiiriṣii, Akintọla si ti waa ba oun ni ilẹ Ibo lọhun-un to ti ṣalaye pe oun ko ni i dalẹ, oun ko si ni i fi oju oloore gungi, awọn yoo jọ ṣejọba Western Region ko le daa ni. Okpara ni bawọn ọmọ ẹgbẹ NCNC yii ba fẹ ijọba to dara, ti wọn si fẹ ki ohun ti awọn n le lati ọjọ yii to awọn lọwọ, ki wọn jẹ ki wọn ba ẹgbẹ Akintọla ṣe, ohun gbogbo yoo si ri bi awọn ṣe n fẹ gan-an. Awọn ọrọ to sọ yii wọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ leti, nitori laarin ọsẹ kan sikeji, awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC gbogbo ti dọrẹ Akintọla.

Ọdun 1962 ni eleyii ṣẹlẹ. Abẹwo ti Okpara si ṣe si ilẹ Yoruba nigba naa lo mu ki ẹgbẹ UPP ti Akintọla ati NCNC lagbara lati le Awolọwọ ati ẹgbẹ AG rẹ kuro lori oye, ti wọn si gbajọba Western Region. Ṣugbọn nnkan ti yatọ bayii lọdun keji si asiko naa, ọdun 1964 la wa yii, Akintọla ti dalẹ NCNC gẹgẹ bi awọn ọmọ Yoruba inu ẹgbẹ naa ti wi nigba naa, ko ba wọn ṣe mọ, o ti ja pupọ ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ NCNC, o si ti ko wọn mọra, wọn ti jọ da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ, ẹgbẹ naa si ti di ọta awọn aṣaaju NCNC, ati awọn ọmọ ẹgbẹ to ba kọ lati darapọ mọ wọn. Eyi ni Okpara ṣe tun ni oun n bọ nilẹ Yoruba, ki oun le waa ṣalaye fun awọn ọmọ ẹgbẹ oun pe awọn ko ba Akintọla ṣe mọ o, Action Group, ẹgbẹ Awolọwọ, lawọn tun jọ fẹẹ maa ṣe, ki oun si sọ idi ti ọrọ naa fi ri bẹẹ, ati ohun ti Akintọla ṣe fun wọn. N lo ba bẹrẹ imura.

 

Akintọla mọ pe nnkan ti ko daa rara ni eleyii, bi Okpara ba wa to ba waa n tu aṣiri oriṣiiriṣii kalẹ, ọrọ naa le koba ẹgbẹ oun tuntun, ko si mu ki ọpọ awọn eeyan ti wọn ti fẹẹ ṣe tawọn tẹlẹ sa sẹyin, ki wọn ni awọn ko ba Dẹmọ ṣe mọ. Eyi lo si fi jẹ pe bi Okpara ti kede pe oun n bọ bayii, bẹẹ ni oriṣiiriṣii ete bẹrẹ lọdọ awọn Akintọla yii, wọn ni gbogbo ọna lawọn gbọdọ wa ti Okpara ko fi ni i wa si ilẹ Yoruba, abi ki lo n wa. Awọn ẹgbẹ ọdọ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ni wọn kọkọ sọ ọrọ naa sita, wọn ni awọn ko fẹ Okpara nilẹ Yoruba, wọn ni bo ba tilẹ fẹẹ wa, ki i ṣe asiko yii rara, wọn ni asiko ti Yoruba n wa iṣọkan laarin ara wọn ni, wọn ko si fẹ ki araata kankan waa ba awọn da si i, bi Okpara ba fẹẹ wa, ko jẹ ki awọn fi ẹsẹ iṣọkan ti awọn n wa mulẹ daadaa na, iyẹn lawọn fi le gba a laaye ko wa.

Ọrọ naa bi awọn ọdọ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ NCNC ninu, awọn naa sare kọ iwe tiwọn jade, wọn ni o to akoko yii ki awọn kan dide ki wọn ni awọn n wa iṣọkan nilẹ Yoruba, ki Okpara ma wa, wọn ni nigba ti Okpara n bọ ni ọdun 1962, to jẹ awọn ti wọn n ṣejọba bayii ni wọn lọọ ranṣẹ pe e, wọn ko mọ pe ko si iṣọkan nilẹ Yoruba nigba naa. Wọn ni ọrọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ sọ pe ki i ṣe bẹẹ, nitori awọn yẹn ti ni Akintọla naa ko ṣa lọ silẹ Ibo, olori ẹgbẹ oṣelu rẹ si ni. Awọn ọmọ NCNC ni Akintọla ko le lọ silẹ Ibo, nitori ẹgbẹ oṣelu ti oun n ṣe, ilẹ Yoruba nikan ni ẹgbẹ Dẹmọ rẹ mọ, ṣugbọn ni ti Okpara, olori ẹgbẹ NCNC ni, ẹgbẹ naa si wa kaakiri ilẹ gbogbo ati ilu gbogbo ni Naijiria ni, niwọn igba to si ti jẹ oun lolori ẹgbẹ naa, ko si ibi to fẹẹ lọ ti ko le lọ, nitori gbogbo ibi to ba de pata lawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ wa.

Nibi ti wọn ti n fa ọrọ yii mọ ara wọn lọwọ ni ijọba Akintọla ti ṣe ofin tuntun, wọn ni awọn ko fẹ iwọde, ipade ita gbangba, akojọpọ awọn eeyan, tabi ọrọ oṣelu kan ni gbogbo Western Region lasiko naa, wọn ni ki onile gbele, ko saaye a n rin kiri. Okpara mọ pe nitori oun ni ofin tuntun yii ṣe waye, n loun naa ba kede, o ni ko si jubita kan ti yoo da oun duro, oun n bọ nilẹ Yoruba dandan.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.