Ọlọwọ tuntun, Ọmọọba Ajibade Ogunoye, gori itẹ awọn baba nla rẹ

Spread the love

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

 Ọkan ninu ọjọ ti ko ṣee gbagbe bọrọ fawọn eeyan ilu Ọwọ lọjọ Ẹti, Furaidee,ọsẹ to kọja yii, pẹlu bi Ọmọọba Ajibade Gbadegẹṣin Ogunoye ṣe gori itẹ awọn baba nla rẹ gẹgẹ bii Ọlọwọ tilu Ọwọ.

Ọgọọrọ ero to wa nibi ayẹyẹ ọhun ko jẹ ki arọọrọda ojo to rọ lọjọ naa di wọn lọwọ lati waa yẹ ọba tuntun naa si.

Gbogbo ojuko mejeeje ti Kabiyesi fi ẹsẹ tẹ lawọn obitibiti ero ọhun n wọ tẹle e, bẹẹ ni wọn ko pada lẹyin rẹ titi to fi ṣetan ni nnkan bii aago mẹrin aabọirọlẹ ọjọ naa.

Nibaamu pẹlu ilana tawọn oṣiṣẹ ijọba n tẹle, Ọjọbọ, Tọsidee, to ṣaaju ni Ọlọwọ tuntun naa kọwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo, lẹyin eyi ni awọn ọrẹ atawọn afẹnifẹre rẹ sin in kuro l’Akurẹ lọ si ilu abinibi rẹ ni Ọwọ.

Ọgbẹsẹ, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, lawọn araalu rẹ ti waa pade wọn, nibi ti gbogbo wọn ti fi idunnu wọn han pẹlu bi wọn ṣe filu ati ijo kọwọọrin lọ saaarin igboro ilu Ọwọ.

Nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ Ẹti, Furaidee, ni eto ayẹyẹ ifinijoye bẹrẹ ni pẹrẹu, ile Olúbulẹ̀ ni Kabiyesi kọkọ lọ, nibi ti wọn ti fi joye meji, Alamurẹn ati Anaun, lẹẹkan ṣoṣo. Oye eyi si ni igbesẹ akọkọ ko too kunju oṣuwọn lati jọba.

Iloro-Arigidi ni Kabiyesi tun mori le, nibẹ ni wọn si tun ti fi joye mi-in, ohun ta a gbọ ni pe ọba tuntun ọhun ati ẹnikan ti wọn n pe ni Adanibọba nikan ni wọn gbọdọ wa ninu yara kan, nibi ti wọn yoo ti fi joye naa.

Ọba Ajibade tun ṣabẹwo sawọn agbegbe mẹta mi-in fun iwure, eyi ti gbogbo rẹ ko fi bẹẹ jinna sira wn, bẹẹ ni wọn o si jinna si aafin Ọlọwọ, ko too ṣẹṣẹ kọja lọ si Oke Mapo, nibi ti yoo ti yan ipin.

O fẹrẹ to bii wakati kan to ti wa ninu ile awo kekere kan ti wọn fi ẹni kọ l’Oke Mapo, nibi to ti lọọ mu ida kan ti wọn n pe ni Àdá Ẹlẹ́wùokùn.

Ninu alaye to ṣe fun wa ni kete ti Kabiyesi ọhun yan ipin tan, Ọjọmu tilu Ọwọ, to tun jẹ olori awọn Ọmọlọwọ-madẹ (awọn afọbajẹ), Agba-Oye Ọlanrewaju Famakinwa, ni ada mejilelọgbọn lo wa nibi ti wọn ti n yan ipinnaa.

O ni ada kan duro fun ọba kọọkan to ti jẹ sẹyin niluu Ọwọ ati ohun to ṣẹlẹ lasiko ti wọn fi wa lori oye.

Eyi ti Ọba Ajibade yan yii lo ni baba rẹ mu ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin to jọba, leyii to tumọ si pe alaafia ati aasiki yoo wa ni gbogbo asiko iṣejọba rẹ.

Aarin ọja ọba ilu ọhun ni Ọlọwọ tuntun yii tun lọ, lẹyin eyi lo lọ sibi ti Alalẹ ti gbe odo iyan kan le e lọwọ.

Oloye Idowu Oludaye ti i ṣe Agbaọmọlọwọ ilu Ọwọ ni ohun ti odo iyan ti wọn fun Kabiyesi naa n ṣapẹẹrẹ ni pe itọju ati igbe aye irọrun awọn eeyan ilu gbọdọ jẹ ẹ logun.

Ile Asamọ (Uha Asamọ), to wa lagbegbe Ìlórò lọrọ yi kan, ibẹ si ni Ọba Ajibade pari gbogbo etutu ọjọ ọhun si, ati pe nibẹ ni ilana ọba jijẹ laye ọjọun sọ pe yoo wa fun oṣu mẹta gbako, ko too di po gba ade.

Adanigbo Olula tilu Ọwọ, Oloye Kunle Ijalana, ṣe e lalaye fun wa pe, oṣu mẹta lawọn ọba to ba fẹ jẹ Ọlọwọ gbọdọ lo ni Uha Asamọ laye atijọ,ṣugbọn ko ri bẹẹ mọ lode oni.

O ni ọlaju to gbode wa lara ohun to ṣokunfa bi wọn ṣe din oṣu mẹta naa ku si wakati kan pere bayii.

Lẹyin ti Kabiyesi pari gbogbo etutu to yẹ lawọn ibi ọtọọtọ kaakiri ilu Ọwọ lo too pada wọ inu aafin lọ, nibi ti yoo ti maa gba ọkan-ojọkan alejo fun ọjọ mẹtadinlogun gbako.

Oloye Oludaye ni o digba ti ọba tuntun ọhun ba pari gbogbo awọn etutu to yẹ ki ọrọ gbigba ọpa aṣẹ ati iwuye too waye.

Ọjọ kẹfa, oṣu keje, ọdun 1966, ni wọn bi Ọba Ajibade Gbadegẹṣin si idile Ọba Adekọla Ogunoye, ẹni to jẹ Ọlọwọ tilu Ọwọ, laarin ọdun 1968 si 1993.

O kẹkọọ jade nileewe alakọọbẹrẹ ijọba ati ti girama to wa niluu Ọwọ, bakan naa lo tun lọọ lo ọdun kan si i nileewe girama Oyemẹkun, to wa l’Akurẹ.

Fasiti ipinlẹ Ondo igba naa, eyi to ti di fasiti ipinlẹ Ekiti bayii lo ti gboye imọ ijinlẹ akọkọ, o tun gba oye digirii ẹlẹẹkeji ni Fasiti Adekunle Ajasin to wa l’Akungba Akoko.

Eyi ko fi bẹẹ tẹ ẹ lọrun pẹlu bo tun ṣe pada si fasiti, to si lọ kẹkọọ nipa imọ ofin, eyi to pari sile-ẹkọ awọn amofin to wa l’Abuja.

Ọdun 2001 ni wọn gba a gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo, o si ṣiṣẹ lọpọlọpọ ẹka, bẹre nileesẹ to n ri si eto idajọ, ileesẹ to n ri sọrọ awọn oṣiṣẹ, ti eto inawo, ileesẹ to n ri seto irinna, ileesẹ to n ri si ipese iṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oṣu to kọja ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, fọwọ si yiyan Ọba Ajibade gẹgẹ bii akọwe agba fun ile ijọba ipinlẹ Ondo, ipo yii lo si di mu titi to fi kọwe fiṣẹ ijọba silẹ lọsẹ to kọja.

Ileeṣẹ ALAROYE naa n ki Kabiyesi ku ipalẹmọ ayẹyẹ igbade ati iwuye to n bọ lọna dẹdẹ.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.