Ọlọrun lo ma yọ Yẹmi Ọṣinbajo o

Spread the love

Kin ni a ba maa wi o, abi ọrọ wo ni a ba maa sọ, bi ẹyi ti a o ro rara ba ṣẹlẹ nipa Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo. Ohun to ṣẹlẹ si i ni Satide to kọja yii, ti ẹronpileeni rẹ fi tipatipa balẹ ni Kaba ki i ma i ṣe kekere, bi ọpọ awọn eeyan ti n ja bọ ninu ẹronpileeni ti wọn n ku danu niyẹn. Ṣugbọn ki eeyan dupẹ lọwọ Ọlọrun pe iru rẹ ko ṣẹlẹ si i. Nitori bi iru rẹ ba ṣẹlẹ naa, ariwo yoo kan pọ naa ni, alaye yoo maa ṣe aye rẹ lọ, wọn yoo si ni ko si ẹnikan to le da iku duro bi ọjọ ba ti pe. Ko ju bẹẹ lọ. Lara wahala to wa nidii ọrọ oṣelu niyẹn, paapaa oṣelu awọn orilẹ-ede bii ti Naijiria yii. Ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ si ẹronpileeni naa, o le jẹ nibi aloju, ka maa fi ojoojumọ lọ si igbara igboro, agaga nigba ti ọrọ ibo yii ti bẹrẹ. Wahala kekere kọ! Bi eeyan ba ri oju Ọṣinbajo yii paapaa, yoo ri i pe o ti gbo ju bo ti wa tẹlẹ lọ, to waa da bii ọmọ aadọrin ọdun yatọ si ọgọta ọdun. Bẹẹ ko ri bẹẹ ko too gba iṣẹ yii, ẹni ba ti gba iṣẹ ilu, aisun, aiwo ni. Iṣẹ naa ko si ni oriyin kan pato, agaga nibi ti nnkan ko ba ti dara fun mẹkunnu, eebu ati epe ni. Ọlọrun nikan ni i ko oloṣelu yọ. Gbogbo koomi-de-koomi ṣa o, gbogbo bi iba ti i jẹ, afi ki Ọṣinbajo fi suuru si i. Ohun to ba ṣee ṣe ni ko ṣe, eyi to ba ti fẹẹ mu wahala dani ju, ko fi i silẹ fẹlomiiran ṣe. Bi a ba wa laye, alaye yoo ṣe e o, bi a ko ba si si nibẹ, alaye yoo ṣe e, bẹẹ eyi to dara ju ni ka wa laye lasiko to ba n yẹ ni, ka le raaye mojuto nnkan to yẹ ka mojuto, ka si raaye ṣe ohun to yẹ ka ṣe to jẹ awọn eeyan yoo fi maa royin wa nigba ti a ko ba si mọ. Gbogbo ohun to ba fẹẹ gbe jade ni wọn gbọdọ ṣe ayẹwo rẹ kinni-kinni, boya mọto ni, bo si jẹ ẹronpileeni, bẹẹ ni bi wahala ko ṣe gbọdọ pọ ju fun oun naa ni wahala ko gbọdọ pọ ju fun awọn ohun to n gbe kiri bii mọto tabi ẹronpileeni, ka ti Eko de Sokoto, ka ti tun sare pada si Maiduguri, kawọn eeyan si tun wa nibi kan ki wọn maa reti wa ni Enugu, ko si ohun to yara da ẹmi ni kukuru ju bẹẹ lọ. Ki i ṣe gbogbo ibi ni olori ilu n de, ọpọ ibi ni yoo ran eeyan lọ. Iṣẹ ti wọn gbe le Ọṣinbajo lọwọ yii le diẹ, oun ni ko fi suuru si i. A dupẹ lọdọ Ọlọrun fun ẹmi Ọṣinbajo, bi iru rẹ ba si ku lẹyin, ki Ọlọrun ba ni ko o yọ. Ọmọ ẹni ko ṣaa ni i ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹkẹ sidii ọmọ ẹlomiiran, tẹni n tẹni o.

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.