Ọlọrun lo kuku yọ Adeleke ni tiẹ

Spread the love

Awọn oloṣelu ki i ṣe eeyan daadaa, wọn si yi orukọ Sẹnetọ Ademọla Adeleke pada. Ni gbogbo asiko ibo yẹn, ẹ ko mọ orukọ ti wọn n pe e ni, ADE DANCER! Bi eeyan ba tumọ rẹ si Yoruba, ADE ALAJOOTA ni, ẹni ti ko ni iṣẹ meji, tabi ti ko mọ ohun meji ju ijo lọ. Oun naa kuku si ti sọ fun wọn o, o ni ki wọn maa wo oun, boun ṣe n jo yẹn naa loun yoo jo lọ sile ijọba gẹgẹ bii gomina. Ere ni wọn ro pe o n ṣe o, ṣugbọn okuta ti awọn ọmọle kọ silẹ bayii, oun lo pada waa di pataki igun ile o. Boya ijo lo n jo o, boya ko mọ nnkan mi-in mọ o, awọn ara Ọṣun to fẹran rẹ pọ ju bi awọn eeyan ti ro lọ, wọn si jade, wọn dibo fun un. Bo ba jẹ bi awọn eeyan ti ro o ni, bi wọn ba dibo naa ti ko mu kinni kan, itiju rẹ yoo pọ ju, bẹẹ naa si ni yoo ṣoro fun un lati ri ipo gidi kan mu lagbegbe naa mọ, yoo yaa pada si Amẹrika, yoo maa jo ijo rẹ lọ ni. Ṣugbọn Ọlọrun ti yọ ọ o, bi awọn APC atawọn to ku ko ba si mura gidi, Adeleke yoo jo wọ ile ijọba Ọṣun. Ọrọ araalu ko ṣee tori ẹ binu, ohun ti wọn si n pe ni ijọba dẹmokiresi niyẹn. Loju awọn ọlọgbọn ilu, ati awọn ọmọwe, ko yẹ ki ẹnikẹni dibo rara fun iru Adeleke yii, inu si bi wọn ju nitori ijo to n jo. Ṣugbọn ọrọ araalu ko ri bẹẹ, bẹẹ ni ijọba dẹmokiresi naa ko ri bẹẹ rara, ẹni to ba wu awọn araalu ni wọn yoo dibo wọn fun, bi wọn ba si ti dibo fun un, o pari naa niyẹn, oun ni yoo maa ṣejọba le wọn lori titi igba mi-in ti wọn ba tun lawọn ko fẹ ẹ mọ. Ẹkọ oṣelu pataki leleyii, iyẹn naa ni pe ko sẹni to ṣee foju di lasiko ibo didi, nitori ọtọ ni ohun ti araalu yoo maa fẹ, ọtọ si ni eyi to wa lọkan awọn oloṣelu, bẹẹ ti araalu ni yoo ṣẹ nibi ti ko ba ti si ojooro. Bi ibo yii ti lọ yii daa o, gbogbo agbaye lo ti ri i, gbogbo aye naa lo si n wo o, wọn fẹẹ wo ibi ti yoo yọri si. INEC ko gbọdọ fi igba kan bọkan ninu o, awọn oloṣelu kan ko si gbọdọ da ibo naa ru, nitori bi wọn ba ṣe bẹẹ, ko jọ pe awọn ti wọn fẹran ọkunrin yii yoo gba kamu, bẹẹ wọn si pọ gidi niye. Ṣugbọn o daju pe bi wọn ba ṣeto idibo naa bo ṣe yẹ ki wọn ṣe e, ẹni yoowu to ba wọle, ko ni si wahala kankan. Ṣugbọn bi wọn ba gba ọna eru, Ọlọrun ma jẹ ki wọn dana sun Ọṣun o, nitori rẹ loloṣelu kan ko ṣe gbọdọ ṣe jibiti, ki kaluku fọwọ sibi tọwọ n gbe. Yoo ṣee ṣe o.

 

(112)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.