Olori tuntun: Gbogbo aye lo n ki Ọọni Ogunwusi ku oriire

Spread the love

Titi di bi a ṣe n ko iroyin yii jọ, kaakiri agbaye lawọn eeyan ṣi n kọwe ranṣẹ, ti awọn mi-in si n tẹlifoonu, ti ọpọlọpọ wọn si n wa si aafin lati ki Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, ku oriire. Ọsẹ to kọja ni Ọọni gbeyawo, bo si tilẹ jẹ pe ọrọ naa ko la ariwo lọ titi ti Olori tuntun, Naomi Oluwaṣeyi, fi de si aafin Ẹnu-Ọwa, sibẹ, lẹsẹkẹsẹ to ti wọle ni ariwo ti gbalu, ti gbogbo aye si n ba Ọọni yọ, wọn ni oriire kan ko ju bayii lọ.
Ki i ṣe pe Naomi, ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn, ti Ọba fẹ yii rẹwa lobinrin nikan kọ, awọn iwa to ni, ati abuda to ni fi i han gẹgẹ bii olori ti Ọlọrun funra rẹ ti pese fun Ọọni. Lara ohun ti wọn maa n ka mọ eewọ ni aye atijọ fun awọn ọba ki wọn too fẹ iyawo kankan ni pe obinrin ti wọn ba fẹẹ fẹ yii, wọn gbọdọ ba a nile, iyẹn ni pe ibale rẹ gbọdọ wa nibẹ, ko jẹ obinrin ti ko ti i mọ okunrin. Nnkan ti bajẹ laye ode oni debii pe ẹni ti yoo ba fẹyawo ti yoo ni dandan ni ki oun ba a nile, tọhun ko ni i ni obinrin laye ẹ ni. Ṣugbọn Ọlọrun pese Naomi fun Ọọni, obinrin ti ko mọ ọkunrin titi to fi dele Ọọni ni.
Ohun to si fa a ko ju pe obinrin yii ti wa ninu ẹsin tipẹ, oniwaasu loun naa, o si maa n ṣe iṣẹ iyanu. Ọpọ awọn to n gbadura fun ni adura naa maa n ṣẹ lẹsẹkẹsẹ, ohun to si mu agbara rẹ le ju tọpọ awọn ajihinrere mi-in lọ ni pe ko ti i mọ ọkunrin. Bi oun si ti n ṣeto fun awọn mi-in ni Ọlọrun naa n ṣeto oriire tirẹ, bẹẹ ni Ooni ṣe gboorun rẹ, to si fi i ṣe aya. Lati igba to si ti wọle ni iyatọ ti ba aafin paapaa, nitori agbara adura rẹ lo gbe wọle.
Bo tilẹ jẹ pe o ti fẹyawo kan ri, Ọba Ogunwusi ko mu olori de aafin nigba to jọba ni ọjọ karun-un, oṣu kejila, ọdun 2015, o wa loun nikan ni. Ṣugbọn wọn ko jẹ ki kinni naa pẹ ti wọn fi wa olori fun un, nigba ti wọn sọ pe apọnle ko si fọba ti ko lolori. O fẹ Wuraọla ọmọ ilu Ibinni ni ọjọ kejila, oṣu kẹta, 2016, o kan jẹ pe igbeyawo naa ko pe ọdun meji to fi foriṣanpọn, ti Olori Wuraọla si jade ni aafin Ọọni ni ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun 2017.
Lati igba naa ni oriṣiiriṣii awọn eeyan ti n sare kiri, wọn fẹẹ fi ọmọbinrin ta Ọọni lọrẹ. Awọn obinrin ti wọn mọ pe ko si iyawo laafin naa n sare asaforigbari, kaluku lo fẹẹ di Yeyeluwa, olori awọn ayaba laafin Ọọni. Ṣugbọn wọn gbiyanju titi ni ko bọ si i, afi nigba ti Ọlọrun sọ pe o to asiko, to si gbe Oluwaṣeyi Naomi dide gẹgẹ bii ayaba.
Iyẹn ni gbogbo aye ṣe n ba tọkọ-tiyawo yii yọ, ti wọn ni nigba yii gan-an ni oriire nla gunlẹ si orirun awa Yoruba, nitori Arole Oduduwa wa ti ni olori tuntun.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.