Olori ikọ Boko Haram ti wọn mu l’Ekoo ti jẹwọ, o ni ọlọpaa meje loun ti pa, awọn tun digunja banki

Spread the love

Lọsẹ meji sẹyin ni ileeṣẹ ọtẹlemuye, (Intelligence Rapid Team), eyi ti DCP Abba Kyari ko sodi  mu ọkan ninu awọn ọga ikọ Boko Haram, Umar Abdulmalik, ẹni ọgbọn ọdun niluu Eko.

Ọmọ bibi ilu Okene, nipinlẹ Kogi, naa ṣalaye ọpọlọpọ ọrọ fawọn agbofinro lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja. Lẹyin ti wọn pa ọlọpaa meje ati ẹni kan ninu oṣu keje, ọdun to kọja, ni adugbo Galadima, niluu Abuja, ni ọga agba ọlọpaa, Ibrahim Idris, pa Kyari laṣẹ lati wa ẹni to ṣiṣẹ ibi naa ri. Oṣu marun-un gbako ni Kyari fi ṣiṣẹ naa, ko too di pe ọwọ tẹ ọkan ninu awọn ikọ yii, Lukman Abdul, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Lampard, niluu Ondo, oun lo si ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ naa marun-un mi-in.

Wọnyi lawọn ọro to sọ:

Bi mo ṣe di ọmọ ẹgbẹ Boko Haram

Mo ti pa ọlọpaa meje ati awọn eeyan to le ni igba (200), ko too di pe ọwọ tẹ mi. Aafaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Mustapha lo mu mi wọ ẹgbẹ Boko Haram. Ọdun 2009 ni Mustapha gbe ẹkọ nipa ẹsin Islam tirẹ de ilu Kogi. Ọkunrin naa kọ mọṣalaṣi, o si rọ awọn eeyan lati ma ṣe ka ẹkọ igbalode kun nnkan kan rara, nitori o ṣe lodi si Allah. Mustapha rọ wa lati faramọ ẹsin Islam, gbogbo arọwa ti o si pa fun wa yii lo mu mi darapọ mọ awọn ọmọlẹyin rẹ. Lasiko ti mo di ọmọ ẹyin ọkunrin naa tan lo bẹrẹ si i kọ wa pe ki a gbogun ti orileede Naijiria ati ijọba rẹ, nitori gbogbo ilana ti awọn olori orileede yii fi n ṣakoso ko ba ilana ẹsin Islam mu.

Ọrọ ti Mustapha sọ yii lo mu mi lọkan, to fi di pe emi naa ati awọn mi-in fa iwe-ẹri ti a gba nileewe ya, ta a si darapọ mọ ọkan ninu awọn igun Boko Haram to wa nipinlẹ Kogi, olori igun wa ni Zeeidi. Awa la ju ado oloro si ipinlẹ Kaduna ati Kano, pẹlu ilu Abuja. Zeidi lo maa n ba wa wa ado oloro ti a maa ju wa, iṣẹ temi  kan ni ki n gbe ado oloro naa lọ sibi ti a fẹẹ ju u si.

Asiko kan wa ti awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ ya bo wa, ti wọn si ko awọn ọmọ ẹgbẹ wa kan, lasiko naa ni wọn si mu Mustapha, ti wọn si tun wo mọṣalaṣi wa.

Zeidi lo tun mu amọran ki a maa ja banki lole wa, lasiko ti owo wọn wa lo gba wa nimọran pe ti a ba ja awọn banki lole, owo maa wọle fun wa gan-an. Awa la digun ja awọn banki lole niluu Ọwọ pẹlu ado oloro. Ogunlọgọ owo la ri ko lọ ni awọn ileefowopamọ yii, owo naa la si fi n ra ado oloro. Lẹyin ti a ja awọn banki lole tan lọwọ tẹ ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ wa, mo si sa lọ siluu Abuja pẹlu awọn ado oloro ti a ti ṣe. Nigba ti mo deluu Abuja, mo da ikọ ẹgbẹ mi silẹ lọdun 2014, ikọ ẹgbẹ mi lo si ju ado oloro lu awọn ibi kan bii Banex Plaza, Yanya, ati Kueje, ti gbogbo wọn wa niluu Abuja. Ọwọ tẹ marun-un ninu awọn ikọ mi, lasiko yii si ni ẹgbẹ mi daru. Wọn ri awọn ado oloro wa, mo si sa lọ si ilu Kano, nibẹ ni mo wa fun ọdun meji gbako, nibi ti mo farapamọ si. Lẹyin ọdun meji ni mo pada siluu Abuja, mo si da ikọ tuntun silẹ to jẹ pe iṣẹ idigunjale ni a n ṣe loju mejeeji.

 

Ọlọpaa kan lo maa n fun wa niroyin

 

A ni ami ninu awọn ọlọpaa, oun lo maa n fi gbogbo bi nnkan ṣe n lọ nileeṣẹ ọlọpaa to wa leti. Apin-Iron lorukọ rẹ, ẹni ti wọn ti yọ niṣẹ bayii. Lẹyin ti Apin-Irin kopa ninu idigunjale kan ni wọn yọ ọ lẹnu iṣẹ ọlọpaa, ṣugbọn wọn ko gba ibọn AK-47 ọwọ rẹ ati ibọn ilewọ to ni, oun lo si maa n lo lati fi halẹ mọ awọn to n ṣe fayawo oogun oloro niluu Abuja, ti yoo si gba awọn oogun naa lọwọ wọn. Ọkunrin naa lo maa n ta awọn oogun oloro fun wa, koda, oun lo maa n fun wa lorukọ awọn olowo ti a maa n ja lole. Asiko kan wa to fun wa lorukọ baba olowo kan, lẹyin ti a ja ọkunrin naa lole tan, miliọnu mẹrin Naira la ri gba lọwọ rẹ, a si fun Apin-Irin ni miliọnu meji aabọ Naira gẹgẹ bii ipin tirẹ.

 

Bọwọ ṣe tẹ mi

 

Mo ni ijamba ọkọ lasiko kan, eyi to gba oju kan lọwọ mi. Lasiko naa ni mo pade ọkunrin kan to n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara ti orukọ rẹ n jẹ Mustapha. Mustapha maa n rowo gan-an nidii iṣẹ naa, ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ko jẹ ko gbadun, o si lọọ fi ẹjọ wọn sun ni teṣan ọlọpaa. Lẹyin ti awọn ọlọpaa fi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa silẹ, niṣe ni wọn pada, ti wọn si tun n halẹ mọ Mustapha. Lasiko naa ni Mustapha waa ba mi pe ki n jọwọ, waa pese eto aabo fun oun. Mo sọ fun un pe ko ra ibọn AK-47 meji fun awọn ọmọ mi, mo si gbe ibọn naa fun Lampard ati Abubakar pe ki wọn maa ṣọ ọ kaakiri. Mustapha tilẹ fẹ ki awọn ọmọ mi maa pa awọn eeyan lọ ni, paapaa nọọsi to n tọju rẹ nile, nitori o ni o ri oun lọjọ kan nibi toun ti n ṣe etutu, ṣugbọn mo paṣẹ fun awọn ọmọ mi pe wọn ko gbọdọ ṣe bẹẹ. Ibinu ọrọ ti mo sọ yii ni lo fi mu ẹjọ mi lọ si ọdọ awọn ọlọpaa. Lasiko ti awọn ọlọpaa waa ka mi mọle, mo yinbọn lu wọn, mo si sa lọ si  Iyana Sango Ọta, nipinlẹ Ogun, nibi ti ẹgbọn mi n gbe, ṣugbọn n ko mọ bi wọn ṣe mọ ile ẹgbọn mi ti wọn fi waa mu mi nibẹ.

 

 

 

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.