Olori ijọba West binu, Akintọla ti ileewe Ileṣa Grammar School pa

Spread the love

Ohun to ṣẹlẹ ni Ileṣa ni Satide, ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, 1964 yẹn, itiju gidi lo jẹ fun ijọba atawọn eeyan rẹ. Abi nigba ti wọn ho le odidi Prẹmia lori, ti wọn si n pariwo, ‘ole’ le Oloye Ladoke Akintọla funra rẹ lori, toun naa si wa ninu mọto, to ri i bi awọn eeyan naa ti n ho, ti wọn si n sare tẹle mọto lẹyin, ti wọn mura lati juko lu oun. Iyẹn o tun waa mu itiju nla dani bii igba ti Akintọla n rojọ ọrọ naa nibi ti wọn ti n fi ẹgbẹ Dẹmọ, Nigerian National Democratic Party NNDP lọlẹ, to n ṣalaye pe oju oun ma ri to loju ọna Ileṣa fawọn eeyan, ti ẹni kan si tun lori-laya laarin awọn ero nibẹ, to tun juko fun Prẹmia wọn, ti ọrọ si di paa-kira-kita, nibi ti awọn ọlọpaa ti n wa ẹni to ju oko naa kiri. Ohun ti ijọba ṣe ka ọrọ naa si ibinu niyẹn. Wọn ni ko sẹni to jẹ ṣe bẹẹ fun Sardauna nilẹ Hausa, bẹẹ ni ko sẹni ti yoo ṣe bẹẹ fun Okpara nilẹ Ibo, o ṣe waa jẹ olori ijọba Western Region lawọn Yoruba n ṣe bayii si, ki lọkunrin naa kuku gba lọwọ wọn.

Nibi ti ọrọ naa ka ijọba lara de, awọn funra wọn ni wọn n rojọ ọrọ naa fawọn ti ko gbọ rara. Wọn ni jẹẹjẹ awọn lawọn n lọ o, awọn ko ba ẹnikan ja o, awọn kan n lọ lati lọọ ko ẹgbẹ awọn jade ni o, afi bi awọn kan ṣe ni o ku ọna ti awọn yoo gba lọ. Wọn ni awọn ọmọ ileewe kan to jẹ awọn kan ni wọn lo wọn lo bẹrẹ si i juko lu mọto awọn, ti wọn si doju oko kọ minisita fun eto ẹkọ, Ọgbẹni Daniel Olumọfin, atawọn minisita mi-in ti wọn jọ n lọ. Wọn ko dawọ oko naa duro nigba ti mọto Oloye Akintọla paapaa n kọja, wọn wọn ọn loko gidigidi ni. Ijọba ni inu awọn o dun rara, awọn yoo si fiya gidi jẹ awọn ti ọwọ ba tẹ pe wọn mọ nipa ohun to ṣẹlẹ. Ijọba ni Piremia Akintọla funra ẹ ti paṣẹ, o ti ni ki igbimọ wadii ọrọ naa delẹdelẹ, ki awọn si mọ bo ṣe jẹ. Wọn ni ko si oju aanu fọmọ to ba sọ pe iya oun kọ lo bi oun, wọn yoo fun un niwee ibanujẹ ni.

 

Ko si ki ọrọ naa ma ka ijọba lara, ohun ti wọn n sọ jade pọ ju eyi to n ba wọn ja labẹnu lọ. Ṣe ẹ ri olori ileewe naa ti wọn n pe ni Prinsipa, ojiṣẹ Ọlọrun ni, rẹfurẹẹndi ni pẹlu, Josiah Akinyẹmi lorukọ rẹ. Ọmọ ẹgbẹ Action Group (AG), Ẹgbẹ Ọlọpe, ni. Koda, ọkan ninu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ijọba apapọ ni, o si wa nile igbimọ aṣofin titi ti ọrọ ti a wi yii fi ṣẹlẹ, iyẹn ni pe bo ṣe n ṣe Prinsipa naa lo tun jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin l’Ekoo, ẹgbẹ AG lo ba lọ, to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Ileṣa lẹgbẹẹ kan. Nigba ti nnkan n lọ deede, ọkan ninu awọn ti awọn Akintọla maa n fọrọ lọ tẹlẹ ni, ti wọn yoo si jọ jokoo gbe eto kalẹ lori ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Ṣugbọn ija ti de, orin gbogbo ti dowe: nigba ti awọn Akintọla da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ, wọn fẹ ki Refurẹẹni maa bọ lọdọ wọn, wọn ni awọn lo yẹ ko maa ba ṣe.

Ko tiẹ too digba naa ni wọn ti n fa a, lati igba ti ijọba ti bẹrẹ ni, lati aye ti Akintọla kọkọ ti da ẹgbẹ tirẹ, UPP, silẹ. Ṣugbọn wọn fa ọkunrin ọmọwe naa titi ko niru, o ni ojiṣẹ Ọlọrun loun, o ni awọn ohun ti oun le ṣe ati awọn ohun ti oun ko le ṣe, bawo ni ẹgbẹ kan yoo ṣe fa oun kalẹ, ti wọn yoo gbe oun wọle, ti oun yoo waa pada fi ẹgbẹ naa silẹ ba ẹgbẹ mi-in lọ, bawo ni oun yoo ṣe maa tẹle aṣaaju kan, ti iṣoro yoo waa ba aṣaaju naa, ti oun yoo waa tori bẹẹ pada lẹyin aṣaaju oun. Ṣe nitori atijẹ yii naa, Akinyẹmi kọ jalẹ, o loun ko ni i ba awọn Akintọla lọ. Ọrọ to ti wa nilẹ tẹlẹ niyẹn. Eyi lo ṣe jẹ pe nigba ti wọn lẹ Akintọla loko, ti wọn ho le e bii ole, to tun waa jẹ niwaju ileewe Ileṣa Grammar School ti Akinyẹmi ti jẹ ọga wọn ni, ko ro o lẹẹmeji to fi sọ pe iṣẹ ọwọ ọkunrin AG naa ni. O sọ fawọn tiẹ pe ọta awọn lo ṣiṣẹ naa, ṣugbọn wọn ko sọ iru ọrọ bẹẹ jade.

Lọrọ kan ṣaa, Ọlọrun nikan lo mọ iru iwadii ti awọn eeyan naa ṣe, iyẹn ijọba Akintọla, nitori ko too di ọsan ọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, iyẹn ọjọ Mọnde, ikede jade pe ijọba Western Region ti ti ileewe Ileṣa Grammar School pa. Wọn ni ki gbogbo awọn irinwo (400) ọmọ ileewe naa tete maa lọ sile iya wọn kia, ki wọn si ṣa ẹnu ọna ileewe ọhun ni kọkọrọ, eeṣin ko gbọdọ wọle sibẹ, ẹni ti wọn ba si ri nitosi ibẹ lẹyin wakati meji ti wọn ti kede, wọn yoo kọ ọ lọgbọn ti ko kọ nile wọn. Ọrọ naa da ina nla si gbogbo Ijẹṣa labẹ, paapaa awọn ijoye ilu, ina naa jo wọn kari ara. Idi ni pe ko too di ọjọ ti Akintọla ti ileewe naa pa, o ti di ọgbọn ọdun ti wọn da a silẹ, gbogbo Ijẹṣa lo si ri i bii ohun-ini wọn. Ọpọ awọn ọmọ Ileṣa to jẹ ileewe naa ni wọn ti jade, ati awọn ti wọn ki i ṣe Ijẹṣa, ṣugbọn to jẹ ibẹ ni wọn ti kawe ni wọn n sare beere lọwọ ara wọn pe ki lo ṣẹlẹ gan-an.

Bayii ni iwe Daily Times to jade ni ọjọ keje, oṣu kẹrin, 1964, ṣe gbe iroyin naa jade. Iwaju ni wọn gbe e si gadagba gadagba pẹlu akọle “Ilesa School shutWọn ti ti ileewe ọlọgbọn-ọdun to jẹ awọn araalu funra wọn lo da a silẹ, iyẹn Ilesha Grammar School, pa o, wọn si ti paṣẹ pe ki awọn akẹkọọ ibẹ ti wọn jẹ irinwo maa lọ sile wọn kiakia. Wọn ti le awọn naa lọ. Ohun to fa a ti wọn fi ti ileewe yii pa fungba diẹ naa ni iṣẹlẹ to waye ni Ileṣa ni Satide to kọja yii, nibi ti awọn eeyan ti ho le Prẹmia, Oloye Ladoke Akintọla ati igbakeji rẹ, Oloye Rẹmi Fani-Kayọde lori nigba ti wọn n lọ. Awọn mejeeji atawọn eeyan wọn n lọ sibi ti wọn ti fẹẹ ko ẹgbẹ oṣelu Nigerian National Democratic Party (NNDP) jade ni. Ijọba paapaa ti gbe igbimọ ẹlẹni-meji kan dide pe ki wọn wadii ohun to ṣẹlẹ naa kia. Aarọ yii ni igbimọ naa yoo bẹrẹ ijokoo wọn niluu Ileṣa.

“Ohun ti igbimọ naa fẹẹ wadii ni ẹsun aile kọ awọn ọmọ lẹkọọ ọmọluabi ati iwa daadaa lawujọ ti wọn fi kan olori ileewe naa, Ẹni-ọwọ Josaiah Akinyẹmi, ẹni toun naa jẹ aṣoju-ṣofin nile igbimọ aṣofin apapọ ti Naijiria l’Ekoo. Awọn ti wọn fẹẹ ṣewadii ọrọ yii ni Ọgbẹni I.A. Akioye ati Ọgbẹni A. Shofọlahan. Ileeṣẹ eto ẹkọ ni Western Region, ti ẹka awọn olubẹwo, lawọn mejeeji yii ti n ṣiṣẹ. Awọn mejeeji yoo tun yẹ ẹsun ipata ati ti wuligansi ti wọn fi kan awọn ọgọrun-un mẹrin awọn akẹkọọ ileewe naa. Wọn yoo wadii ohun to fa a ti awọn ọmọleewe naa fi huwa bii ọmọọta. Rẹfurẹẹni Akinyẹmi ti sun ipade awọn oniroyin ti wọn fẹẹ ṣe lanaa tẹlẹ siwaju, o sọ fun awọn oniroyin Daily Times pe oun yoo gbe atẹjade toun jade, lori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yii, ati bi ọrọ naa ti ṣe jẹ gan-an!”  Bayii ni iwe iroyin Daily Times ọjọ naa ti gbe e jade fun gbogbo aye ka.

Lẹsẹkẹsẹ ni ọrọ naa ti di ariwo, ko si si ohun meji ti wọn ri sọ ni Western Region ju ọrọ ileewe Ileṣa ati ti Akintọla yii lọ. Inu bi awọn eeyan, nitori wọn ri i ninu atẹjade yii pe Akinyẹmi gan-an ni ijọba fẹẹ ba ja. Ṣugbọn abuku lasan lọrọ naa tun da si wọn nigba, nitori Akinyẹmi ti wọn n wi yii, iyẹn olori ileewe Ileṣa Grammar School yii, ko si ni Ileṣa rara lọjọ ti wọn juko fun Akintọla ati awọn eeyan rẹ, o wa l’Ekoo to n ṣiṣẹ awọn aṣofin. Ni gbogbo igba ti awọn Akintọla si n binu ti wọn n fẹsẹ halẹ yii, wọn ko mọ, wọn ro pe ọkunrin naa wa nibi kan to ka jọ si to n wo awọn ọmọ rẹ bi wọn ti n lẹ olori ijọba West loko gidigidi. Nigba ti wọn yoo fi mọ pe ọrọ naa ko ri bi awọn ti ro o, ti wọn yoo fi mọ pe ẹni ti awọn n tori rẹ bọ ṣokoto ija ko si niluu, wọn ti gbe iwe jade, wọn si ti ti ileewe Ileṣa Grammar School pa.

Bẹẹ, alákàtàǹpó lo ṣe bi ọbọ ko gbọn ni o, ọbọ gbọn, ti inu ọbọ lọbọ n ṣe. Akintọla ati ijọba rẹ mọ ohun ti wọn n ṣe. Asiko kampeeni ti fẹẹ bẹrẹ, wọn si mọ pe bi wọn ko ba fiya to le jẹ awọn ti wọn juko lu Prẹmia ni Ileṣa, ki gbogbo ara West to ku ri i, bi wọn yoo ti maa fabuku kan Prẹmia kaakiri niyẹn. Iyẹn ni wọn ṣe sare gbe igbimọ naa dide, ti wọn si pe Akinyẹmi lẹjọ, ti wọn ko wadii, ki wọn mọ pe Akinyẹmi ko si nile. Bẹẹ ki i ṣe Ileṣa ni ọrọ naa ti kọkọ ṣẹlẹ, o ṣẹlẹ ni ilu Ọwọ naa ti awọn kan fẹẹ ra Prẹmia mu, ti wọn fẹẹ fagidi ja a laṣọ, bi wọn ṣe ribi de ọdọ rẹ ko ye ẹnikan. Koda, ọrọ naa bi Fani-Kayọde ninu, o ni awọn ọlọpaa to tẹle awọn ko mọ iṣẹ wọn bii iṣẹ rara, bi wọn ba mọ iṣẹ wọn bii iṣẹ ni, wọn ko ni i jẹ ki iru nnkan bẹẹ yẹn ṣẹlẹ lae. O ni bi awọn ba ti de Ibadan loun yoo da gbogbo wọn pada ki wọn ma tẹle awọn mọ, ki wọn pada si baraaki wọn.

Ohun to si ṣẹlẹ nibẹ naa ni pe Akintọla n bu Awolọwọ ni. Nigba to n ba awọn ara ilu Ọwọ sọrọ, o dojukọ wọn, o si wi bayii pe, “Igberaga lo pa ẹgbẹ Action Group. Igberaga lo pa wọn. Ki a too dibo ti a di kọja ni 1959, niṣe ni Oloye Awolọwọ n leri kiri, to n sọ pe oun loun maa wọle ibo naa, oun loun dẹ maa jẹ olori Naijiria akọkọ lẹyin ominira. Lọdọ Awolọwọ, ko si ọba to jẹ nnkan kan, ko si ijoye kan to ṣe pataki, ko si si eeyan nla kan to ja mọ kinni kan loju ẹ. Nigba ti Azikiwe fi ṣejọba, Awolọwọ n kanra mọ ọn, bẹẹ lo koriira Alaaji Ahmadu Bello to jẹ olori ijọba North, gbogbo wọn lo ṣa loun o fẹẹ ba ṣe. Ṣe awa nikan la a maa da ṣe ni?” Lẹyin naa lo sọ fawọn eeyan pe ki wọn ma daamu ara wọn kiri mọ, ẹgbẹ Dẹmọ ni ki gbogbo wọn darapọ mọ, ki wọn di ọmọ ẹgbẹ kia, nitori ko si ẹgbẹ to ni ibọwọ-fawọn-eeyan bii ẹgbẹ awọn.

Nitori pe o n bu Awolọwọ naa lawọn kan ṣe jade, ti wọn si pada lati kọlu oun ati awọn eeyan rẹ, ko too di pe awọn ọlọpaa tun ribi da si i, iyẹn lẹyin tẹnikan ti gba a mu ni o. Awọn ohun to jẹ ki wọn mura kankan si ọrọ ti Ileṣa yii ree, agaga nigba to tun jẹ ọmọ ẹgbẹ AG ni olori ileewe ọhun, ti wọn si ti wa a tẹlẹ lati le e lọ. Lọjọ ti wọn ti ileewe girama yii pa naa ni awọn ọlọpaa Ileṣa ko awọn mẹtadinlogun kan lọ si ile-ẹjọ Ileṣa Magistrate Court, wọn ni wọn huwa to le da ilu ru, wọn ni wọn da wahala silẹ, wọn ni janduku ti ko yẹ ko wa laarin igboro ni wọn. Wọn fẹsun kan wọn pe lasiko ti Oloye Akintọla ati awọn eeyan rẹ wa si Ileṣa, awọn eeyan naa dalu ru, wọn fẹẹ pa Prẹmia lara, ori Prẹmia lo ko Prẹmia yọ. Raimi Ajani ti gbogbo Ileṣa mọ si Raimi Sango ni wọn kọkọ mu siwaju adajọ naa lọhun-un, wọn lo ṣe Michael Molokun leṣe ni Okesa, n’Ilesa, nibẹ.

Bi wọn ṣe mu Raimi Sango jade, bẹẹ naa ni wọn mu Jimoh Alamu ati Iṣọla Bello jade. Wọn ni iwa wọn jọ ara, adaluru ni wọn, awọn naa da rogbodiyan silẹ lọjọ ti Akintọla ati awọn eeyan rẹ waa bẹ wọn wo. Lẹyin awọn mẹta yii ni wọn tun ko awọn mẹrinla mi-in jọ, ọlọpaa to ko wọn wa si fi wọn han adajọ pe bo ti n wo gbogbo wọn yii, ọdaran gidi ni wọn. O ni ki i ṣe pe wọn kan n fa wahala lasan, wọn tun maa n gbe awọn ohun ija oloro kaakiri. Ọlọpaa naa, David Iyare, to wa lati Ibadan sọ pe lọjọ ti Akintọla wa siluu Ileṣa yii, awọn eeyan kan bẹrẹ si i pariwo, ‘Aawo, Aawo, Aawo ati Ziiki, Ziiki, Ziiki’, bo tilẹ jẹ pe wọn mọ pe ọrọ to le da ijangbọn silẹ ni. Insipẹktọ Iyare ni ko tan sibẹ. O ni bi Akintọla ati awọn eeyan rẹ ti duro, niṣe lawọn meji kan jade pẹlu okuta lọwọ, ti wọn si bẹrẹ si i lẹ Pirẹmia naa loko, ti wọn n ju oko naa leralera.

Ọlọpaa yii ni bawọn mejeeji ti n juko lu Pirẹmia ni wọn tun kọju oko si awọn ero to waa pade wọn, nibẹ ni wọn si ti ṣe obinrin kan, Rosaline David ati ọkunrin kan, Michael Molokun leṣe, ti ẹjẹ si da jade lara wọn. Iyare ni lọjọ naa, awọn ri Raimi Sango to n gbe aake kaakiri, o si mura lati fi aake naa ṣa ẹnikẹni to ba duro. O ni awọn ti wa awọn mejeeji to ṣaaju awọn onijangbọn naa kan o, Raimi Sango ati Iyanda ni, awọn mejeeji si wa nile-ẹjọ. N ladajọ ba ni ki wọn tiẹ kọkọ gba beeli awọn mẹtala to ku, ki awọn maa lọ, ṣugbọn ki wọn mu Raimi Sango ati Iyanda, ki wọn ko wọn pọ mọ Jimoh Alamu ati Iṣọla Bello, ki wọn ti wọn mọle titi ẹjọ wọn yoo fi jẹ gbigbọ. Eyi ni pe gbogbo ọna pata ni ijọba Akintọla fi n ja lori ọrọ yii, wọn fẹẹ fi awọn ti wọn mu naa jofin ni. Wọn ko fẹ ki iru rẹ tun ṣẹlẹ ni ibi kankan ni Western Region, wọn fẹ ki Akintọla maa lọ ire, ko si maa bọ ire.

Ṣugbọn awọn ti wọn mọ bi ọrọ yii ti n lọ sọ pe ẹjọ ti ijọba Akintọla n ro ati ọrọ ti olori ijọba funra rẹ n sọ yii kọ ni oogun alaafia ti wọn n wa, wọn ni Akintọla gan-an ni ko ṣọ ara rẹ gidigidi. Wọn ni yoo ṣoro ki Akintọla too maa lọ silẹ Yoruba ko maa bu Awolọwọ, pe nibi yoowu to ba lọ to ti bu Awolọwọ nibẹ, ki oun naa ti mọ pe ija yoo ṣẹlẹ nibẹ, nitori awọn eeyan kan wa ti wọn ko ni i kuro lẹyin Awolọwọ laye, to jẹ ko si ohun ti wọn le ṣe fun wọn. Ohun to mu ki awọn aṣofin lati Ekiti kọwe si Akintọla niyi, wọn ni awọn ko fẹ ki ohun to n ṣẹlẹ kaakiri ṣẹlẹ l’Ekiti, nitori bo ba ṣẹlẹ nibẹ, ti ibẹ ni yoo le ju, awọn ko si fẹ wahala kan ti yoo ba awọn eeyan awọn. Awọn aṣofin Western Region naa ni gbogbo wọn o, awọn maraarun si pawọpọ, wọn kọwe lẹẹkan. Wọn ni bi Akintọla ba ti kawe yii, ohun ti awọn n sọ yoo ye e, yoo si mọ pe awọn ko fẹ wahala kan lọdọ awọn ni.

Awọn aṣofin maraarun ti wọn kọwe naa ni J. E. Babatọla, S. A. Akerele, D. A Atọlagbe, N. O. Arẹọla ati S. Okeya. Ohun ti awọn maraarun wi fun Akintọla ni pe ko yi ikede ati ipolongo rẹ pada. Wọn ni ohun ti awọn ri ni pe Akintọla fẹẹ fi tipatipa mu gbogbo eeyan pe ki wọn maa ṣe Ẹgbẹ Ọlọwọ, iyẹn NNDP, Ẹgbẹ Dẹmọ. Awọn aṣofin ni ohun to n da wahala silẹ niyẹn, nitori ki i ṣe gbogbo eeyan lo fẹran ẹgbẹ wọn. Ati pe ko si ere kan ti Akintọla yoo ri gba ninu ka maa bu Awolọwọ kaakiri, kaka bẹẹ, yoo maa gba ẹtẹ ati abuku nibi to ba lọ ni, eleyii ko si dara fun odidi Prẹmia. Awọn aṣofin kan waa ṣe ikilọ o, wọn ni bo jẹ oun, tabi igbakeji rẹ, tabi ẹni yoowu lo ba fẹẹ fi ipa mu awọn Ekiti lati ṣe ohun ti wọn ko fẹẹ ṣe, ki tọhun ti mọ pe oju oun naa yoo ri ohun ti ko fẹẹ ri, ohun to ba si tidi ẹ yọ fun un, ko mọ pe funra oun loun fọwọ fa a o.

Awọn Akintọla gbọ ọrọ naa ni, wọn ko gba, o jọ pe orukọ Awolọwọ ti wọn n da kiri ati eebu ti wọn n bu u yẹn ni wọn ti gbojule pe yoo gbe ẹgbẹ wọn wọle. Awọn ara Ileṣa ni tiwọn ni eyi to tilẹ wa nilẹ yii ko ti i kan awọn, ki Akintọla ṣi ileewe awọn pada ni alaafia le fi wa, nitori awọn o le gba ki wọn ti ileewe ayebaye pa. Awọn igbimọ ti wọn gbe dide naa ti bẹrẹ iwadii, abajade iwadii wọn ni gbogbo eeyan si n reti, wọn fẹẹ wo ohun ti yoo tidi sagbasula naa yọ. Ṣugbọn ko jọ pe Akintọla ti i ṣetan lati ṣi ileewe naa, o tilẹkun Ileṣa Grammar School, o fi kọkọrọ pamọ!

(108)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.