Ọlọpaa ti mu awọn afurasi to ja olootu iweeroyin Guardian lole l’Ekoo

Spread the love

Awọn ọlọpaa Ayaraṣaṣa (RRS), ti ipinlẹ Eko ti mu awọn mẹta kan ti wọn ni wọn ja Olootu iweeroyin elede oyinbo kan, Guardian, Ọgbẹni Debọ Adeṣina, lole ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, lagbegbe Oshodi-Oke, niluu Eko.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni wọn ṣafihan wọn ni olu ileeṣẹ ọlọpaa. ***(Ta lo salaye) O ṣalaye pe awọn ọlọpaa Ayaraṣaṣa (RRS), lo mu Tunde Ṣẹgun, ẹni ọdun mẹtalelogun, Ayọ Ọmọniyi, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Samson Oyelẹyẹ, ẹni ọdun mejilelogun.

Lasiko ti wọn n yẹ ara wọn wo, ni wọn ba foonu Samsung ati kaadi idanimọ ọga awọn akọroyin naa lọwọ wọn.

O ni ***(ta lo ni) awọn ti dari ẹjọ wọn lọ si ọdọ ẹka to n gbogun ti iwa idigunjale fun iwadii to ni kikun.

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.