Ọlọpaa mẹrin wọ wahala, ẹsun idigunjale ni wọn fi kan wọn

Spread the love

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan awọn oṣiṣẹ wọn mẹrin kan, Insipẹkitọ Amiete, Sajẹnti Gbemunu Samuel, Sajẹnti Afọlabi Oluwaṣeun ati Kọburu Adigun Ọmọtayọ, ti gbogbo wọn n ṣiṣẹ ni teṣan ọlọpaa to wa ni Ijanikin, niluu Eko.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu to kọja, ni awọn ọlọpaa naa mu Theodore Ifunanya, wọn ni awọn fura si i pe adigunjale ni. Lasiko ti wọn n yẹ ara rẹ wo ni wọn ba ẹgbẹrun lọna irinwo din laaadọta owo ilẹ okeere  (350,000.00 Cefas), nikaawọ rẹ, ti wọn si gba a.

Lẹyin iwadii, wọn ri i pe Ifunnaya ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn nigba ti wọn da a silẹ, to si beere owo ti wọn gba lọwọ rẹ ni awọn ọlọpaa na kọ jalẹ lati da a pada fun un.

Ọrọ yii ni ọmọkunrin naa fi to ọga ọlọpaa to wa ni teṣan Area K, laduugbo Marọgbọ, ACP Hope Okafor, leti, ẹni to paṣẹ pe ki wọn da owo rẹ pada fun un lẹsẹkẹsẹ.

Lẹsẹkẹsẹ ni ọga ọlọpaa naa fi ẹjọ awọn afurasi kanda ninu iṣẹ ọlọpaa yii sun Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal,  ẹni to paṣẹ pe ki wọn ṣewadii wọn. Bakan naa ni Edgal paṣẹ pe ki wọn ṣewadii ọga ọlọpaa to wa ni teṣan Ijanikin, ti aṣiri rẹ ba si tu pe o lẹbọ lẹru, awọn yoo mu ẹsun rẹ de ọdọ ọga agba ọlọpaa lorileede yii.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.