Olopaa ipinle Osun ti mu awon ti won ji akọwe ẹgbẹ onimọto nipinlẹ Ondo gbe

Spread the love

Awọn ọmọkunrin mẹta ti wọn ji akọwe ẹgbẹ onimọto, NURTW nipinlẹ Ondo atiyawo rẹ gbe, lọwọ ti tẹ niluu Oṣu, nipinlẹ Ọṣun bayii.

 

Awọn afurasi mẹtẹẹta ọhun ni Henry Omenihu ẹni ọdun mẹrinlelogun, Paul Chituru toun naa jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun pẹlu Henry Bright, ọmọ ọdun mejidinlogun.

Nigba ti kọmisannaa ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Adeoye Fimihan, n ṣafihan wọn lọsan-an ọjọ Satide to kọja, o ni ọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni wọn ji Ọgbẹni Kayode Agbeganji atiyawo rẹ, Oyeyẹmi Agbeganji gbe.

 

O ni bi wọn ṣe gbe awọn eeyan ọhun ni wọn fori le ipinlẹ Cross Rivers, latibẹ ni wọn si ti gba owo ti wọn beere lọwọ awọn mọlẹbi ọkunrin naa ko too di pe wọn tu wọn silẹ.

 

Latigba ti wọn si ti tu wọn silẹ lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii titi tọwọ fi tẹ awọn mẹtẹẹta ninu aṣọ awọn sọja ti wọn wọ.

 

Ọgbẹni Fimihan ṣalaye fawọn oniroyin pe niluu Oṣu, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Atakumọsa lọwọ ti tẹ awọn mẹtẹẹta lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.