Ọlọpaa, ewo waa ni tepe!

Spread the love

Nnkan meji ṣẹlẹ ni gbara ti wọn dibo ẹgbẹ PDP tan ni Ekiti. Dayọ Adeyẹye kọkọ ti sọ pe oun ko ni i binu bi wọn ba dibo naa tan, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ ti wọn dibo tan lo ti pe awọn oniroyin jọ pe inu oun ko dun si ibo naa, oun n fi ẹgbẹ PDP silẹ. Ko ti i sọ inu ẹgbẹ to n lọ, ṣugbọn o daju pe ko le lọ si APC, nitori ninu AD lo ti jade lọọ di ọmọ ẹgbẹ PDP. Ẹẹkeji ni pe Fayoṣe fi ẹjọ ọkunrin agbalagba oloṣelu naa sun gbogbo aye. O ni ni gbara ti wọn dibo tan ti wọn si ti ka a to ti han pe Ẹlẹka ti oun mu silẹ lo wọle, niṣe loun bẹrẹ si i pe awọn oloṣelu to ku ti wọn jọ du ipo naa lati bẹ wọn, ki oun si ṣalaye fun wọn pe iṣẹ to delẹ yii, iṣẹ gbogbo awọn ni. O ni loootọ loun ṣe atilẹyin fun Ẹlẹka, ṣugbọn oun ko le ma ṣe atilẹyin fun un nitori igbakeji oun ni, o si tun fi ootọ ṣiṣẹ pẹlu oun, ofin ẹgbẹ awọn si faaye gba oun lati wa lẹyin ẹni to ba wu oun. Fayoṣe ni ṣugbọn bi foonu oun ṣe dun leti Adeyẹye, ti oun si ni ki oun bẹrẹ si i ki i, niṣe lo fi epe bọnu, to si bẹrẹ si i wọn oun ni epe oriṣiiriṣii, o si ṣepe titi foun ti oun fi pa foonu naa ni, nitori ko sinmi epe, ko si fẹẹ gbọ nnkan kan lẹnu oun. Agbalagba to n rojọ, to n laagun, ẹkun lo n sun. Ki Dayọ Adeyẹye too binu rangbọndan bẹẹ, o ni ohun ti Fayoṣe ti ṣe fun un. Ọkunrin naa ti fẹẹ ṣe gomina Ekiti ọjọ pẹ, o si ṣee ṣe ki Fayoṣe ti leri fun un lasiko ti oun naa fẹẹ du ipo lọjọsi pe lẹyin ti oun ba ti ṣetan, oun Adeyẹye loun yoo gbe e fun. Ṣugbọn awọn oloṣelu ko lankuuri, ọrọ ko si ri bẹẹ mọ niyẹn, Fayoṣe fẹẹ gbejọba fẹni ti yoo baṣiri ẹ bo ba lọ tan, ti yoo si maa gbọrọ si i lẹnu, ti yoo si da bii pe oun naa lo n ṣejọba Ekiti bi Tinubu ti n ṣe l’Ekoo. Boya ni ko jẹ ohun to fa ibinu rẹpẹtẹ bẹẹ niyẹn. Ṣugbọn Dayọ Adeyẹye ti dagba nidii oṣelu ju ko ma mọ bi kinni naa ti n lọ si lọ, ṣebi ole gbe e, ole gba a ni, abi meloo loloṣelu wọn to n ṣiṣẹ nitori awọn eeyan ilu wọn, onikaluku n wa bi yoo ti jẹun yo naa ni. Iyẹn ni ko ṣe gbọdọ la epe lọ: wara ko si loni-in niyẹn, wara le wa lọla; ẹni to ṣe ohun to dun ni nidii oṣelu loni-in, o le pada waa ṣe ohun ti yoo pada dun mọ ni lọla. Ṣugbọn ẹni to n ṣepe fun ni ko ro daadaa si ni, bi iru yẹn ba si lagbara lati ṣeeyan leṣe, ko ni i pẹ rara ti yoo fi la oluwarẹ ni nnkan lori. Iyẹn ni gbogbo eeyan ṣe n beere pe, “Ọlọpaa, ewo n tepe!”

(75)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.