Ọlọpaa ti mu ondupo sẹnetọ ati ẹṣọ ẹ to yinbọn paayan meji nibi ọdun Ọranmiyan l’Ọyọọ

Spread the love

Awọn agbofinro ti ra oludije fun ipo sẹnitọ nipinlẹ Ọyọ, Oloye Bisi Ilaka, mu, nitori bi ọkan ninu awọn to n ṣọ ọ ṣe yinbọn paayan meji laafin Ọyọ. Bẹẹ lọwọ ti tẹ ẹṣọ ẹ to yinbọn pa awọn eeyan yii.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adekunle Ajiṣebutu, lo fidi ọrọ naa mulẹ nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun to waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, iyẹn Satide to kọja yii.

Ilaka, ẹni to n dupo sẹnetọ fun ẹkun idibo Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ ninu idibo ọdun 2019 lo lọọ kopa nibi aṣekagba ayẹyẹ ọdun Ọranmiyan ti Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi (Kẹta), maa n ṣe lọdọọdun, ti iṣẹlẹ aburu ti ko lero si gbẹyin igbesẹ naa fun un.

Awọn to wa nibi ayẹyẹ ọhun to waye ninu aafin Ọyọ fidi ẹ mulẹ pe lẹyin ti Oloye Ilaka, ẹni to wọsọ bii ginni funfun lọ sibi ariya naa lo ogun iṣẹju nibẹ lo mura lati fi oju agbo naa silẹ, ti awọn eeyan si rọ tẹle e lẹyin, ti wọn n sa a ni mẹsan-an mẹwaa nitori kó le fun wọn lowo.

Gẹgẹ bi akọroyin wa ṣe gbọ, bo ṣe fọn owo saarin awọn eeyan naa lati dọgbọn le wọn kuro lọna lo ko sinu mọto rẹ lati yara jade kuro ninu aafin. Ṣugbọn nigba ti ọkọ yoo fi kọju si ọna abajade kuro laafin, pupọ ninu awọn to n tọrọ owo lọwọ ẹ  wọnyi ti rọ di oju ọna, wọn ni o ni lati fun awọn lowo dandan ni.

Nigba naa ni ẹṣọ alaabo oloṣelu yii yinbọn lẹẹmẹta lera lera. Oun ṣe bẹẹ lati dẹruba awọn eeyan naa, ki awọn le ribi ba tiwọn lọ ni, ṣugbọn ko si eyi to ṣofo ninu ọta mẹtẹẹtạ to gba ẹnu ibọn rẹ jade, meji ninu ẹ paayan meji, tọkunrin tobinrin, ẹkẹta si ṣe obinrin mì-ín lẹṣẹ. N nibẹ ba daru lẹsẹkẹsẹ pẹlu bi kaluku ṣe n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi ara ẹ.

Ọkan ninu awọn to ṣalabaapade iku oro yii lo jẹ ọkunrin to n kiri kasẹẹti toun ti baagi ọja to n ta to gbe pọn sẹyin. Agbari lọta ibọn ti ba a.

ALAROYE gbọ pe wọn papa wọ Ilaka atawọn ẹmẹwa ẹ jade ninu ọkọ, wọn si lu wọn nilukulu ki ọkunrin oloṣelu naa too ri awọn kan gba a silẹ laarin awọn ero naa, ti wọn si wa ibi gbe e sa jade.

Dẹrẹba ọkunrin oloṣelu yii lo pada fori fa iya ti gbogbo wọn iba jọ jẹ pẹlu bi awọn eeyan ṣe lu u ja sihoho. Gbogbo ariwo to si n pa pe ki i ṣe oun loun yinbọn ko wọ awọn eeyan naa leti.

Nigba to si woye pe awọn eeyan wọnyii le ṣe bẹẹ gbẹmi oun, niṣe lo sare pada soju agbo nihooho ọmọluabi to wa naa. Eyi lo si jọ pe Ọlọrun fi gbẹmi ẹ la pẹlu bi awọn alejo pataki to wa nibi ayẹyẹ naa ṣe gba a silẹ lọwọ awọn ero ti wọn n lu u tibinu tibinu.

Ileewosan ijọba to wa niluu Ọyọ la gbọ pe wọn gbe obinrin to farapa nibi iṣẹlẹ ọhun lọ fun itọju.

SP Ajiṣebutu, ẹni to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe iwadii alagbara ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ yii ni ibamu pẹlu aṣẹ ti CP Abiọdun Odude ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ pa fawọn agbofinro.

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.