Ọlọpaa da ipade awọn ẹgbẹ okunkun meji ru nipinlẹ Ọyọ

Spread the love

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nnkan ko rọgbọ fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kaakiri ipinlẹ Ọyọ mọ bayii, gbogbo ibi ti wọn ti n ṣepade lawọn agbofinro n lọọ ka wọn mọ, ti wọn si n ko wọn da satimọle.

Laarin ọsẹ meji sira wọn, awọn ọmọ ẹgbẹ Ẹiyẹ ati Aiye ti wọn jẹ ikọ oriṣii ẹgbẹ okunkun meji ọtọọtọ lawọn ọlọpaa ba nnkan jẹ mọ lọwọ pẹlu bi wọn ṣe lọọ ka wọn mọ ibi ti wọn ti n ṣepade, ti wọn si fi panpẹ ọba ko wọn.

Ileetura kan niluu Ọyọ, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Aiye ti n ṣepade làwọn agbofinro kọkọ ya wọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja. Nigba naa lọrọ di pẹ̀ẹ́-ǹ-túká, ti kaluku ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ti ọrọ si di ẹni ori yọ, o dile. Ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro tẹ mẹrin, Durodọla Ọlamide, Fẹmi Aluko, Fáróyèjẹ Ayanfẹ ati George Ifeanyi. Ọlamide ati Fẹmi ni wọn ti jẹ akẹkọọ-jade nileewe  Ọyọ State College of Education to wa niluu Ọyọ, nigba ti Ifeanyi ati Ayanfẹ jade ni fasiti ipinlẹ Ekiti (Ekiti State University).

Egboogi oloro ti wọn n pe ni igbó lawọn agbofinro ka mọ wọn lọwọ pẹlu fila atawọn aṣọ idanimọ ẹgbẹ buruku wọn naa.

Lọsẹ to lọ lọhun-un, ni nnkan bii aago mọkanla aarọ, lawọn ọlọpaa ya wọ ibudo ipade awọn ọmọ ẹgbẹ Ẹiyẹ, nibi kọlọfin kan laduugbo Bodija, n’Ibadan, ti wọn si ri mẹrin mu ninu awọn naa.

Orukọ wọn ni Ọjẹbisi Johnson, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29); Popoọla Ṣeun, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25); Afeez Fatai, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ati ọmọọdun mẹrindinlọgbọn (26) kan to n jẹ Taiwo Adeyẹmi.

Ṣaaju lọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Shina Olukolu, ti gbe ikede jade fun gbogbo ara ipinlẹ naa lati kun fun iṣọra, ki wọn si tete ta awọn agbofinro lolobo nibikibi ti wọn ba ti ṣakiyesi pe awọn ọdọ kan n ṣepade ìkọ̀kọ̀ laduugbo wọn.

Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran yii, CP Olukolu sọ pe aṣeyọri ti awọn ṣe ni pa bi wọn ṣe kapa awọn ẹgbẹkẹgbẹ yii ko ṣẹ̀yìn ikede ti awọn ti kede, ati bi awọn ọlọpaa ṣe tete gbe igbesẹ ni kete ti wọn ta wọn lolobo nipa awọn ipade láabi ti wọn n ṣe.

Iwadii awọn ọlọpaa gẹgẹ bi ọga wọn yii ṣe fidi ẹ mulẹ fi han pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ni wọn ti maa n yọ awọn araalu lẹnu, to jẹ pe bi wọn ṣe n digunjale ni wọn n fipa ba awọn obinrin

Gbogbo awọn tọwọ ba yii ni wọn fidi ẹ mulẹ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn, ati pe ninu ipade lawọn agbofinro ti waa ko

Awọn ọmọ ẹgbẹ yii tọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ kaakiri ipinlẹ Ọyọ laarin oṣu mẹrin sasiko yii ko din laaadọta (50) gẹgẹ bi iwadii akọroyin wa.

Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ naa ti ni laipẹ yii lawọn eeyan yii yoo foju ba ile-ẹjọ.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.