Ole ni Lekan ja l’Abẹokuta to fi dero ẹwọn lakọọkọ Ile-ẹjọ ti ran an lọdun meje ni-in lori ẹsun kan naa

Spread the love

Lẹyin to tẹwọn de laipẹ yii lori ẹsun ole jija, kootu Majisireeti to n jokoo n’Iṣabọ, l’Abẹokuta, tun ti ran Lekan Famuyiwa, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lẹwọn ọdun meje mi-in bayii.

 

Ọsẹ to kọja yii ni Adajọ-agba Aliu Ṣonẹyẹ ran Lekan lẹwọn tuntunt yii, nigba tawọn ọlọpaa mu un pe o ji irinṣe ti wọn fi n jo irin nina, eyi ti iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira(70,000).

 

Ṣaaju asiko yii ni Adajọ Ṣonẹyẹ ti ju Lekan sẹwọn, nigba ti wọn mu un wa si kootu naa pe o fọle onile, o si jale nibẹ. Ko too tun lọọ ji irinṣẹ jorin-jorin to gbe e de kootu lasiko yii.

 

Gẹgẹ bi agbefọba Famuyiwa Matthew ṣe ṣalaye ọrọ naa fun kootu, o ni ọjọ ọdun tuntun, ọjọ kin-in-ni, oṣu ti a wa yii, ni Lekan wọ ṣọọbu ọkunrin kan to n jẹ Tobi Ọlatunji, labule Agbaakin Ooṣa, Bode-Olude, l’Abẹokuta, ibẹ lo ti ji irinṣẹ naa lọsan-an gangan, ṣugbọn awọn eeyan ka a mọbẹ, ti wọn si gba a lọwọ ẹ, ti wọn fa a fọlọpaa.

 

Nigba ti Adajọ Ṣonẹye tun ri olujẹjọ yii lori ẹsun kan naa, o ṣalaye fun kootu pe ẹjọ mẹta mi-in to jẹ ti ole jija ṣi wa nilẹ to n jẹ lọwọ, yatọ si pe oun ti ran an lẹwọn ri lori ẹsun kan naa.

 

O ni iwa ti Lekan n hu yii ko jọ iwa ẹni to yẹ lawujọ eeyan rara, nitori gbogbo igba to ba lanfaani ati wa nita lo n jale.

 

Lekan funra rẹ ko ba adajọ jiyan, bi wọn ṣe beere lọwọ ẹ pe ṣe o jẹbi ẹsun ole jija tabi bẹẹ kọ lo ti dahun pe bẹẹ ni, oun jale loootọ loun tun fi dero kootu.

 

Nigba naa ladajọ paṣẹ pe ko pada sọgba ẹwọn, ko lọọ lo ọdun

meje mi-in nibẹ pẹlu iṣẹ aṣekara. Boya bi yoo ba fi jade lọtẹ yii, yoo ti ronu piwada, ko si ni i jale mọ to ba foju kan igboro lẹyin ọdun meje.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.