Ọlẹ lọkọ mi, ko niṣẹ kankan lọwọ-Idayat Ọdun mẹwaa sẹyin ni mo ṣiṣẹ kẹyin-Sulaiman

Spread the love

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni Idayat Owonikoko wọ ọkọ rẹ, Sulaiman Owonikoko, to ti fẹ ni ọdun mẹrindinlogun sẹyin lọ si kootu Agege, o loun fẹẹ kọ ọ, nitori ọlẹ paraku ni.

Obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji naa sọ pe ọdun 2002 lawọn fẹra, awọn si bimọ mẹta. Iyaale ile yii ṣalaye fun kootu pe oun ko nifẹẹ Sulaiman mọ, o si tun maa n halẹ mọ oun, awọn idi toun fi fẹẹ kọ ọ silẹ niyẹn.

Idayat sọ pe oun loun n gbọ bukaata ile, ọkọ oun ki i da si nnkan kan. Bakan naa, o ni Sulaiman yọbẹ si ọmọ oun lọjọ kẹrinlelogun, oṣu to kọja, pe oun yoo gun un pa. O fi kun un pe ọkọ oun yii ko niṣẹ kankan lọwọ, ko si si iṣẹ ti wọn ba a ri to maa ṣe e daadaa.

Ninu awijare ọkọ iyawo, o sọ pe ainiṣẹ lọwọ naa ki i ṣe ẹbi oun. Sulaiman ni ọdun mẹwaa sẹyin loun ti ṣiṣẹ kẹyin, iyawo oun lo n bọ oun latigba naa.

O ni ko si ootọ kankan ninu ẹjọ ti obinrin naa ro kalẹ. Bẹẹ lo ni oun ṣi nifẹẹ rẹ gan-an, ki kootu ma tu awọn ka.

Adajọ Patricia Adeyanju ati awọn ọmọ igbimọ rẹ sun igbẹjọ wọn si ọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun to n bọ. O ni awọn mejeeji ko gbọdọ ja ko too di ọjọ naa. Bakan naa lo paṣẹ fun wọn ki wọn mu awọn mọlẹbi wọn lẹyin ti wọn ba n bọ.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.