Ọlatunji fee sa iya e pa l’Ekiti

Spread the love

Lori pe o dunkooko mọ iya to bi i lọmọ, Rachael Aladewọlu, pe oun yoo gbẹmi ẹ, ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Ọlatunji Aladewọlu, ti foju bale-ẹjọ majisreeti agba tilu Ado-Ekiti.

Afurasi naa to jẹ ọmọ keji ninu ọmọ marun-un ti obinrin naa bi ni Inspẹkitọ Oriyọmi Adewale to ṣoju ijọba ṣalaye pe o huwa naa lọjọ kọkanla, oṣu yii, laduugbo Surulere, Irọna, l’Ado-Ekiti, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ.

O ni afurasi dukooko mọ iya rẹ lọjọ naa pe oun maa fi ada ṣa a pa, eyi to tako abala kẹrindinlaaadọrun-un iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2012 tipinlẹ Ekiti n lo.

Ṣugbọn iya afurasi to tun jẹ olupẹjọ bẹ kootu pe ki wọn ma ran an lẹwọn, oun kan fẹ ki wọn paṣẹ fun un ko kuro nile oun ni, koun le fọkanbalẹ lo igbesi-aye oun.

Adajọ Modupẹ Afẹnifọrọ gba beeli Ọlatunji pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira ati oniduuro meji ti ọkan ninu wọn gbọdọ jẹ mọlẹbi rẹ, to si niṣẹ gidi lọwọ. O ni awọn oniduuro gbọdọ maa gbe lagbegbe ile-ẹjọ, ki wọn si ni adirẹsi tawọn ọlọpaa jẹrii si.

Bẹẹ lo paṣẹ pe ki olujẹjọ naa ko kuro nile iya rẹ ko too di ọjọ igbẹjọ, iyẹn ọjọ kẹrin, oṣu to n bọ.

(61)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.