Ọlaniyi ṣẹ Yahoo dẹwọn l’Abẹokuta, kootu tun gbẹsẹ le mọto ẹ

Spread the love

Jibiti ori ẹrọ ayelujara ti a mọ si Yahoo ti ran ọkunrin kan, Adeitẹ John Ọlaniyi, lọ sẹwọn oṣu marun-un bayii, bẹẹ ni ile-ẹjọ tun gbesẹ le mọto ẹ to fi owo eru naa ra niluu Abẹokuta.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ni wọn gbe Ọlaniyi wa sile-ẹjọ giga to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta. Ajọ to n ri si ẹsun to ba jẹ mọ jibiti (EFCC) lo mu olujẹjọ naa lẹka wọn to wa n’Ibadan.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni gbigba owo lọwọ ẹlomi-in nipa pipe ara ẹni loun ti a ko jẹ, eyi to ni i ṣe pẹlu ẹrọ ayelujara.

Owo ilẹ okeere ti i ṣe Dọla ni lọọya EFCC, Shamsideen Bashir, sọ fun kootu pe Ọlaniyi fi eru gba lọwọ oyinbo kan, lẹyin to pe ara ẹ lohun ti ko jẹ fun un, ti oyinbo si fowo ranṣẹ si i.

Ẹṣẹ yii lodi si abala kejilelogun, ẹka keji, ofin jibiti ori ayelujara ti wọn ṣe lọdun 2005, ijiya ẹwọn si wa fun un gẹgẹ bi kootu ṣe wi.

Ọlaniyi funra ẹ ko jiyan nigba ti wọn ka awọn ẹsun naa si i leti, o loun jẹbi.

Adajọ Ibrahim Watilat paṣẹ pe ki Ọlaniyi lọọ ṣẹwọn oṣu marun-un, ko si da ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin din laaadọta Dọla(750, 000 Dollar) to feru gba lọwọ oyinbo pada.

Lẹyin naa ladajọ sọ pe mọto ayọkẹlẹ Honda Accord ẹ naa yoo lọ si i pẹlu, bẹẹ ni kọmputa alaagbelatan ati Iphone X-Max ẹ naa yoo di ẹru ijọba.

(45)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.