Ọladeji gun Bayọ pa nibi ayẹyẹ ọjọọbi l’Agbado

Spread the love

Awọn ọlọpaa Agbado, nipinlẹ Ogun, ti mu ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọladeji Hamzat, ohun ti wọn mu un fun ni pe o gun ọrẹ ẹ, Bayọ, pa lode ọjọọbi kan to waye nile ọti Hummes, lalẹ ọjọ Ẹti, Fraide, to kọja yii.

Ohun ti a gbọ ni pe ọrẹ ati-kekere ni Hamzat to gun Bayọ pa yii pẹlu oloogbe naa, ṣugbọn iṣẹ aje ti gbe Hamzat lọ si Abuja ni tiẹ, nibi to ti n siṣẹ gẹgẹ bii onimọ ẹrọ kọmputa.

Lọjọ ti wahala yii waye, ọrẹ wọn kẹta to n jẹ Owoṣeeni lo n ṣọjọọbi nile ọti Hummes to wa l’Agbado, nipinlẹ Ogun, wọn si ti n ṣe faaji lọ ki Ọladeji too de ba wọn lẹnu ẹ ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ.

 

Bo ti de ni wọn lo n ki gbogbo eeyan to wa nikalẹ, ṣugbọn Bayọ to pada doloogbe yii sọ pe Ọladeji ko ki oun bo ti ki gbogbo eeyan to, wọn lo sọ pe o foju pa oun rẹ. Ko pẹ ti ọrọ a ki ni, a o ki ni naa fi mu ariyanjiyan wa, lo ba di pe wọn n tahun sira wọn.

 

Nigba naa ni wọn ni Ọladeji Hamzat ki igo ọti kan mọlẹ, lo ba fọ ọ poo, ọrun Bayọ ti wọn jọ n tahun sira wọn lo ki igo naa bọ, bi ẹjẹ ṣe bo ọmọkunrin naa niyẹn.

Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni Hamzat ti fẹẹ sa lọ, Bayọ to gun nigo si n gbiyanju lati jade sita ninu ile ọti naa, ṣugbọn ko lagbara rara. Awọn ti wọn jọ wa nibẹ lo sare gbe e lọ sọsibitu, ṣugbọn awọn yẹn ko gba a. Wọn tun gbe e lọ sọsibitu keji, wọn ko tun gba a, ki wọn too waa gbe e lọ si ọsibitu jẹnẹra Ifakọ-Ijaye, nibi to pada dakẹ si.

 

Latigba ti wọn ti mu Hamzat to gun ọrẹ ẹ pa yii ni wọn ti taari ẹjọ rẹ si ẹka to n ri si iwa ipaniyan ati iwa ọdaran bẹẹ nipinlẹ Ogun, ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, Abimbọla Oyeyemi si fidi ẹ mulẹ pe bẹẹ lo ri loootọ, o ni Ọladeji yoo foju ba kootu laipẹ ojọ

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.