Okoji dana sun ara rẹ nibi to ti n sun igbo l’Orisunmibare

Spread the love

Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Okoji Godstime la gbọ pe o dana sun ara rẹ nibi to ti n gbiyanu ati sun igbo labule Orisunmibare, nijọba ibilẹ Idanre, nipinlẹ Ondo.

 

Okoji ti wọn ni aisan warapa n ba finra lati bii ọdun diẹ sẹyin ni wọn ni o ni oko kekere kan to ṣan lẹgbẹẹ ile wọn, eyi to fẹẹ fi gbin awọn nnkan jijẹ.

 

Lẹyin ti gbogbo awọn araale yooku ti jade ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ iṣẹlẹ ọhun ni wọn ni ọkunrin yii lọ sibi oko to ti san, o gba gbogbo panti to wa nibẹ jọ, o si sọ ina si i.

 

Nibi to ti n sun panti ọhun lọwọ ni wọn ni aisan warapa rẹ ti gbe e, to si ṣubu sinu ina, aisi nitosi awọn araale rẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa waye la gbọ pe o ṣokunfa bi ko ṣe ri ẹni gbe e titi to fi jona ku sinu ina to fọwọ ara rẹ da.

 

Ẹnikan ninu awọn ẹbi rẹ ni wọn lo kọkọ ri ajoku oku oloogbe ọhun, to si lọọ fi ohun to ri to awọn araale yooku leti.

 

Wọn ti gbe oku oloogbe yii lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa ni Alade-Idanre fun ayẹwo, bakan naa la gbọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori ọrọ iku rẹ.

 

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.