Ọkọ tẹ John pa nibi to ti n sa fawọn ọlọpaa l’Ọba-Ile

Spread the love

Ọkunrin ẹni ogun ọdun kan, Polir John Lohbut, ti ṣalabaapade iku ojiji nibi to ti n sa fawọn ọlọpaa niluu Ọba-Ile.

 

Ni nnkan bii aago meje aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja lọhun-un, niṣẹlẹ naa waye loju ọna marosẹ to wa lagbegbe ileewe girama Ejiọba, niluu Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, nipinlẹ Ondo.

 

Eto gbaluu-mọ oloṣooṣu to maa n waye laarin aago meje si mẹwaa gbogbo ọjọ Abamẹta, Satide, to ba ti kẹyin oṣu nipinlẹ Ondo ti wọn n ṣe laaarọ ọjọ naa lo mu ki ọkunrin ọhun tete maa sa lọ sile lẹyin to ṣiwọ lẹnu iṣẹ ọdẹ to ṣe mọju nileeṣẹ to ti n ṣiṣẹ.

 

Asiko to de ileewe Ejiọba lo ba awọn ọlọpaa kan loju ọna ti wọn n gbiyanju lati da a duro, ṣugbọn to kọ ti ko duro fun wọn.

 

Ibi to ti n wọna ati sa mọ wọn lọwọ lo ti lọọ ko sẹnu taya ọkọ tipa kan to n lọ jẹẹjẹ loju ọna tirẹ, to si tẹ ẹ pa loju ẹsẹ.

 

Awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe ere asapajude ti awakọ tipa ọhun n sa lasiko ti John jana mọ ọn lẹnu lo ṣokunfa bi ọkọ naa tun ṣe wọ oku rẹ diẹ loju ọna marosẹ naa, leyii to mu kawọn ẹya ara rẹ ja kaakiri oju titi.

 

Ibinu ohun iṣẹlẹ naa lo mu kawọn ọdọ ti wọn jẹ ẹya Hausa niluu Ọba-Ile  bẹrẹ ifẹhonu han, ti wọn si di oju ọna marosẹ ọhun pa pẹlu taya ti wọn dana sun soju ọna ọhun.

Ori eyi ni wọn wa ti Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Olugbenga Adeyanju, fi ko awọn ọlọpaa kan lẹyin lọ sibi iṣẹlẹ ọhun lati pẹtu sawọn ọdọ to n fẹhonu han ninu.

 

Gbogbo akitiyan kọmisanna ọlọpaa lati ri ọrọ naa yanju nitubi- inubi ko seso rere nitori pe dipo kawọn ọdọ naa jawọ ninu ifẹhonu han ti wọn n ṣe, niṣe ni wọn doju ija kọ awọn ọlọpaa to waa pẹtu si wọn lọkan.

 

Nigba tawọn agbofinro ri i pe ifẹhonu han naa ti fẹẹ dija igboro ni wọn wa gbogbo ọna lati sa kuro nibi iṣẹlẹ ọhun.

 

Awọn isọri ọlọpaa mi-in ti wọn ko wa sibẹ ni wọn pada kapa awọn ọdọ Hausa naa, ti wọn si fipa le wọn kuro loju titi ti wọn ti n fẹhonu han.

 

Oludamọran fun Gomina Akeredolu lori ọrọ awọn Hausa ati Fulani, Ọgbẹni Bala Umaru, sọ pe awọn ọdọ kan ti wọn wa lati Lantans, nipinlẹ Jos, ni wọn n fẹhonu han nitori ọmọ bibi ipinlẹ naa ni oloogbe yii.

 

O waa rọ awọn to n fẹhonu han lati gba alaafia laaye, ki wọn si ṣọra fun ṣiṣe idajọ lọwọ ara wọn.

 

Bakan naa ni Ọlọba tilu Ọba-Ile, Ọba Oluwadare Agunbiade, rọ awọn ọdọ lati fọwọ wọnu, ki wọn si yago fun ohunkohun to le di alaafia ati isọkan to wa laarin awọn olugbe ilu Ọba-Ile lọwọ.

 

Iṣẹ ọdẹ, ọkada ati mẹkaniiki la gbọ pe John to doloogbe ọhun n ṣe ko le rowo tujọ lati wọ ileewe giga ti wọn ti n kọ nipa eto ọgbin lọdun to n bọ.

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.