Ọkọ mi lo pa awọn ọmọ mi, mi o fẹ ẹ mọ- Iyabọ

Spread the love

Iriri aye gbaa ni ọrọ awọn lọkọ-laya kan, Iyabọ Akibọni ati ọkọ rẹ, Ọla Akinbọni, jẹ fun awọn ero to wa ni kootu kọkọ-kọkọ to wa ni Agege, niluu Eko, nitori ṣe ni iyawo n naka si ọkọ rẹ pe oun lo wo sunsun, to si pa meji ninu awọn ọmọ toun bi fun un.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, ni Iyabọ, ẹni ogoji ọdun, lọ kootu Agege, o loun fẹẹ kọ ọkọ ọun toun fẹ lọdun mejilelogun sẹyin silẹ.

Obinrin naa ṣalaye pe loootọ, ọkọ oun ni Ọla, ṣugbọn awọn ko ṣegbeyawo kankan. Ọdun 1996 ni awọn mejeeji fẹra wọn. Nnkan mẹta pataki ni Iyabọ sọ pe o fa a ti oun fi fẹẹ kọ Ọla silẹ. Akọkọ, o loun ko nifẹẹ rẹ mọ, ẹlẹẹkeji, o ni oninufufu eeyan ni, ki i pẹẹ binu, ẹlẹkẹẹta si ni pe o lu oun lọmọ pa.

Ẹsun kẹta naa lo ka gbogbo ero kootu lara, gbogbo eeyan fẹẹ gbọ idi ti baba ọmọ yoo fi wo sunsun, ti yoo si fi lu ọmọ bibi inu rẹ pa.

Iyabọ ṣalaye fun kootu pe irọlẹ ọjọ kan ni ọkọ oun ṣadeede wọle, to si sọ fun oun pe oun ti niyawo tuntun, ki oun yaa ko ẹru oun kuro nile dandan.

Ọrọ yii ni obinrin naa lo fa wahala nla lọjọ naa, ti ọmọ oun si woju baba rẹ pe iru ọrọ wo lo n ba iya oun sọ yẹn. Ibinu ọrọ ti ọmọbinrin naa sọ lo ni baba rẹ fi lu u, to si daku mọ ọn lọwọ. Fun bi wakati mẹrin lo ni ọmọ naa ko mira, nigba ti awọn aa si fi gbe e de ọsibitu, awọn dokita lọmọ naa ti ku.

Iyabọ ni iṣẹlẹ yii lo mu oun kuro lọdọ rẹ ninu oṣu kejila, ọdun 2017. O ni loru ọjọ kan ni ọmọ oun kan to n gbe lọdọ Ọla pe oun lori foonu pe ara oun ko ya. Ko si pẹ sigba naa ti ọmọ naa tun pe oun pada pe baba oun ti fi nnkan kan ti oun o mọ pa oun lara, latigba naa lara oun ko si ti balẹ mọ. O ni aarọ ọjọ keji loun lọ si ile Ọla, toun si gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu, ṣugbọn ibẹ lọmọ yii tun pada dakẹ si.

Obinrin naa sọ pe inu oṣu karun-un, ọdun yii, loun ko awọn ọmọ meji to ku kuro lọdọ rẹ, ko ma tun pa wọn, latigba naa ni wọn si ti n gbe lọdọ oun.

Ọla ti iyawo rẹ fẹsun kan naa wa ni kootu. Ọkunrin to ni ẹni aadọta ọdun yii ni latigba ti ọmọ akọkọ ti ku mọ Iyabọ lọwọ loun naa ti n wa ọna toun fi maa kọ ọ silẹ, ṣugbọn ti awọn eeyan kan tun n parọwa soun.

Ọla ni oun ka iyawo oun mọ otẹẹli pẹlu ale rẹ kan to n ṣiṣẹ ọlọpaa nibi ti wọn ti n jọ n mu ọti. O ni ni gbogbo asiko yii, iṣẹ alubọsa tita lo n ṣe, ko si si nnkan to yẹ ko gbe e de otẹẹli rara. Ọkunrin naa ni lẹyin eyi, baba ṣọọṣi ti iyawo oun n lọ tun n yan an lale, koda, aago mọkanla alẹ lo maa n wọle.

O ni ni tọmọ to ku, iwa arifin lọmọ naa hu si oun toun fi ba a wi, niṣe loun gba a lẹnu. O ni iyalẹnu lo jẹ pe ọmọ yẹn daku, ki awọn si too gbe e de ọsibitu, wọn lọmọ naa ti ku.

Ọla ni loootọ, oun ko tete sọ fun iyawo oun pe ọmọ awọn ku, nitori oun ko fẹ ko ba ara jẹ, oun si pe ọkan ninu awọn aburo rẹ pe oun fẹẹ sin ọmọ naa, ṣugbọn ko si ẹni to yọju soun. O ni funra oun loun sin ọmọ naa, o ni irọ ni, oun ko fi ọmọ naa ṣe nnkan kan. Ọkunrin naa loun faramọ ki wọn tu igbeyawo awọn ka.

Adajọ Patricia Adeyanju ni o ṣe ni laaanu pe awọn mejeeji padanu ọmọ wọn, pe o ṣee ṣe ti wọn ba wa nirẹẹpọ, ọmọ wọn le ma ku. O ni ile-ẹjọ naa aa gbiyanju lati ba wọn wo o, boya wọn le ri atunṣe si aarin wọn. Ọjọ kẹtala, oṣu yii, lo ni ki wọn pada wa si kootu, pẹlu ẹlẹrii meji meji.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.