Ọkọ mi fẹẹ fi mi ṣoogun owo, ẹẹmẹta lo ti fa irun abẹ mi-Bọsẹ

Spread the love

Ifẹ ọdun mọkanla to seso ọmọ meji laarin obinrin kan, Bọsẹ Ọladepo, ati ọkọ ẹ, Ọladapọ Ọladepo, ti n lọ sopin bayii. Iyawo ti mu ẹjọ ọkọ ẹ lọ si kootu ibilẹ to wa ni Agbẹlọba, niluu Abẹokuta. O ni ki wọn tu oun ati Ọladapọ ka, nitori ọkunrin naa fẹẹ foun ṣoogun owo.

Abilekọ Bọsẹ Ọladepo ṣalaye pe irun abẹ oun lọkọ oun maa n fa nigba toun ba sun, o ni ẹẹmẹta lo ti fa kinni ọhun lasiko toun sun lọ. Nigba toun ji loun ri i pe gbogbo irun to wa ni sẹnta igboro oun lo ti poora pata, bẹẹ,oun ko sun ti ẹlomi-in ju Ọladapọ toun bimọ meji fun yii naa lọ.

Obinrin yii fi kun un pe oun loun kọle toun atọkọ oun yii n gbe, ṣugbọn pẹlu ẹ naa, awọn iwa ti ko fi ifẹ han rara ni Ọladapọ  maa n hu soun ninu ile, ki i ro tawọn ọmọ meji toun bi fun un.

‘’Ki i fun emi atawọn ọmọ wa lowo ounjẹ, gbogbo ojuṣe ẹ gẹgẹ bii baba lo kọ silẹ, emi ni mo n ṣe e. Sibẹ naa, Ọladapọ tun maa n ba mi ja ninu ile to jẹ emi ni mo kọ ọ funra mi ni. Nigba to dẹ ti ba a debi ko maa fa irun abẹ mi bayii, mi o fẹ ẹ mọ.

‘Ẹẹmẹta lo ti fa irun abẹ mi, mo mọ pe oogun owo lo fẹẹ fi mi ṣe lo jẹ ki n tete mu ẹjọ ẹ wa si kootu pe ki ẹ tu wa ka.’ Bẹẹ ni Bọsẹ wi.

Nigba to n dahun si ẹsun tiyawo ẹ fi kan an, Ọgbẹni Ọladapọ sọ pe oun faramọ ikọsilẹ ti obinrin naa n fẹ, irọ to n pa mọ oun loju gbogbo aye yii nikan loun ko nifẹẹ si. O ni ki kootu tu igbeyawo naa ka, ki wọn si kilọ fun Bọsẹ ko yee parọ mọ oun.

Aarẹ J.A. O Ṣofọlahan to gbọ ẹjọ naa ni ki wọn pada lọ sile, ki wọn jẹ kawọn famili ba wọn da si i na ki wọn too pada si kootu.

(56)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.