Okada ni Ayomide fi n ja baagi ati foonu gba l’Akure

Spread the love

Ọmọkunrin kan, Adeniyi Ayọmide lo ti wa latimọle awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo nibi to ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, ṣalaye fun akọroyin wa pe iṣẹ kan ṣoṣo ti Ayọmide fẹran ju ni ko maa fi ọkada ja baagi pẹlu foonu awọn eeyan gba laarin igboro ilu Akurẹ ko too di pe o ṣe eyi tọwọ awọn ọlọpaa fi pada tẹ ẹ lọṣẹ to kọja yii.

Gẹgẹ bi iṣe ẹ, ọmọbinrin kan torukọ rẹ n jẹ Ọluwatubọsun Tosin  logboju ole ọlọkada naa tun kọlu ni agbegbe Ariṣọyin, niluu Akurẹ, logunjọ, oṣu to kọja yii, to si ja foonu rẹ gba, lẹyin eyi lo sa lọ.

Ni kete tawọn ọlọpaa ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti bẹrẹ si i ṣọ ọ, ti wọn si ri i mu lọṣe to kọja yii.

Ibọn ilewọ kan pẹlu ọta ninu rẹ, ibọn iṣere kan ati ọkada kan ti ko ti i ni nọmba ni Fẹmi Joseph sọ pe wọn ba nile ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun naa.

Nigba to n ṣalaye ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an, afurasi naa jẹwọ pe loootọ loun maa n ja awọn eeyan lole foonu ati awọn nnkan mi-in toun ba le ja gba lọwọ wọn.

Ọmọkunrin to pera rẹ lọmọ bibi ilu Akurẹ naa ni o ti pẹ diẹ toun ti wa lẹnu iṣẹ ole jija ko too di pe oun ṣe eyi to yi oun lọwọ lọsẹ to kọja yii.

Ọ ni loootọ loun n jale, ṣugbọn ko ti i ṣẹni toun gbẹmi lẹnu ẹ latigba toun ti n ja a.

 

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.