Ọjọ wo lawọn gomina ilẹ Yoruba fẹẹ ṣepade tiwọn

Spread the love

kan ati ọrọ kan, wọn ni awọn ko ni ilẹ ti awọn fẹẹ fun ijọba Buhari lati ko awọn Fulani onimaaluu si, wọn ni bi ẹnikẹni ba sọ pe awọn ti fun wọn nilẹ, tabi ipinlẹ kankan ni ilẹ Ibo ni ilẹ ti yoo fun awọn eeyan naa, ki gbogbo wọn ti mọ pe irọ ni. Wọn lawọn ko nilẹ, awọn ko si ni i fun Fulani onimaaluu kan nilẹ laduugbo awọn. Pọn-un la a ṣẹfọn, bi yoo ṣẹjẹ ko ṣẹjẹ, bi yoo si ṣomi ko ṣomi. Ohun ti eeyan ko ba ni i gba, ẹnu rẹ ni yoo fi sọ pe oun ko ni i gba a. Eyi ti awọn gomina ilẹ Ibo ṣe yii, wọn ti fi kilọ fun ijọba apapọ, wọn si ti fọ ile irọ ti wọn n kọ kiri. Ko si minisita kan tabi ẹni kan ti yoo lọ si ilẹ Ibo ti yoo ni oun fẹẹ gba ilẹ wọn fun iṣẹ maaluu, tabi fun awọn Fulani. Bi gbogbo gomina ba ko ara wọn jọ ti wọn ba ṣe eleyii, ohun yoowu to jẹ aburu to wa lọkan awọn eeyan yii ko ni i ṣee ṣe. Iyẹn leeyan ṣe gbọdọ beere pe nijọ wo lawọn gomina ilẹ Yoruba fẹẹ ṣe ipade tiwọn o, nijọ wo ni wọn fẹẹ kede fun gbogbo aye pe awọn ko fẹ abule Fulani nilẹ Yoruba. Bi wọn ba wa ni kọrọ, wọn yoo maa leri, wọn yoo maa halẹ, pe ko sẹni ti yoo gbe abule Fulani fawọn ti awọn yoo gba a, ṣugbọn bi wọn ba de ọdọ Buhari ati awọn eeyan rẹ, ọtọ pata ni ohun ti wọn yoo sọ. Bi ọrọ ati iwa wọn ba da wọn loju, kawọn naa bọ si gbangba ki wọn sọ fun gbogbo aye pe awọn gomina ilẹ Yoruba ko ni i gba abule maaluu, tabi ilu awọn Fulani laaye lọdọ tawọn naa. Ki wọn jade ki wọn tete sọ bayii o, ki gbogbo aye le mọ ibi ti wọn n lọ. Ṣugbọn yoo ṣoro fun wọn lati waa sọ. Ijẹkujẹ ko ni i jẹ, ọtẹ ko ni i jẹ, ojo ko ni i jẹ, jinjin-aara-ẹni-lẹsẹ ko ni i jẹ, awọn mi-in ti yoo fẹẹ sọ ara wọn di Fulani nitori ijẹkujẹ ko si ni i fẹẹ jẹ ko ṣee ṣe. Ṣugbọn gomina Yoruba to ba ta Yoruba fun Fulani, Ọlọrun yoo mu un, awọn ti wọn ni ilẹ Yoruba paapaa yoo si mu un!

(68)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.