Ọjọ meje lawọn ajinigbe ko fi fun mi lounjẹ–Taiwo Davies

Spread the love

Lati ọgọta ọdun sẹyin ti wọn ti bi Alagba Taiwo Davies, o daju pe baba naa ko ti i ri iru ibẹru ati wahala to ko si lọdọ awọn ajinigbe ti wọn ṣe e nijamba fun ọjọ meje gbako lori oke kan ninu igbo kijikiji, laarin ipinlẹ Ekiti si Ondo.

Lọsẹ to kọja lọmọ bibi Ilogbo-Ekiti, nijọba ibilẹ Ido-Osi, naa ba wa sọrọ lori nnkan toju rẹ ri lọdọ awọn apanilẹkun-jaye ti Ọlọrun ko jẹ ki wọn gbẹmi rẹ ọhun. Iṣẹlẹ yii ko yatọ si iṣẹ iyanu rara nitori oju rẹ ri mabo ninu igbo aginju ti wọn mu oun ati pasitọ kan nigbekun si.

Gẹgẹ bi oṣiṣẹ-fẹyinti ileeṣẹ Nigeria Export Promotion Council tẹlẹ naa ṣe sọ, o ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla to kọja yii, niṣẹlẹ manigbagbe naa waye loju ọna Ikẹrẹ, nipinlẹ Ekiti si Iju, nipinlẹ Ondo, lasiko toun n wa ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes Benz 180 oun lọ jẹẹjẹ.

‘’ Ilu Akurẹ ni mo n lọ lọjọ yẹn lati Ado-Ekiti ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ. Bi mo ṣe kọja lọdọ awọn ọlọpaa ti wọn wa lẹnu ibode Ekiti si Ondo lawọn marun-un kan ti wọn di ihamọra pẹlu ibọn AK47, Pump Action atawọn ibọn mi-in deede bẹ si titi, ni wọn ba da ọkọ Toyota Camry to wa niwaju mi duro.

‘’Ko si bi ẹnikẹni ṣe le sare nibẹ yẹn nitori ọju ọna ko daa, iyẹn lo jẹ ko rọrun fun wọn lati ko wa ni papamọra. Wọn na ibọn sawa ta a wa ninu mọto mejeeji, ṣugbọn ẹni kan pere ni wọn wọ sọkalẹ ninu mọto keji, wọn ni kawọn to ku maa lọ. Wọn wọ emi naa silẹ, wọn fọ foonu mi mọlẹ, ni wọn ba mu emi ati ọkunrin keji ti mo pada mọ bii pasitọ wọ igbo lọ.’’

Alagba Taiwo ni inu oko koko kan ni wọn kọkọ mu awọn wọ, niṣe lawọn si rin lati asiko naa di nnkan bii aago mẹrin aabọ idaji ọjọ keji ti wọn ni kawọn gun apata kan. O ni ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ naa ti i ṣe Satide lawọn sọ kalẹ lori oke yii, nirin-ajo mi-in ba tun bẹrẹ, eyi to gba gbogbo oru ọjọ naa di Sannde.

Lọjọ Sannde yii ni baba naa ri nnkan kan ti ko ni i kuro lọkan rẹ titi laelae, iyẹn naa si ni oku ọkunrin ati obinrin kan to ti n jẹra. Ṣugbọn ṣe lawọn ajinigbe naa to pe ni Fulani ko tiẹ bikita, ibẹ si ni ibẹru-bojo ti da bo o, o waa daju wayi pe ẹruuku gidi lawọn eeyan naa.

O tẹsiwaju pe, ‘’Aarọ ọjọ Mọnde la de ibi ti wọn n ko wa lọ gan-an lori oke kan bayii. Ni gbogbo asiko yẹn, wọn ko fun wa lounjẹ, iya to si jẹ wa ko kere rara. Lọjọ yẹn ni wọn waa beere nọmba ẹni ti mo mọ pe o le gba mi silẹ. Ọlọrun lo jẹ ki n mọ nọmba iyawo mi sori, boya ibẹ ni wọn iba ti yinbọn pa mi.

‘’Ọkan ninu wọn pe iyawo mi, o ni ajinigbe lawọn, ọgbọn miliọnu (30, 000, 000), lawọn si fẹẹ gba. Mo sọ fun wọn pe oṣiṣẹ-fẹyinti ni mi lẹyin tiyawo mi sọ pe ko sowo lọwọ oun, ko si sibi ta a ti le ri iru owo bẹẹ nipinlẹ Ekiti. Wọn ni iyẹn ko kan awọn, ṣe lawọn mọlẹbi gbaruku ti awọn tawọn gbe ni Port Harcourt, Enugu atawọn ibomi-in, kawọn eeyan tiwa naa ṣe bẹẹ.

‘’Nigba ti wọn pe iyawo mi lọjọ Wẹsidee, o jọ pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (100,000), Naira to loun le fun wọn lo bi wọn ninu ti wọn fi bẹrẹ si i ṣa mi ladaa, eyi ni wọn fi da awọn ọgbẹ oriṣiiriṣii si mi lara.

‘’Aburo mi, Idowu, lo pe wọn lọjọ Tọsidee pe ẹbi ti ri ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000) Naira, igba yẹn ni wọn waa sọ pe awọn maa din owo yẹn lati ọgbọn miliọnu si miliọnu kan aabọ (1, 500, 000). Idowu tun pe laaarọ kutu ọjọ keji pe awọn ti ri ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800,000), Naira, lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ni wọn sọ pe miliọnu kan lawọn maa gba jalẹ, ko lọọ wa ẹgbẹrun lọna igba (200,00), si i.

‘’Ọjọ Furaidee yẹn ni wọn yinbọn fun mi lẹsẹ, wọn ni awọn mọlẹbi mi n fasiko awọn ṣofo, ki wọn le mọ pe awọn ṣetan lati pa mi.’’

Aarọ ọjọ naa lo ni awọn ajinigbe yii ni ki Idowu wa si Ikẹrẹ Ekiti, nigba to sọ pe Ado-Ekiti loun wa, lẹyin iyẹn ni wọn ni ko maa bọ ni Iju, wọn si juwe ibi to maa duro si. Ibẹ lo ti pade iyawo pasitọ toun naa gbe owo wa.

Nibi ti wọn duro si lẹnikan ti gbe ọkada ti ko ni nọmba waa ba wọn, oun lo si juwe ọna igbo kan fun wọn. Lẹyin irin bii wakati meji lo ni awọn ajinigbe naa deede ni ki awọn duro, lawọn mẹta ba yọ si wọn, wọn si da ibọn bolẹ. Nigba ti wọn ko ri ẹnikankan ko yinbọn pada ni wọn gba owo, ti wọn si ka a, igba yẹn ni wọn waa pe awọn meji to ku pe ki wọn fi awọn silẹ.

‘’Awọn meji to ku yẹn tẹle wa, ni nnkan bii aago mejila ọsan la de ibi ti aburo mi atiyawo pasitọ wa, ni irin-ajo mi-in ba bẹrẹ fawa mẹrẹẹrin. Nnkan bii aago mẹsan-an alẹ la de orita Iju.

‘’Ni gbogbo ọjọ ta a lo ninu igbekun, omi to n sun nibi apata yẹn nikan ni wọn jẹ ka mu fun ọjọ meje yẹn, wọn ko fun wa lounjẹ, bẹẹ obinrin kan to n jẹ Funkẹ lati Iju maa n se ounjẹ fun wọn ti wọn maa n lọọ gbe wa. Irẹsi lẹni yẹn maa n saaba se, oju wa naa ni wọn ti maa jẹ ẹ.

‘’Mo dupẹ lọwọ Ọlorun… mi o mọ pe mo maa la a ja rara. Ha, iriri ibẹru gbaa ni.’’

A gbọ pe ọga ọlọpaa Iju tete gbe mọto Alagba Taiwo pada fun un lẹyin to gbọ nnkan toju rẹ ri ninu igbo ọdaju ti wọn gbe e lọ, bẹẹ ni baba naa lo ọsẹ meji gbako nileewosan aladaani kan l’Ado-Ekiti. Bo tilẹ jẹ pe mọlẹbi naa ko ri iranlọwọ kankan gba lasiko idaamu ọhun, ọkan ọpẹ ni wọn n lo igbesi-aye wọn lojoojumọ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph, sọ pe awọn ọlọpaa ti ya bo gbogbo inu igbo yii, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lọsan-an loru lati dawọ iṣẹ ibi awọn ajinigbe duro lagbegbe Iju, Ita Ogbolu, Akoko, Ọrẹ, Ọwọ atawọn agbegbe mi-in. Bakan naa ni ojugba rẹ nipinlẹ Ekiti, Caleb Ikechukwu, fi kun un pe igbo Ikẹrẹ tiṣẹlẹ naa ti waye lo gun de Ẹfọn Alaaye tiṣẹlẹ ijinigbe ti waye lẹnu ọjọ mẹta yii, nibi tawọn kan ti padanu ẹmi wọn, awọn si ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa Ondo.

Iwadii ALAROYE fi han pe ọkan awọn to n gba oju popo Ikẹrẹ si Akurẹ atawọn to n rin irin-ajo gba Itawurẹ ati Ẹfọn Alaaye ko balẹ mọ lasiko yii, paapaa bi ọdun ṣe n sun mọle. Eyi lo jẹ kawọn ọlọpaa maa kede pe kawọn araalu ran awọn lọwọ nitori iṣẹ awọn yoo rọrun ti wọn ba le maa ta awọn lolobo lori awọn nnkan ajoji ati iṣẹlẹ abami to ba n waye lawọn agbegbe wọnyi.

 

 

 

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.