Ọjọ lọjọ naa niluu Eko, Lọjọ ti Fẹla ṣe ohun Tẹni kan ko ṣe ri

Spread the love

Ohun to fi ọkan awọn eeyan balẹ lọjọ ti Fẹla loun yoo fẹ iyawo mẹtadinlọgbọn lẹẹkan ni pe nigba ti wọn de otẹẹli Parrisona, ni Anthony Village, lọna Ikorodu, awọn naa ri i pe ipalẹmọ ti lọ rẹpẹtẹ loootọ. Loootọ wọn ko to aga sinu gbọngan nla naa bii pe ṣọọṣi ni wọn wa, tabi ki wọn ṣe e bii ti ile-ẹjọ, nibi ti wọn ti n ṣeyawo alarede, ṣugbọn awọn eto ibilẹ kan ti wa to fi han pe loootọ igbeyawo yoo waye, o kan jẹ ọna ti Fẹla yoo gbe kinni naa gba lo n jọ wọn loju, awọn ti wọn mọ nipa aṣa ati eto ibilẹ nikan lọrọ naa ye diẹ, wọn ni igbeyawo eleyii yatọ si tawọn oniṣọọṣi, bẹẹ ni ki i ṣe tawọn onikootu, tiwa-n-tiwa ni. Fẹla naa ko fi kinni naa bo pe ohun ti oun fẹẹ ṣe niyi, nitori naa ni ko si ṣe pe awọn alufaa ijọ kankan sibẹ, ko si si awọn ti wọn wọ aṣọ adajọ tabi ti lọọya ti wọn yoo ṣe ibura kan fẹnikan, tiwa-n-tiwa ni kinni naa lati ibẹrẹ dopin.
Ni gbangba gbọngan nla ti igbeyawo naa yoo ti waye ni wọn tẹ ẹni oore mẹfa si, ẹni ibilẹ ni wọn n pe bẹẹ, ẹni yii si fihan pe awọn iyawo naa ko ni i jokoo sori ṣia, ori ẹni ni wọn yoo wa, awọn pẹlu ọkọ wọn ti wọn yoo fi ṣe eto igbeyawo naa lọna ti ibilẹ. Lori ẹni yii ni wọn ti to awọn eelo si, eelo iwure, iyẹn awọn ohun ti wọn yoo fi ṣe adura igbeyawo. Akọkọ to wa nibẹ ni ṣuga, wọn ti tu awọn ṣuga naa sinu awo, ohun ti wọn si fẹẹ fi kinni naa ṣe ko le ye awọn ọgbẹri, awo nikan lo ye. Lẹyin ṣuga yii, wọn tun gbe awo funfun mi-in sibẹ to jẹ orogbo ni wọn ko sibẹ, orogbo naa si jẹ awọn orogbo to tobi daadaa. Awo funfun mi-in tun wa nibẹ, obi ni wọn ko sinu iyẹn naa, awọn obi to ti gbo ni. Lẹyin eyi ni awo goodo mi-in tun wa lori ẹni yii, oyin lo wa ninu rẹ, oyin igan to jẹ ogidi ni.
Ki i ṣe awọn nnkan wọnyi nikan lo wa nibẹ o, wọn tun gbe awo mi-in sibẹ to jẹ aadun ni wọn bu sinu rẹ, aadun naa si pọ rẹpẹtẹ ninu awo. Ẹyin eyi ni wọn to ireke nla nla jọ sibẹ, ireke naa si n lọ si bii idi marun-un, bii mẹjọ mẹjọ lo si wa ninu idi kọọkan. Gbogbo eleyii ni wọn ko kalẹ, wọn si fi akeregbe ogurọ kan ti i lẹgbẹẹ, ogurọ wa ninu rẹ to n ru itọ funfun jade lẹnu, o si jọ pe eroja igbeyawo naa ti pe. Gbogbo eyi ti wọn ṣe yii, iwaju ọpọn Ifa ni wọn ko wọn si o, ṣe ọpọn Ifa naa ti wa nibẹ, wọn bu iyerosun sori rẹ, bẹẹ ni wọn gbe ọpẹlẹ ti i lẹgbẹẹ, iwaju Ifa yii si ni awọn eelo gbogbo yii wa. Bi ẹnikẹni ba ti wọle, ohun ti yoo kọkọ ri niyẹn, eleyii si jẹ ki awọn eeyan mọ pe nnkan kan yoo ṣẹlẹ loootọ. Wọn mọ pe bi Fẹla ba ti pinnu nnkan kan, afi to ba ṣe e, wọn mọ pe bo ti loun fẹẹ ṣegbeyawo yẹn, yoo ṣe e, ọna ti yoo gba ṣe e ni ko ye wọn.
Amọ gbogbo ẹni to ba wọle naa lo ti ri i bi yoo ti ṣe e, o ti fihan gbogbo aye pe ọna ibilẹ ni igbeyawo toun, ati pe babalawo ni yoo dari eto naa, ko ju bẹẹ lọ. Ni bii aago mejila ni babalawo ti yoo dari eto naa waa jokoo siwaju Ọpọn-Ifa rẹ, iyẹn Oloye Yesufu Ọlalẹyẹ to ti Ekan Ekiti wa, ṣe oun ni aṣoju Ọrunmila ti yoo dari ayẹyẹ igbeyawo naa. Oun nikan kọ lo jokoo, o tun mu babalawo mi-in lẹyin ti wọn yoo jọ ṣeto naa, ti yoo si maa ran an lọwọ bi ọrọ ba di ka ki ẹsẹ Ifa to rọ mọ eto ti wọn n ṣe. Lati ilu Iwo ni babalawo keji yii ti wa, orukọ rẹ si ni Ọlaṣupọ Alamu. Awọn mejeeji ti jokoo, wọn si n jẹnu wuyẹwuyẹ fungba diẹ, ko si sẹni ti ko mọ pe wọn n juba Ifa ni, bo tilẹ jẹ pe awọn ti wọn wa nibẹ ko gbọ ohun ti wọn n sọ. Ṣugbọn nigba to jẹ bi wọn ba sọrọ diẹ, wọn yoo fori kanlẹ, ọrọ naa ti ye awọn ọmọ awo.
Boya gẹgẹ bii eto ti wọn ṣe ni, abi kinni naa ni i ṣe pẹlu ọrọ Ifa, ko sẹni to mọ, ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ ni pe ni deede aago kan geere lawọn iyawo tuntun naa bẹrẹ si i jade nikọọkan. Ẹni to kọ jade lọjọ yii ni Funmilayọ Onileere, oun ni aṣaaju awọn onijo lẹyin Fẹla, ṣugbọn oun ni wọn pe ni iyaale gbogbo wọn kaafata. Lẹyin tirẹ ni Alakẹ Adedipẹ jade. Alakẹ yii ni olori awọn agberin lẹyin Fẹla, o si da bii pe oun ni iyaale keji lọjọ naa, nitori eto ti wọn ṣe naa ni pe bi awọn obinrin naa ba ṣe ju ara wọn lọ si nile ọkọ wọn ni wọn yoo fi maa jade, iyaale agba gbọdọ mọ ara rẹ ni iyaale, iyaale kekere gbọdọ mọ pe iyaale kekere loun, ki awọn iyawo keekeekee naa si mọ ipo ara wọn. Bi ipo awọn iyawo Fẹla ṣe jẹ naa ni wọn fi n jade. Nọmba tirii, iyẹn iyaale kẹta, ti yoo jade lọjọ naa ni Oghomienor, oun naa si jokoo tepọn siwaju Ifa.
Tẹjumade Adebiyi lo jade tẹle e, oun naa si ti mọ ipo ara rẹ pe oun ni iyaale kẹrin, nọmba fọọ loun nile Fẹla. Igba ti oun ti jokoo ni iyaale karun-un jade, Ngosi Olisa, bo si ti n jokoo ni ẹni to wa ni ipo kẹfa tẹle e, iyẹn Nagite Mukoro. Oun naa jokoo tai jokoo ni nọmba siisi jade, iyaale kẹfa. Adejuwọn Williams niyẹn o. Bi Juwọn si ti jokoo naa ni ẹlomi-in tun jade, iyẹn ẹni ti yoo wa ni ipo keje, ṣugbọn ọrọ tirẹ ni ariwo diẹ ninu. Adeọla Williams ni, ẹnu si ya awọn eeyan pe bawo ni Adeọla Williams ati Adejuwọn Williams yoo ṣe jade tẹle ara wọn, ṣe ọmọ baba kan naa ni wọn ni, nigba to jẹ orukọ baba kan naa lawọn mejeeji jọ n jẹ. Eleyii lo pada waa di ariwo, nitori awọn eeyan ko duro beere alaye mọ, ohun ti wọn n sọ ni pe ọmọ baba meji wa ninu awọn iyawo ti Fẹla ṣẹṣẹ fẹ, wọn ni awọn foju awọn ri wọn: awọn ọmọ Williams.
Ẹni to jade ṣikẹjọ wọn lọjọ nla yii ni Fẹhintọla Kayọde, oun naa si rẹrin-in sawọn eeyan, o juwọ si wọn pe oun ni iyaale kẹjọ nile Fẹla. Lẹyin tirẹ ni nọmba nain jade, ipo kẹsan-an ni Ihasuyi Obpotu wa nile ọkọ. Bo ti n jokoo ni ipo kẹwaa tọ ọ lẹyin, Emawaghewo Osawe ni nọmba tẹẹni. Lẹyin tirẹ ni Bọsẹ James jade, awọn eeyan ti wọn wa nibẹ ko si jẹ kẹnikẹni sọ fun wọn ti wọn fi pariwo nọmba ẹlẹmin, wọn ni oun ni iyaale kọkanla lọdọ Fẹla ọkunrin ogun. Bo ti jokoo pẹsẹ niwaju Ifa bayii ni iyawo tirẹ naa jade sita, Kikẹlọmọ Oseni ni nọmba tuẹẹfu. Adunni Idowu ni nọmba tatin, ipo kẹtala loun wa, tidunnu-tidunnu lo si fi jokoo siwaju Ọpọn-Ifa. Afi bii igba ti wọn i ba maa korin, “Oni lọjọ ayọ rẹ ..” fawọn oniyawo ode-oni ni Ọlaide Babayale ba wọle, pẹlu idunnu ni, ṣe oun ni iyaale kẹrinla.
Awọn mẹrinla yii ni wọn jokoo siwaju, ohun ti eyi si tumọ si ni pe awọn mẹrẹẹrinla yii ni iyaale, bi wọn si ṣe tẹle ara wọn ni wọn fi ni ọwọ laarin ara wọn. Nigba ti awọn to ku bẹrẹ si i de, ẹyin wọn ni wọn n to si, wọn n to si ẹyin wọn nikọọkan ni. Iyawo lawọn. Iyawo akọkọ to wọle ni Tokunbọ Ṣolẹyẹ, loootọ oun ni nọmba fiftin to wa ni ipo kẹẹẹdogun, sibẹ o mọ pe oun naa ki i ṣe ẹgbẹ awọn kan. Bi oun ti n jokoo ni nọmba sistin, ẹni to wa ni ipo kẹrindinlogun jade sita, ọmọge Ibe Agwu, oun naa si jokoo sẹgbẹẹ iyaale rẹ. Iyawo kẹtadinlogun to bọ sita lẹyin ẹ ni Orode Olowu, bo si ti n jokoo ni Iyabo Chibueze bọ sita pẹlu ẹrin, oun ni nọmba eetin, ipo kejidinlogun lo wa. Ọjọ ayọ lọjọ naa, nitori ẹrin ni Ọmọwunmi Aferume ba wọle, ko tilẹ wo ẹyin rara pe ipo kọkandinlogun loun wa, nọmba naitin, o n rẹrin-in idunnu ni tirẹ ni.
Ọmọlara Ṣosanya ni nọmba tuẹnti, ipo ogun to si wa nile ọkọ yii dun mọ ọn debii pe o n bẹyin kẹẹ ni. Bẹẹ ni Kevwe Ogene to wa nipo kọkanlelogun, nọmba tuẹnti-waanu, ọjọ ayọ nla lọjọ naa jẹ fun un. Koda, Olurẹmi Akinsanya to wa ni ipo kejilelogun naa n rẹrin-in ayọ ni o, o ni ko si ohun to fi n ṣeeyan, ọjọ igbeyawo oun ree, ọjọ alarinrin ni. Ohun tawọn eeyan ti gbọ tẹlẹ ni pe iyawo mẹtadinlọgbọn ni Fẹla fẹẹ fẹ lẹẹkan, nigba ti wọn si ka awọn iyawo naa debii mejilelogun ti wọn ko ti i ri awọn to ku, wọn n wo o pe abi ki i ṣe bẹẹ ni, abi ko sawọn iyawo mọ lọdọ Fẹla ni, abi awọn iyawo ti sa lọ ni, bo si tilẹ jẹ pe awọn eeyan ko sọ ọ sita, wọn bẹrẹ si i kun seti ara wọn, wọn n fi to ara wọn leti pe awọn iyawo yii ko ma pe mẹtadinlọgbọn, ewo waa ni ariwo ti Fẹla n pa si gbogbo ilu leti pe mẹtadinlọgbọn niyawo oun.
Awọn miiran ko wo iyẹn rara o, wọn ni ẹni to se ọbẹ atẹ, wọn ni ki oriṣa pa a, ẹni ti ko sebẹ rara nkọ! Wọn ni ọga nla ni Iya Muda, ọmọ ẹlomi-in ni ko le mu ọbẹ rara. Wọn ni ọkunrin meloo lo le fẹ iyawo meji, ka ma ti i sọ mẹta, ka ma waa ti i sọ mejilelogun, wọn ni bo ba jẹ iye to fẹ naa ree, ọkunrin ju ọkunrin lọ ni. Ṣugbọn nibi ti wọn ti n fa ọrọ naa mọ ara wọn lọwọ ni awọn marun-un to ku sare wọle de, o da bii pe wọn pẹ ki wọn too mura tan ni. Bo tilẹ jẹ pe wọn wọle pọ naa ni, sibẹ, niṣe ni wọn tẹle ara wọn. Ẹni akọkọ to kọkọ wọle ni Dupẹ Oloye, ipo kẹtalelogun loun wa nile Fẹla, ẹni to si tẹle e ni Fọlakẹ Orosun ti oun wa ni ipo kẹrinlelogun. Ọmọwumi Oyedele naa wa nibẹ, nọmba tuẹnti-faifu, ipo kẹẹẹdọgbọn naa ko si han loju rẹ, inu rẹ dun wọle ni. Chinyere Ibe ni nọmba tuẹnti-siisi, ipo kẹrindinlọgbọn ni.
Iyawo kekere patapata, iyawo lọọdẹ ọkọ rẹ ni Idiat Kasumu. Oun lo gbẹyin, oun naa lo si kere ju, ọmọde si tun ni pẹlu, yoo gbadun ọkọ rẹ daadaa. Bayii ni gbogbo wọn jokoo pẹrẹmu, bi wọn si ti jokoo ti wọn n wo raaraa ni ọkọ iyawo naa de, ariwo si ta gee nigba ti Fẹla wọle de, oun si jokoo, o dojukọ awọn iyawo rẹ ni deede aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹwaa, babalawo si bẹrẹ etutu, igbeyawo Fẹla bẹrẹ pẹrẹwu.
Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

(57)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.