Ọjo keji ti were ṣa Abiọdun ọlọpaa pa niyawo ẹ bimọ

Spread the love

Ọmọtẹyinṣe Abiọdun jẹ ọkan lara awọn ọlọpaa ti were kan ti wọn n pe ni At all At all ṣa pa labule Onipẹtẹẹsi, niluu Ondo, lọsẹ to kọja.
Ọsẹ to kọja ni wọn sinku ọkunrin naa si ilu Erinjẹ, nijọba ibilẹ Okitipupa, nipinlẹ Ondo. Aarọ ọjọ keji ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ niroyin gba ilu kan pe iyawo Abiọdun ti bimọ. Awọn ọlọpaa kan sọ fun wa pe nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, wọn ko sọ fun obinrin naa pe ọkọ rẹ wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ibanujẹ naa rin. Ṣe awọn ọlọpaa meji mi-in, iyẹn Tosin Aminu ati Niyi Olotu, ni wọn ṣi n gba itọju lọwọ ni ọsibitu kan niluu Ondo, nitori ọkunrin naa ṣa wọn lapa.
Ọjọ kẹta lẹyin ti iyawo Abiọdun bimọ ni wọn tufọ iku ọkọ rẹ fun un. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii ni wọn sinku ọlọpaa naa, niṣe ni ẹkun si n pe ẹkun ran niṣẹ nibi isinku yii.
Ṣugbọn iyawo Abiọdun ko le wa sibi isinku naa, wọn lo wa lọdọ awọn obi rẹ niluu Ikarẹ, nibi to ti n ṣe ọlọjọjọ ọmọ.
Ọna ẹyẹ ni awọn ọlọpaa yii fi sinku Abiọdun, nitori niṣe ni wọn yinbọn soke lati fi ki akọni naa pe o digbooṣe, ko si pẹ rara ti wọn fi gbe oku rẹ sinu koto.
Ọkan ninu awọn ọlọpaa to ba wa sọrọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri sọ fun wa pe awọn ọlọpaa lo tun da owo jọ fun itọju awọn ẹgbẹ wọn to wa lọsibitu, o ni ijọba ko ri tiwọn ro rara. Koda, o ṣalaye pe funra awọn lawọn dawo posi tawọn fi sinku Abiọdun.
Nigba ta a bi i leere bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ, o ni ọlọdẹ ori lọkunrin naa, o juwe rẹ bii anjannu, nitori ko si ibọn ti awọn yin lu u to ran an. O ni ọrẹ ọkunrin were naa torukọ rẹ n jẹ Ajaka nikan lo le sun mọ ọn.
O ni ọrẹ rẹ yii lo fi ọgbọn gba ada lọwọ rẹ, to si mu un silẹ fun awọn ọdọ ti wọn waa fi okun de e. Lẹsẹkẹsẹ lo ni wọn gbe e lọ si olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ, ṣugbọn o ni irọlẹ ọjọ naa ni At all At all ku si teṣan awọn ọlọpaa.
Ṣa, wọn ti gbe oku were naa pamọ si mọṣuari ọsibitu awọn ọlọpaa to wa l’Akurẹ.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.