Ọjọ buruku lọjọ ti wọn pa ọkan ninu awọn tọọgi Fani-Kayọde sọna Ibadan

Spread the love

Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu Dẹmọ, Oloye Samuel Ladoke Akintọla, ati awọn ti wọn jọ wa ninu ijọba rẹ ni Western Region, gbogbo wọn pata ni wọn n binu si awọn ọlọpaa ti ọga wọn pata lati Eko fi ranṣẹ siluu Ibadan pe ki wọn waa koju awọn tọọgi awọn oloṣelu to n da ipinlẹ naa laamu. Inu wọn o dun rara pe awọn ọlọpaa kan le wa si agbegbe naa ki wọn maa waa yọ awọn lẹnu. Tẹlẹtẹlẹ, awọn ọlọpaa ibilẹ ni wọn n lo lati fi ṣe iṣẹ wọn, awọn ọlọpaa ti wọn si wa ti wọn jẹ ti ijọba apapọ yoo gbe oju wọn si ẹgbẹ kan bi wahala naa ba n lọ ni. Ṣugbọn nigba ti wahala awọn tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ pọ lati bii idaji ọdun 1964, Balewa paṣẹ ki ọga ọlọpaa ko awọn adigboluja ti ko moju ẹnikan lọ sibẹ, ki wọn si ri i pe awọn fiya jẹ tọọọgi to ba tafelefele. Eyi ko dun mọ awọn olori ẹgbẹ Dẹmọ naa ninu rara.

Loootọ, onikaluku lo ni tọọgi tirẹ ninu awọn ti wọn n ṣejọba yii, ṣugbọn ko sẹni ti tọọgi rẹ to ti ọkunrion kan ti wọn n pe ni Rẹmi Fani-Kayọde, igbakeji Akintọla. Gbogbo agbara oṣelu ti Fani ni, awọn tọọgi yii lo fun un, nitori nibikibi ti ẹ ba ti ri Fani-Kayọde ni Western Region lawọn asiko yii, oun pẹlu awọn tọọgi rẹpẹtẹ ni. Bẹẹ aye ko ti i laju to bayii rara. Bi ọkunrin naa ba n tẹle e, lanrofa mẹta ni yoo ba a rin, yatọ si kaa ti oun funra rẹ ba gbe lọ. Lanrofa kan ni yoo ṣaaju, awọn tọọgi ni yoo kun inu rẹ fọfọ. Lẹyin naa ni kaa tirẹ yoo kọja pẹlu awọn isọmọgbe tirẹ, ati ọlọpaa ẹyọ kan tabi meji, lẹyin naa ni lanrofa meji mi-in yoo tun tẹle oun, awọn tọọgi ni yoo si tun wa ninu lanrofa mejeeji. Bi Fani-Kayọde ti n rin irin rẹ nigba naa niyẹn. Bẹẹ ni ko sẹni kan to to lati ko o loju, igi ti Ṣango ba pa, apagbe ni.

Awọn ọlọpaa to ṣẹṣẹ de si West yii ni ko faaye palapala yii silẹ ṣaa o, nibikibi ti wọn ba ti ri Fani pẹlu awọn ọmọ ogun rẹ ni wọn n da wọn duro, nitori ijọba ti kilọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ ko tọọgi rin nibẹ rara. Bo ṣe waa di lọjọ kan ti wahala de niyẹn. Fani-Kayọde n ti Ile-Ifẹ bọ ni, Ibadan naa ni wọn si ti gbera lọ, wọn ni ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ n ṣe ikomọ ọmọ kan nibẹ ni, ni wọn ba lọ. Igba ti wọn n pada bọ ni bii aago mẹrinla aabọ irọlẹ ni wahala de, nitori awọn tọọgi ti Fani-Kayọde ko lọ ti ta nnkan sara, awọn iwa ti wọn si n hu bọ loju titi, iwa ta ni yoo mu mi ni, ẹnikẹni ti wọn ba ri to jẹ ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ, iyẹn AG, tabi ti wọn ṣeeṣi pade rẹ lọna, wọn yoo lu u ni ilukulu, iyẹn bi wọn ko ba pa a patapata. Eyi lo ṣe jẹ pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa, tabi awọn ti ko tilẹ ṣe oṣelu rara, ti wọn ba ti gbọ pe Fani atawọn ọmọ ogun rẹ n bọ, gbogbo wọn ni i fara soko, wọn yoo sa lọ bamubamu.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ Sannde ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ bọ si, iyẹn lọjọ karun-un, oṣu keje, ọdun 1964, ko sẹnikan to ṣaya gbangba lati duro de Fani ati awọn ọmọ rẹ, nigba ti wọn ti gbọ pe o n kọja lọ laaarọ ni wọn ti yaa sa kuro nitosi, pupọ ninu awọn oloṣelu agbegbe naa si ti gba ọna oko wọn lọ. Ṣugbọn nigba ti awọn eeyan naa yoo fi maa pada bọ, awọn ọlọpaa tuntun ti wọn ko de Ibadan ti wa loju ọna Ibadan si Ile-Ifẹ gẹgẹ bii iṣe wọn. Ohun ti wọn maa n ṣe naa ni lati yẹ awọn eeyan ti wọn ba fẹẹ wọ igboro Ibadan wo, ki wọn ri i pe wọn ko ko ohun ija oloro wọle, ki wọn si ri i pe ko si awọn tọọgi ninu awọn ti wọn n lọ. Awọn yii ti wa lọna bẹẹ, wọn si ti n yẹ awọn mọto oriṣiiriṣii to n kọja wo, bi wọn ba si ti yẹ wọn wo tan ti wọn ri i pe wọn ko ni ẹru ofin, ti ko si si awọn ti wọn fura si nibẹ, wọn yoo ni ki wọn maa lọ ni.

Afi nigba ti wọn wo ọọkan ti wọn ri awọn lanrofa ti wọn to tẹle ara wọn. Lanrofa akọkọ to yọju de ọdọ wọn, awọn ọlọpaa naa da a duro ko duro, niṣe ni dẹrẹba naa ṣe bii ẹni ti ko ri wọn. Eyi to si dun awọn ọlọpaa yii ju ni pe niṣe ni awọn ti wọn wa ninu mọto naa yọri soke, ko si ṣẹṣẹ ni awotunwo kan ninu, ẹni ba ti ri wọn yoo ti mọ pe tọọgi ni gbogbo wọn. Awọn kan mu kumọ dani, awọn mi-in mu ọbẹ ati awọn ohun ija oloro gbogbo si ọwọ wọn. Wọn o si fi pamọ pe awọn ni awọn ohun ija lọwọ, wọn na an soke bi wọn ti n kọrin ẹgbẹ Dẹmọ lọ, ati awọn orin ija mi-in ti wọn n kọ fawọn alatako wọn. Wọn ko fi bo rara pe awọn mura ija, ati pe ti ija ba de, ẹni ti awọn ba kọlu yoo fi iku ojiji ṣefa jẹ ni. Iyẹn lawọn ọlọpaa ṣe fẹẹ beere ohun to ṣẹlẹ lọwọ wọn, afi nigba ti wọn ko wa duro yii nkọ!

Awọn naa mọ ohun ti ko jẹ ki awọn duro, wọn mọ pe ko si ohun ti ọlọpaa kan yoo ṣe fawọn nigba ti Fani-Kayọde wa lẹyin awọn, wọn mọ pe ile agbara niyẹn, ibi ti agbara Western Region pin si ni. Wọn ni bi inu ba n bi awọn ọlọpaa naa ki wọn forisọlẹ ni, nitori ko si ohun ti wọn yoo fi awọn ṣe ni tawọn, baba agba lawọn n ṣiṣẹ fun, ọmọ baba alaye lawọn. Nibi tawọn ọlọpaa si ti lanukalẹ pe abi iru ẹgbin wo ree, abi iru awọn eeyan wo ree, ki lo n ṣe wọn gan-an, nibẹ naa ni kaa to gbe Fani-Kayọde funra rẹ ti kọja lọ, oun naa kọja bọn-un, ko si duro fawọn ọlọpaa naa rara. Loju tirẹ, ọlọpaa wo ni yoo wa ni Ibadan ati agbegbe rẹ ti yoo ni oun ko mọ Fani, arifin wa kọ ni yoo si jẹ ki odidi oun duro fun ọlọpaa kankan. N ni mọto tirẹ naa ba kọja lọ. Ṣugbọn o ku lanrofa meji lẹyin ẹ to n bọ, n lawọn ọlọpaa ba mura daadaa.

Orukọ ọga ọlọpaa to ko awọn ọmọ rẹ lọ soju ọna lọjọ naa ni Lasisi Ọlatubọsun, Chief Superintendent of Police, ọga ọlọpaa lo n jẹ bẹẹ. Lẹsẹkẹsẹ lo paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa oun rọ ja oju titi, ki wọn ri i pe awọn lanrofa meji to ku yẹn ko kọja. N lawọn ọlọpaa ba ṣe bẹẹ, nigba ti lanrofa naa si fi tipatipa duro, awọn ọlọpaa naa ya bo wọn ni, nitori wọn ti ri ada, ọbẹ ati kumọ pẹlu afọku igo, ati awọn ohun ija buruku mi-in lọwọ wọn. N lawọn kan ba mura ninu wọn lati ba awọn ọlọpaa ja, wọn ti gbojule e pe Fani-Kayọde yoo gba awọn. Awọn ọlọpaa naa si ti mura wọn silẹ, kondo buruku ọwọ wọn ni wọn n la mọ wọn lori, nigba ti wọn si ri i pe awọn meji ninu wọn gbe ibọn jade, ọrọ di bo o lọ o yago, awọn ọmọọta naa bẹrẹ si i sa lọ. Ṣugbọn ko too da bẹẹ, awọn bii mẹsan-an ninu wọn ti farapa gidi, kondo ọlọpaa lo se wọn leṣe.

Ọkan waa wa ninu awọn tọọgi naa ti oun gboju gan-an, bẹẹ lo laya, ọmọ Ileefẹ loun, ni agboole Ọruntọ. Latifu Makinde lorukọ rẹ gan-an, ṣugbọn oun kan naa ni wọn tun n pe ni Joseph Ajayi, eyi to ba bọ si arọwọto lo maa n lo ninu orukọ mejeeji, o jọ pe ọkan ninu awọn oruko naa wa fun iṣẹ ipanle, ekeji si wa fun ti iṣẹ ọmọluabi. Oun fẹrẹ laya ju awọn to ku lọ nitori ọmọ ile-Ifẹ bii ti Fani-Kayọde loun, bii aburo lo si jẹ si Fani. Eleyii fun un lagbara debii pe ki i woju ọlọpaa tabi aṣaaju ẹgbẹ oṣelu kan bi ija ba de, ko si si olowo tabi gbajumọ ti ko le kọlu, amugbalẹgbẹẹ Fani ni. N loun ba bẹrẹ agidi lile pẹlu awọn ọlọpaa yii, n lawọn ọlọpaa ba kuku dari kondo si ọdọ rẹ, nigba ti yoo si fi to bii iṣẹju diẹ ti wọn ti n ko kondo bo ọga awọn tọọgi naa, wọn lu u pa. Nigba tawọn to ku ri iku Lati Makinde, wọn fẹsẹ fẹ ẹ.

Fani Kayọde naa ti da mọto tirẹ duro, oun ati awọn oloṣelu ti wọn wa ninu rẹ ti bọ silẹ, wọn si ti fẹsẹ rin waa ba ọga ọlọpaa Ọlatubọsun nibi ti oun wa pẹlu awọn ọmọ rẹ, oun naa si ri i bi awọn tọọgi oun ti n ba awọn ọlọpaa fa a karakara. N loun naa ba bẹrẹ ariwo, pe ṣe ọga ọlọpaa naa yoo sọ pe oun ko ri oun ni, tabi pe oun ko mọ pe oun loun n kọja lọ. Ọkunrin naa ni oun ko mọ ẹni ti o n kọja lọ, ṣugbọn ohun ti ijọba to ko awọn wa lati Eko sọ ni pe bi awọn ba ti ri mọto yoowu to ba n lọ, ki awọn da wọn duro, bi awọn ba si ti ba ohun ija oloro lọwọ ẹnikẹni, ki wọn mu tọhun. O ni awọn ti da mọto lanrofa akọkọ to lọ duro, mọto naa ko duro, awọn da mọto tirẹ naa duro, oun naa ko duro, iyẹn lawọn ṣe dena de lanrofa to tun tẹle wọn, ti awọn si ba awọn ọmọọta ati awọn ohun ija nibẹ fọfọ.

Ọrọ naa ti di ohun ti awọn ọlọpaa to ku n kẹ ibọn wọn lọwọ, ti wọn si fẹẹ sọ ọrọ naa di ere-ibọn. Ọgbọn ni agbalagba fi n sa fun maaluu to ba ja, Fani-Kayọde ri i pe ọrọ awọn ọlọpaa naa ti di ọrọ ibọn, bi wọn si pa oun naa sibẹ, ẹnu ni wọn yoo fi sọ ọ, idi ni wọn yoo fi jokoo ni. N loun naa ba fẹyin rin, o lọọ wọ mọto rẹ, o n lọ. Ṣugbọn awọn ọlọpaa naa ko awọn mẹsan-an ti wọn ti ṣe leṣe ninu awọn toogi to ko dani, wọn si gbe oku Makinde sinu ọkan ninu awọn lanrofa wọn, wọn ko gbogbo wọn, o di teṣan wọn nigboro ilu Ibadan, wọn ni ki awọn ọga awọn oloṣelu yii ko gbogbo awọn tọọgi to ku jade, bi bẹẹ kọ, gbogbo wọn lawọn yoo mu nikọọkan. Amọ Fani-Kayọde ko jẹ ki ọrọ naa tutu, bo ti de’Badan lo fi ariwo bọnu, o ni awọn oloṣelu kan ni wọn ran awọn ọlọpaa yii jade lati waa pa oun, ni wọn ba rẹbuu oun lọna Ifẹ.

Kia lọrọ naa ti di ranto, nitori awọn Fani-Kayọde gbe ọrọ naa dewaju adajọ, wọn ni ki wọn wadii iku to pa Makinde, wọn ni ko lẹṣẹ kankan to ṣẹ awọn ọlọpaa ju pe o n lọ jẹẹjẹ rẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ lọ. Awọn Fani-Kayọde ni ọkunrin naa ki i ṣe tọọgi, wọn ni awọn ko mọ ohun  to n jẹ tọọgi, nitori ko si ohun ti awọn fẹẹ fi tọọgi ṣe. Wọn ni ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu awọn ni, awọn si n ti ode oṣelu bọ lasan ni, ko sohun to si ni ki wọn ma kọrin ẹgbẹ oṣelu awọn nigboro, awọn ọlọpaa kan pe wọn ni tọọgi ki wọn le ṣe wọn leṣe ni. Bi ọrọ ba ti da bayii, ti wọn ba ti mu awọn tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ, ko si lọọya mi-in ti wọn yoo lo ni gbogbo Western Region nigba naa ju Richard Akinjide lọ, nitori oun nikan lo mọ bo ṣe le fi ofin sọ ọrọ funfun di dudu, tabi ọrọ dudu di funfun. Afi ti wọn ba ri i.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti de ọdọ adajọ to n wadii ohun to fa iku ọkunrin ti wọn pa sọna Ibadan yii, nigba to si jẹ ijọba lo ni ileeṣẹ to n wadii ọrọ yii, awọn naa ni wọn ni adajọ, igbakeji olori ijọba si ni Fani-Kayọde ti ọrọ naa ṣẹlẹ si, ko sẹni ti ko mọ iru ẹjọ ti ọkunrin adajọ naa yoo da. Ibinu lọkunrin naa fi jokoo paapaa, afi bii ẹni pe oun naa wa nibi iṣẹlẹ naa, tabi pe o ri awọn ọlọpaa nigba ti wọn n pa a. Adajọ Majisreeti, Tunji Adeyẹmi, lo ṣe alaga igbimọ oniwadii iku to pa Makinde yii, oṣiṣẹ ijọba Western Region si ni. Nidii eyi, ko si ohun to le ṣe to gbọdọ lodi si ohun ti ijọba ba fẹ, bo ba si tilẹ fẹẹ ṣe ohun to lodi si tijọba, ko ni i ṣe ohun to lodi si Fani-Kayọde, nitori alagbara inu ijọba naa ni. Ohun to fa a ti ọkunrin naa fi n kanra mọ awọn ọlọpaa ti ọrọ naa ṣẹlẹ si niyẹn, o ni iṣẹ ti wọn ran wọn kọ ni wọn ṣe.

Nigba ti awọn ọlọpaa sọ niwaju adajọ yii pe aṣẹ ti awọn ti wọn ran awọn niṣẹ pa fawọn ni pe ki awọn maa mu ẹni yoowu ti awọn ba ti ri to mu ohun ija oloro dani, bi awọn ba ti le ri ọbẹ tabi ada, tabi ida, tabi igo, tabi awọn ohun ija mi-in lọwọ awọn eeyan kan, paapaa ti wọn ba jẹ oloṣelu tabi awọn ti wọn n tẹle oloṣelu, ki awọn mu wọn, nitori wahala to n ṣẹlẹ kaakiri West,adajọ naa ni awọn ti wọn ran wọn ni iṣe naa ko mọ ohun ti wọn n sọ ni. O ni ọlọpaa ko le wa si Western Region ko waa maa mu awọn oloṣelu ti wọn ba n ko tọọgi tabi ti wọn n mu ohun ija oloro rin, nitori ko si oloṣelu gidi kan to le rin ni West lasiko naa ti ko ni i mu tọọgi rin, tabi ki oun naa ni ohun ija oloro ti yoo fi gba ara rẹ silẹ bi awọn kan ba kọlu u. N ni gbogbo eeyan ba pariwo pe, “Haa, Adajọ Adeyẹmi lo sọ eyi tan!”

Awọn ọmọ ẹgbẹ AG ko tilẹ mu ọrọ ti adajọ yii sọ ni kekere, kia ni wọn ti bẹrẹ si i kọ iwe si ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa, wọn ni awọn fẹ iwe aṣẹ ki awọn le gbe ibọn rin, ki awọn si le maa mu awọn ohun ija oloro mi-in kaakiri, nitori Adajọ Adeyẹmi ti sọ pe oloṣelu gidi kan ko gbọdọ rin ni Western Region lai ni ọbẹ tabi ibọn, tabi awọn ohun ija oloro mi-in lọwọ. N lọrọ ba di ariwo mi-in lọna ọtọ, nitori Adajọ Adeyẹmi fẹẹ sọ pe bẹẹ kọ loun wi, ṣugbọn ọrọ naa ti bọ si ọwọ awọn oniroyin, o si wa ninu akọsilẹ iwe ile-ẹjọ, ko si bo ṣe le yọ ara rẹ jade. Koda nigba to dajọ naa, o ni oun ko gba pe iku amutọrunwa lo pa Lati Makinde, oun o si gba pe ọkunrin naa n ṣe tọọgi, nitori oun ko le gba ohun ti awọn ọlọpaa n sọ lẹnu gbọ rara, ọrọ wọn ko ye oun. Nitori bẹẹ, ki awọn ọlọpaa ṣewadii iwa ọdaran lori iku to pa Makinde.

Ohun ti adajọ naa n sọ ni pe ki wọn mu awọn ọlọpaa ti wọn wa lọna Ibadan naa, ki wọn si ba wọn ṣe ẹjọ apaayan, ki wọn si fiya nla jẹ wọn. Oun kọ lo n sọrọ yii o, Fani-Kayọde ni. Ohun ti Fani fẹ niyẹn, pe ki wọn fiya jẹ awọn ọlọpaa naa, ki iyẹn le le awọn ọlọpaa to ku to ba tun fẹẹ di awọn lọwọ danu, nitori ija naa ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Awọn ọlọpaa ko dahun ṣaa o, nitori wọn mọ iṣẹ ti awọn ran awọn ti wọn ko lọ s’Ibadan, wọn si mọ pe ohun ti awọn ni ki wọn ṣe ni wọn n ṣe. Kaka bẹẹ, olori awọn ọlọpaa pata, Ọgbẹni Edet, kọwe si Akintọla pe oun n bọ waa ri i, ki wọn le yanju ọrọ naa. Ọkunrin naa ri Akintọla loootọ, o si sọ fun un ko kilọ fun awọn oloṣelu ẹyin rẹ ti wọn n ko tọọgi rin, nitori ofin ijọba apapọ ni pe ko gbọdọ si tọọgi ni West, ẹni to ba n ṣe bẹẹ yoo fara jẹgba.

Bayii ni wọn pa tọọgi Fani-Kayọde sọna Ibadan, ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ si tori ẹ binu, ṣugbọn ti wọn ko ri nnkan kan ṣe.

 

 

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.