Ọjọ buruku lọjọ ti Fẹla gbe posi iya rẹ ka Ọbasanjọ mọle ni Dọdan Barracks,awon soja faraya gidigidi.

Spread the love

Ọrọ ki i tan ninu ọlọrọ. Arokan arokan ni i fa ẹkun asun-un-dakẹ, ẹni ba ṣe ni nibi, ẹda ki i gbagbe bọrọ, bẹẹ ni ija ki i tan ninu ẹni meji ti wọn ba n binu sira wọn. Inu n bi Fẹla si Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti wọn jọ jẹ ọmọ abule kan naa pẹlu iya rẹ, ṣugbọn ti tọhun lo ida ijọba le e lori. Gbogbo ọjọ to ba ti ji lo n ronu ohun ti oun yoo ṣe fun ọkunrin naa ti yoo fi mọ pe bi a ba ti yọwọ kaki to wọ sọrun ni, ko sohun ti yoo foun ṣe, nigba ti ko sohun ti gbẹdogbẹdo yoo fi ìtì ọgẹdẹ gbẹ, ti ko si ohun ti oromọdiẹ yoo fi iya rẹ ṣe. Ṣugbọn lagbaja ju ọ lọ, o ni diẹ naa ni, diẹ yẹn ki i ṣee ge danu naa ni, bẹẹ ni kekere kọ ni baba fi ju ọmọ rẹ lẹ. Loootọ ni Fẹla n kọrin, to si gbajumọ kaakiri origun mẹrẹẹrin agbaye, ṣugbọn ọmọ Naijiria ni, ẹnikẹni to ba si ti jẹ ọmọ Naijiria nigba naa, abẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo wa, ko si ohun tọmọde kan yoo fi baba rẹ ṣe.

Agbara ijọba Naijiria wa lọwọ Ọbasanjọ, ẹni to ba si lo o le lori nigba naa, ko si bi tọhun yoo ti bọ, afi toun funra rẹ ba ṣaanu onitọhun, to ni ki wọn yọ okun ijọba kuro lọrun rẹ. Fẹla ko wa aanu Ọbasanjọ, o ni oun ko ni i dọbalẹ nitori ti oun yoo jẹ maaluu laelae, ohun to ba wu Ọbasanjọ ni ko ṣe. Boya Ọbasanjọ lo ṣe e o, boya ijọba ṣọja funra rẹ lo ṣe e, ko ṣa si ẹni to mọ, ohun ti kaluku ri ni pe gbogbo ohun ti Fẹla le maa fi ṣe ọkunrin ni wọn gba lọwọ rẹ, ti wọn sọ ọ di korofo, ti ko si si kinni kan lọwọ rẹ mọ ju ohùn to fi n kọrin nikan, ati awọn iyawo mẹtadinlọgbọn to fẹ nijọ kan. Ṣugbọn ọkunrin ogun ni Fẹla, ki i bẹru ija, bẹẹ ni ki i bẹru ogun, gbogbo ohun to ba si ba a nibi to ti n ja yii ki i ka a si kinni kan, yoo maa ja lọ ni, yoo si maa sọ pe afi bi ẹmi ba bọ lara oun nikan loun o ni i ja ija naa mọ, akọni ọkunrin gbaa ni.

Awọn ṣọja ki i fẹran iru awọn eeyan bẹẹ yẹn, nitori wọn koriira ẹni to n ṣe agidi pẹlu wọn, boya iyẹn ni wọn fi mu ọrọ ija naa le koko bẹẹ, ti wọn si ni awọn ko ni i gba ki Fẹla da ilu ru mọ awọn lori. Ohun ti wọn fi kẹwọ ti wọn si n sọ ni pe Fẹla fẹẹ ba aye awọn ọmọ keekeekee jẹ ni, awọn ko si ni i gba fun un. Wọn ni bo ti n ko awọn ọmọde jọ to ni ki wọn maa waa jokoo lọdọ oun, ti wọn n ṣi idi silẹ ti wọn n ṣi ara silẹ, ti awọn mi-in yoo si kọ pe awọn ko lọ sileewe mọ ki i ṣe ohun to dara fun iru awujọ bẹẹ, wọn si n kilọ fun awọn ọmọ obinrin pe ki wọn ma sọ ara wọn di ọmọ Fẹla sigboro. Ṣugbọn awọn ọmọ ti wọn n lọ si ọdọ Fẹla ni awọn ki i ṣe ọmọ bẹẹ, awọn mọ ohun ti awọn n ṣe, ko si si ibi ti awọn ti le gbadun aye ara wọn ju ọdọ Fẹla lọ, bi ẹni kan ba si ni ki awọn ma ba Fẹla lọ, awọn yoo ku si tọhun lọrun ni. Abi ko waa tan!

Nidii eyi, ọpọ eeyan ko mọ boya Fẹla ni wọn yoo gbeja tabi ijọba. Bi awọn kan ti n sọ pe ika ni ijọba Ọbasanjọ atawọn ṣọja to ku bii Danjuma ati Yaradua, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ohun ti wọn ṣe fun Fẹla yẹn lo daa, agaga awọn ti ọmọ wọn tabi ọmọ ẹbi wọn kan ba ti ko si ile Fẹla ti ko si jade mọ. Ohun to si ṣẹlẹ ni pe ko si bi ọmọbinrin kan ti le kere to, bo ba ti to bii ọmọ ọdun mẹẹẹdogun soke, bo ba fi le sa wọ ile Fẹla, Fẹla ko ni i le e, paapaa to ba ti ni oun fẹẹ maa kọrin, tabi oun fẹẹ maa jo. Igbagbọ Fẹla ni pe iṣẹ-ọna ati ẹbun amutọrunwa ni iṣẹ orin ati ijo jijo, ko si sẹni ti ko le ṣe e bi Ọlọrun ba ti fun un lẹbun rẹ, lati pa ẹbun mọ ọmọbinrin kekere ninu ko dara, nitori ko sẹni ti i di wọn lọwọ niluu oyinbo pe ki wọn ma ba elere ṣere, tabi kawọn funra wọn ma di olorin. Ijọba ko fẹ bẹẹ yẹn, wọn ni aṣa ilu oyinbo ko delẹ yii rara.

Ohun ti wọn n sọ fun aye pe awọn fi n ba Fẹla ja ree, wọn ni iwa ko-sẹni-to-maa-mu-mi ẹ ti pọ ju, ominira to n lo bii pe ko sijọba niluu ko daa, awọn ko si le gba iru rẹ, bo ba ti n ṣẹ ẹṣẹ kan lawọn yoo maa gbe e. Ọrọ igbo mimu ni wọn kọkọ fi n gbe e, wọn ni wọn n mu igbo ni otẹẹli rẹ, wọn n fun awọn ọmọ keekeekee nigbo mu, awọn ko si fẹ amugbo lawujọ ilẹ yii, wọn ni bo si ti n mugbo to bẹẹ ni iya rẹ n kin in lẹyin, boya iya naa si n mu kinni naa awọn ko mọ ni. Loootọ si ni, igbakigba ti wọn ba ti mu un fun igbo mimu, ti awọn ọlọpaa de ti wọn jọ fa wahala, tabi ti wọn gba a lẹṣẹẹ titi, iya rẹ yoo dide, awọn lọọya nla nla naa yoo si naro lorukọ iya rẹ, wọn yoo si gba a silẹ nibi yoowu ti awọn ọlọpaa ba ti i mọ. Bi wọn ba ti gba a silẹ lo tun n lọ, ọrọ igbo yii yoo si tun di wahala laipẹ rara. Ojumọ kan, ijangbọn kan ni.

Ani ijọ buruku kan wa ti wọn mu Fela ninu lọdun 1974, iroyin si sọ pe awọn ọlọpaa ka igbo to we gbọgbọrọ mọ ọn lọwọ ni, wọn si mu un wọn, ni yoo ṣẹwọn. Ṣugbọn nigba ti ọrọ di ẹjọ gidi, ko si ẹri ti awọn ọlọpaa yoo fi ṣe ẹjọ pe wọn ba igbo lọwọ Fẹla. Ohun to fa iyẹn ni pe wọn ni nigba ti wọn mu un, bi wọn ti ni “Igbo ree lọwọ ẹ, ṣe o ko mọ pe ko ba ofin mu lati maa mu igbo ni!”, bẹẹ ni Fẹla fi ibinu sọ kinni naa sẹnu, o si run un wuruwuru, o si gbe kinni ọhun mi pata. Iyẹn lawọn ọlọpaa ṣe mu un, ti wọn ti i mọle pe nigba to ba ya, yoo yagbẹ, wọn yoo si ri igbo odidi to gbe mi yii ninu rẹ, ṣugbọn nigba ti yoo to ọjọ keji si ọjọ kẹta ti Fẹla yoo yagbẹ, igbẹ ṣiṣan lo ya, ko si si igbo kan bayii ninu igbẹ rẹ. Awọn ọlọpaa sọ eleyii niwaju adajọ, ṣugbọn ẹrin ladajọ ati awọn lọọya fi wọn rin, n ni wọn ba ni ki Fẹla maa lọ ni tiẹ o jare.

Nidii eyi, awọn ọlọpaa gba pe ko tun si ẹni kan ti ijangọn rẹ gbona bii ti Fẹla, saaba de saaba ni wọn si maa n ṣe fun ara wọn, bi aja ti n saaba ẹkun, bẹẹ naa ni ẹkun n saaba aja, afi ti ọrọ ba de oju rẹ pata ni awọn ọlọpaa ati Fẹla maa n tako ara wọn, ti wọn yoo si ba ara wọn ja ija ajadiju pata. Iyẹn lo ṣe jẹ nigba ti awọn ṣọja dana sun ile rẹ ti iya rẹ tun gba ibẹ lọ sọrun yii, awọn eeyan ko mo ibi ti Fẹla yoo gba yọ. Koda awọn ọlọpaa paapaa ko ti i mọ ibi ti Fẹla yoo gba yọ sawọn, wọn mọ pe loootọ awọn ṣọja lo ṣe e, awọn ni wọn sun ile rẹ, ṣugbọn bi ọwọ rẹ ko ba to awọn ṣọja, wọn mọ pe awọn ọlọpaa ni yoo pada fori ko kinni ọhun, awọn ni wọn yoo jiya ohun tawọn ṣọja yii ṣe. Awọn ti wọn n ṣejọba ni tiwọn, iyẹn awọn ọga ologun yii, ti ro pe awọn ti rẹyin Fẹla, wọn ni ko si ohun ti yoo ṣe ti ko ni i ba awọn nibẹ, afi to ba gbe jẹẹ nikan.

Fẹla n wa ọna ti yoo fi jẹ Ọbasanjọ niya, nitori bẹẹ, nigba ti awọn yẹn ti ni awọn n lọ, awọn yoo gbejọba silẹ fun awọn alagbada, Fẹla naa gbiyanju lati da ẹgbẹ oṣelu tirẹ silẹ, o ni ẹgbẹ ti yoo ja fun mẹkunnu ni, ẹgbẹ ti yoo ṣe ofin ti gbogbo ẹni to ba fẹẹ mugbo yoo maa mugbo rẹ lai si wahala, ẹgbẹ ti yoo ṣofin ti gbogbo ọmọde to ba jẹ ijo tabi orin lo yan laayo yoo le maa ṣe tire lai ni i si idiwọ, ẹgbẹ oṣelu ti yoo fun gbogbo eeyan ni ominira tiwọn. O pe orukọ ẹgbẹ oṣelu naa ni Movement Of the People, iyẹn MOP, o si ti ra mọto kan ti wọn kun lọda, ti wọn n gbe e kaakiri, orukọ ẹgbẹ oṣelu rẹ yii si wa nibẹ, bẹẹ ni wọn ya aworan awọn ọpọlọpọ eeyan ti wọn n lọ ti wọn n bọ lati fihan pe tiwọn ni ẹgbẹ naa, ẹgbẹ awọn araalu ni loootọ. Ohun ti oun naa si ni oun fẹẹ fi ẹgbẹ oṣelu oun ṣe niyẹn: ki oun tọju araalu.

eeyan si ti n tẹle e o, paapaa awọn ọdọ ti wọn nigbagbọ ninu rẹ ati ninu iwa rẹ, wọn n pariwo, “Fẹla for President!” “Fẹla for President” kaakiri. Nibikibi ti oun naa ba ti bọ silẹ ninu mọto MOP rẹ yii ni yoo ti nawọ meji soke lala, ti yoo si maa rẹrin-in sawọn eeyan, ti awọn naa yoo si maa pariwo. Nibi yoowu to ba ti dana ere rẹ paapaa, ko si ohun meji ti i fi ere naa ṣe ju ko bu awọn Ọbasanjọ ti wọn n ṣejọba, ko bu awọn olowo ti wọn n ba wọn rin kiri bii MKO Abiọla, ko si kọrin fun ominira awọn eeyan dudu agbaye. Ṣugbọn nisalẹ inu rẹ lọhun-un, Fẹla mọ pe bi ẹgbẹ oṣelu oun ba le wọle, ti oun ba si ribi di aarẹ Naijiria loootọ, iru awọn eeyan bii Ọbasanjọ yii daran lọwọ oun, nitori gbogbo ohun ti wọn ṣe loun yoo beere, bi oun ti n ṣa awọn akowojẹ loun yoo maa mu awọn ṣọja to ṣejọba ọran yii, kaluku yoo si jiya ohun to ba ṣe.

Boya ijọba waa mọ ero inu Fẹla ni o, tabi iwa rẹ ni ko tẹ wọn lọrun, tabi ẹgbẹ oṣelu to fẹẹ da silẹ ko ni awọn ohun to yẹ ko ni gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu, ko si tẹle awọn ilana ofin ti wọn to silẹ lati fi ni ẹgbẹ oṣelu ni o, ko sẹni to mọ, ohun to ṣa ṣẹlẹ ni pe nigba ti wọn n fi orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo dije lasiko ibo ti wọn fẹẹ di lọdun 1979 silẹ, wọn yọ orukọ ẹgbẹ Fẹla, MOP, danu, ijọba ko fi orukọ ẹgbẹ naa silẹ, wọn ni ko kun oju oṣuwọn to ni tawọn. Ni Fẹla ba tun bẹrẹ ariwo le wọn lori. O ni nitori wọn mọ pe oun yoo tu aṣiri gbogbo awọn ṣọja onikun-bẹmbẹbẹmbẹ ati awọn ọrẹ wọn ti wọn jọ ko owo Naijiria jẹ ni wọn ko ṣe forukọ ẹgbẹ oṣelu oun silẹ, nitori ti wọn ko fẹ ki oun di aarẹ, bo tilẹ jẹ pe oun ni gbogbo ara ilu fẹran julọ, ni wọn ṣe ni ẹgbẹ toun ko kun oju oṣuwọn, ṣugbọn oun o ni i gba, oun aa ṣe ṣege fun wọn.

Ni gbogbo asiko yii lo ti hu posi oku iya rẹ nibi ti ina ti jo o, to si ti gbe posi kan naa pada lọ sibi to n gbe ni Ikẹja, to si ni ki awọn eeyan maa ronu ohun ti oun yoo fi posi naa ṣe. Nigba to ti waa di inu ọdun 1979 tawọn Ọbasanjọ n lọ, ko si ẹni to tun fọkan si i pe Fẹla ni ijangbọn kankan lọwọ ti yoo tun fa mọ, wọn ni bo pẹ bo ya yoo rẹ ija gbẹyin ni, o jọ pe o ti rẹ Fẹla pẹlu wahala to fa lori ọrọ ile rẹ ati ti iya rẹ, o ti fẹẹ dojukọ iṣẹ orin to n ṣe. Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ, afi bi Fẹla ṣe kede ni bii oṣu kan to ku ki awọn Ọbasanjọ lọ, to sọ pe ọrẹ oun ni Ọbasanjọ, oun si fẹran rẹ daadaa, bo ti ṣejọba tan to fẹẹ maa lọ yii, oun ni awọn nnkan ara ọtọ kan ti oun yoo fi ta a lọrẹ. O ni eeyan ko le ṣe iru awọn iṣẹ ti Ọbasanjọ ṣe ko ma gba ẹbun pataki, nitori bẹẹ, oun yoo ri i pe oun fun un ni ẹbun to tọ si i ko too lọ, O ni oun fẹẹ fi ẹmi imoore han si i ni.

Ọbasanjọ mọ pe gbogbo ohun ti Fẹla n sọ yii, ase ni. O mọ pe o ti tun ni kinni kan ti yoo ṣe ni, o mọ pe ẹbun yoowu to ba fẹẹ fun oun, ẹbun ti yoo fi oun ṣe yẹyẹ ni. Awọn ṣọja ati ọga ọlọpaa naa ti mọ, wọn ni ẹbun wo ni Fẹla yoo fun Ọbasanjọ ju ko da wahala silẹ lọ. Ṣugbọn awọn eeyan ko ti i mọ ẹbun ti Fẹla fẹẹ fun ọrẹ rẹ Ọbasanjọ loootọ. Afi bo ṣe di ọsẹ ti Ọbasanjọ fẹẹ gbejọba silẹ ti Fẹla kede pe ko si ohun to tọ si Ọbasanjọ bo ṣe n lọ yii ju posi iya oun lọ, o ni oun yoo gbe posi iya oun fun un ko le maa gbe e lọ, ko si le maa fi ranti iya naa, nitori o jọ pe awọn mejeeji fẹran ara wọn. “Haa, posi ṣe waa jẹ!” Ohun ti ọpọ awọn eeyan n pariwo niyẹn, bẹẹ lawọn mi-in sọ pe “Ko jẹ jẹ bẹẹ, ọrọ apara ni!” Awọn ti wọn mọ Fẹla nikan ni wọn mọ pe bo ti wi yẹn ni yoo ṣe, koda, awọn ṣọja ni Dodan Baraaki ti bẹrẹ igbaradi, wọn mura silẹ fun un.

Ko tun si ẹni to gbọ nnkan kan mọ titi ọjọ kẹta to ku ki awọn ṣọja gbejọba silẹ, ni Fẹla ba ni lọjọ keji yẹn, iyẹn ni ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 1979, lawọn yoo gbe posi oku iya oun lọ si ọdọ Ọbasanjọ ni ọfiisi rẹ ninu baraaki awọn ṣọja ni Dodan, o ni kawọn ṣọja mura silẹ nitori wọn ko le da oun duro pe ki oun ma fun ọrẹ oun lẹbun ti oun fẹẹ fun un. O ni bi oun ko ba fun un lẹbun naa, iya oun yoo binu lọrun, nitori ọmọ rẹ l’Ọbasanjọ, oun lo si mọ bi iya naa ṣe ku, ko waa ni i daa ko ma gbe posi rẹ lọ bo ṣe n lọ yẹn. N lawọn ṣọja ba bẹrẹ girigiri, wọn mura silẹ bii kaa si nnkan ni, nitori lati oru ki ilẹ too mọ rara lọjọ naa ni wọn ti di gbogbo ọna to wọ Baraaki Dodan pa, wọn si ti sọ fun ara wọn pe nibi yoowu ti Fẹla ba ba yọ, awọn yoo gbe e janto ni, ko si ni i ri aaye fa wahala kan ti awọn yoo fi ra a mu.

Lati aago aarọ lawọn ṣọja ti n paarọ ara wọn nibẹ, to jẹ bi awọn kan ba ti ṣọ ẹnu ọna Dodan Baraaki yii diẹ, awọn mi-in yoo tun pada waa rọpo wọn, nitori wọn mọ pe Fẹla yoo de gija nigba ti awọn ko ro ni. Ṣugbọn lẹyin ti wọn ti wa nibẹ lati aarọ, ti wọn si ṣọ ẹnu ọna naa ati ayika titi di aago mejila si aago kan ọsan ti Fẹla ko wa, nigba to di aago meji, gbogbo wọn tuka, wọn ni ọkunrin naa kan ko awọn lẹmi-in soke lasan ni, wọn kan fi iwọnba awọn ṣọja ti wọn maa n ṣọ geeti sibẹ ni, kaluku si pada si aaye rẹ, wọn ni Fẹla ko wa mọ o. Ṣugbọn ko ju ogun iṣẹju ti wọn tuka bẹẹ ti mọto sifilian kan ati danfo kan fi de giiri lojiji, nigba tawọn ṣọja naa yoo si fi mọ ki lo n ṣẹlẹ, awọn mọto mejeeji ti de iwaju wọn gulẹ, wọn wọle sinu baraaki. Lara bọọsi sifilian yẹn ni wọn kọ Burnt Palace Line si, danfo si jẹ ti ẹgbẹ oṣelu MOP.

Ninu mọto sifilian yii ni Fẹla ati awọn iyawo rẹ wa, ati gbogbo awọn ọmọlẹyin rẹ ti wọn ba a wa, ṣugbọn ninu danfo yii ni wọn gbe posi Iya Fẹla si, wọn si kun posi naa ni ọda pupa ati dudu (Red and Black), lọwọ kan ti Fẹla si ti wọle ni wọn ti ja posi naa silẹ, wọn fẹẹ yipada ki wọn tete maa lọ. Nibẹ ni awọn ọlọpaa ṣọja ti wọn n pe ni Military Police ti ya bo wọn, nitori ojiji ni kinni naa ba wọn. Wọn ni ki Fẹla gbe posi iya rẹ pada sinu mọto rẹ, ṣugbọn o taku, o ni posi naa, ọrẹ oun loun waa gbe e fun, bi o ba ti de ọdọ rẹ ti wọn gbe e fun un, kinni naa yoo ye e. Awọn ṣọja onifila pupa naa ni awọn ko gba, ko ṣa gbe e pada sinu mọto rẹ ti ko ba fẹ iyọnu. Ṣugbọn ẹrin ni Fẹla n rin, o ni posi naa ki i ṣe ti oun mọ, ti ọrẹ oun Ọbasanjọ ni. Nibẹ nija ti de, toun atawọn ṣọja ti bẹrẹ si i tutọ si ara wọn loju. N lawọn ṣọja ba fipa ka a lọwọ sẹyin.

Igba naa ni wọn ni ki gbogbo awọn iyawo rẹ bọ silẹ ninu mọto sifilian ti wọn wa, ṣugbọn awọn eeyan naa taku, wọn ni awọn ko ni i bọ silẹ, ọkọ awọn lawọn ba wa, oun lalejo wọn, awọn kọ ni alejo Ọbasanjọ. Ṣugbọn niṣe ni ọkan ninu awọn ṣọja naa sare lọọ gbe bẹntirolu wa, ti wọn ni wọn yoo dana sun mọto naa ti wọn ko ba bọ silẹ nibẹ kia. O jọ pe awọn iyawo Fẹla yii ranti ohun to ṣẹlẹ nile wọn lọdun 1977, nigba ti wọn dana sunle, ti wọn si ṣe wọn ṣikaṣika, iyẹn lo jẹ ki wọn ṣilẹkun mọto naa, ni gbogbo wọn ba rọ bọ silẹ, n lawọn ṣọja ba bẹrẹ si i fi igi ati koboko lu wọn, ti wọn si ni ki wọn niṣo ni itimọle. Fẹla binu. O ni ki wọn yee fi igi tabi koboko lu awọn iyawo oun, bi wọn ko ba mọ, awọn iyawo ọba ni wọn n lu yẹn o, ẹnikẹni to ba si lu iyawo ọba yoo ri ija ọba, nitori awọn irunmalẹ ni yoo ba tọhun ja, ki i ṣe oun.

Lẹsẹkẹsẹ lawọn ero ti pe jọ, wọn le ni ọgọrun-un meji ti wọn ti wa nibẹ, wọn fẹẹ mọ ohun ti yoo gbẹyin ọrọ naa, oju wọn ni wọn si ṣe n wọ Fẹla ati awọn olori rẹ lọ, ti wọn si lọọ ti wọn mọle sinu Baraaki Dodan. Wọn ti wọn mọle ti wọn ko fi wọn silẹ titi ti awọn oloṣelu fi gbajọba lọwọ Ọbasanjọ lọjọ keji, Ọbasanjọ si ti ko ẹru rẹ lọ ki wọn too ṣi wọn silẹ. Ṣugbọn kinni kan ni, Fẹla ko gba posi naa lọwọ awọn ṣọja, o ni oun fi ta Ọbasanjọ lọrẹ, igba ti wọn ba ri i ki wọn gbe e fun un, nitori posi naa ki i ṣe toun mọ, ti ọmọ iya oun to n jẹ Ọbasanjọ ni.

 

(100)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.