Ojo balẹ jẹ n’Ilọrin, gbogbo ina mọnamọna wọn lo ti ku o.

Spread the love

Nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ lojo wakati kan bẹ silẹ n’Ilọrin ti o si ba ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye jẹ. Lara awọn nnkan to bajẹ ni poolu ina Ibadan Electricity Distribution Company (IBDEC).

Lati ọjọ Iṣẹgun ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ ni wọn ti nina mọnamọna gbẹyin lawọn apa ibikan niluu Ilọrin. Awọn apa ibikan ni Stadium Complex, awọn ile kọọkan paapaa julọ Queen Elizabeth Secondary School.

Awọn ibi ti ojo yii ti ṣọṣẹ julọ ni Taiwo road, Basin road, Adewọle, Sanngo, Alore, Ọlọjẹ, Ogidi, Okolowo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ojo yii le debii pe o wu awọn ogiri-ipolowo (Billboard) ti ijọba fi maa n polowo awọn oriṣiiriṣii nnkan loju titi. Ọkan ninu awọn ogiri-ipolowo yii kọlu ọkọ taxi kan, o si ṣe awọn ero inu ọkọ naa leṣe yanayana.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.