Ohun to ṣẹlẹ l’Ekiti ti wọn n yinbọn funra wọn

Spread the love

Ohun to le fa ki awọn eeyan maa gbe ibọn kiri debii pe wọn yoo bẹrẹ si i yin in lu ara wọn nitori ọrọ ibo ko ye ẹnikan. Nigba ti awọn nnkan bayii ba n ṣẹlẹ lọdọ wa, awọn oyinbo a maa pe wa ni ẹranko, nitori awọn iwa to maa n ṣẹlẹ lọdọ wa nigba mi-in loootọ, bii ti ẹranko ni. Ibo la ni a fẹẹ di, ohun ti a si sọ naa ni pe gbogbo ilu lo fẹran wa, ki labọrọ maa ko ọlọpaa kiri si, kin ni idi lati maa kiri tibọn-tibọn. Ariwo ti a n gbọ lori ibọn ti wọn yin lọjọ ti Fayẹmi wọ Ekiti yii ko ju ti pe eeyan pataki ni ibọn naa ba lọ, bo ba jẹ araalu kan lasan nibọn ba, koda ko pa a danu, wọn yoo ti gbagbe rẹ, wọn yoo si maa ba ipolongo wọn lọ ni. Ṣugbọn bo ti n ri ree o, awọn oloṣelu wọnyi naa yoo si mọ bo ti ṣe n ri, nigba ti wọn ba yinbọn fun odidi Ọpẹyẹmi Bandele, ta lo waa ku ti wọn ko le yinbọn lu. Ko si ohun to le mu iru eleyii ma ṣẹlẹ ju ki awọn oloṣelu funra wọn fi suuru ṣe e lọ. Bi Fayẹmi ba n bọ ni Ekiti, to si mọ pe ilu awọn eeyan oun ni, awọn eeyan naa si fẹran oun, kin ni yoo maa waa fi ọlọpaa ati awọn agbofinro oriṣiiriṣii halẹ mọ wọn si. Awọn igbesẹ ti Fayẹmi n gbe, bii igba pe o ti ni in lọkan lati fi tipatipa gba ijọba ipinlẹ Ekiti, koda bi awọn ara Ekiti ko ba fẹ ẹ. Ko le to bẹẹ yẹn, ko si yẹ ko ri bẹẹ rara. Agbara ijọba apapọ ni Fayẹmi gbojule, agbara ti Buhari ati awọn eeyan rẹ yoo fun un lati fi gbajọba. Loootọ bo ba fẹ ṣọja, wọn yoo fun un, bo si fẹ ọlọpaa, wọn yoo ko o le e lọwọ, ṣugbọn iyẹn ko dara to, ohun yoowu ti a ba fẹẹ ṣe, afi ka fi ti araalu si i. Bi ara ilu ba ti fẹ tẹni, ko si ohun ti ọta tabi ẹgbẹ alatako kan le ṣe, awọn araalu wọnyi ni yoo di odi ati asà, awọn ni wọn yoo si maa sọ ẹni ti wọn ba fẹ nipo funra wọn. Bo ba ti di pe ka lo ọlọpaa ati ṣọja fi halẹ mọ awọn eeyan, ibi ti yoo maa ja si naa lo n ja si yii o. Bi ọrọ si ṣe ri laarin ọdun 2007 si 2010, ti Ṣẹgun Oni n ṣejọba, ti awọn Fayẹmi ni dandan ni ki awọn gbajọba naa pada ree, wahala igba naa ko si tan nile ẹlomi-in titi doni. Ko dara ki iru iyẹn tun ṣẹlẹ mọ o, ẹ fi araalu lọkan balẹ, ẹ fawọn Ekiti lọkan balẹ, a ki i fi tipatipa ṣejọba, ifẹ araalu la fi n ṣejọba o.

(64)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.