Ohun ti a fẹ niyẹn o

Spread the love

Ni ọsẹ to kọja yii, Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ileri kan, o ni oun ṣeleri lati fi Naijiria silẹ ni didara ju bi oun ti ba a lọ. Igba ti awọn aṣoju ẹgbẹ ẹlẹsin Kristẹni nilẹ yii lọọ ki i ku oriire ti pe o wọle ibo ẹlẹẹkeji yii lo sọ bẹẹ, to si fi awọn ẹlẹsin naa lọkan balẹ pe gbogbo ohun to ba tọ loun yoo ṣe lati ri i pe Naijiria yii dara pupọ ju bi oun ṣe ba a ni ọdun 2015 lọ. Ohun ti a n wi gan-an niyẹn. Bi Buhari ba ṣe e ti Naijiria dara ju bo ti wa lọ lọdun to gbajọba, ko sẹni ti inu rẹ ko ni i dun, ko si sẹni ti ko ni ki i pe o ṣeun. Yatọ si ariwo ti awọn oloṣelu n pa pe ayipada kan ti wa, awọn ti ṣe igba awọn ti ṣe awo, yoo ṣoro fun ojulowo ọmọ Naijiria kan, paapaa awọn mẹkunnu, lati sọ peawọn ri ayipada gidi kan to jẹ daadaa lati igba ti Buhari ti gbajọba ni 2015. Bẹẹ ko too di pe o gbajọba yii loootọ, nnkan ko dara, ariwo ti oun ati awọnẹgbẹ oṣelu rẹ si n pa ni pe awọn n mu ayipada bọ, ayipada daadaa.Ṣugbọn kaka ki owo ọja gbogbo  dinku, wọn lọ soke si i ni. Ṣe owo epo bẹntiroolu ni ka sọ ni tabi ti kẹrosinni, owo ti a n ra awọn ounjẹ bii irẹsi la fẹẹ wi ni tabi awọn oogun ti mẹkunnu le lo, ko sẹni ti ko mọ pe awọnnnkan wọnyi ti lọ soke ju bo ti wa ni 2015 lọ, inira lo si jẹ fun awọn araalu, agaga awọn ti wọn ki i baa ṣe oloṣelu, ti wọn ko si ri ọna lati ko owo ijọba jẹ. Yatọ si eyi, ipaayan to pọ nilẹ yii lati ọwọ awọn Fulani onimaalu ko fiọkan ẹnikẹni balẹ, awọn araabule ko le gbe abule wọn pẹlu ifọkanbalẹmọ, awọn agbẹ ti wọn ti n da oko wọn lati ọpọ ọdun wa ko le ṣe iṣẹ oko wọn ko dara, ibẹru Fulani ko ni i jẹ, nitori wọn le de oko oloko lọjọ kan ki wọn si pa baba oloko ati awọn ọmọ rẹ, ki wọn ni wọn ko jẹ ki maalu awọn jẹ oko. Ijọba yii ko si ba wọn wi, lara awọn ohun to jẹ ki ọpọ eeyan koriiraijọba naa niyẹn. Awọn eeyan paapaa n kun nipa iwa ẹlẹyamẹya, pe gbogbo ipo to ba dara to si jẹ ipo alagbara ni Naijiria, ọmọ Fulani tabi Hausa ni Buhari n fi sibẹ, koda bo ba ṣe ọmọ Ibo tabi Yoruba lo ṣẹṣẹ yọ. Bi Naijiria yoo ba dara, to ba si jẹ loootọ ni Buhari yoo mu ki Naijiria daa ju bo ti wa ko too gbajọba lọ, aa jẹ gbogbo awọn ohun yii ni yoo mu kuro, ti yoo tun eto ọrọ-aje ṣe, ti yoo si kilọ fawọn Fulani apaayan to n rin kiri igboro yii, ti yoo si da awọn to n huwa ẹlẹyamẹya ninu ijọba rẹ duro. Bo baṣe eleyii, to si gbogun ti iwa ibajẹ rẹ bo ti n ṣe e lai fi i ṣe ojuṣaaju, ti ko muẹni kan ko fi ẹlomi-in silẹ nitori wọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ tabi ẹya kan naa, ko si ki Naijiria ma dara ju bo ṣe ba a lọ. Ohun ti awa fẹ niyẹn, ohun ti gbogbo ilu si fẹ naa niyẹn, ki gbogbo awọn ti wọn si n tẹle e tabi ti wọn jọ n ṣeẹgbẹ kan naa ba a sọrọ lori eyi, ki wọn ṣalaye ọna ti yoo fi mu Naijiria daa ju aye Jonathan lọ fun un, Aarẹ ti sọ pe ohun to wu oun niyẹn, ki gbogboẹni to sun mọ ọn si ran an lọwọ lo ku, ki Ọlọrun fun Buhari ṣe ladura tiwa.

(48)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.